ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/13 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 1/13 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò ní January àti February: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé olójú ewé méjì-lé-lọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa túbọ̀ wúlò dáadáa fún onílé lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà. March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Inú wa dùn láti sọ fún yín pé lọ́dún 2013, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Badagry ní March 16-17 àti August 18; Benin City ní February 8-9 àti June 30; Ibadan ní March 23-24 (Àpéjọ Àkànṣe máa wáyé ní Lekki ní June 9); Kwali ní February 16 àti June 22-23; Lekki ní March 30-31 àti June 8; Uli ní February 24 àti May 4-5. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe lédè Faransé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Badagry ní March 24 àti June 15-16. Èdè Faransé àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la máa fi ṣe àwọn àpéjọ yìí látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ àwọn èdè yìí pé kí wọ́n wá.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ní, “Ìhìn Rere Fún Gbogbo Èèyàn Lónírúurú Èdè.”

◼ Ní gbàrà tí àwọn ìwé ìròyìn wa bá ti tẹ̀ yín lọ́wọ́, ẹ máa kó wọn jáde síbi tí àwọn akéde ti máa gbà á. Èyí á jẹ́ kí àwọn ará lè ka àwọn ìwé náà kí wọ́n sì mọ àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa. Wọ́n sì lè fẹ́ lo àwọn àpilẹ̀kọ kan látinú àwọn ìwé ìròyìn náà tàbí ìwé ìròyìn náà lódindi nígbà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti máa lo àwọn ìwé ìròyìn náà nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́