Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 4
Orin 70 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 5 ìpínrọ̀ 1 sí 6 àti àpótí tó wà lójú ìwé 55 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Mátíù 22-25 (10 min.)
No. 1: Mátíù 23:25-39 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Gbogbo Èèyàn Ló Máa Ní Ìgbàlà?—td 18D (5 min.)
No. 3: Àwọn Àpẹẹrẹ Wo Nínú Bíbélì Ló Jẹ́ Ká Mọ Àǹfààní Tó Wà Nínú Òwe 3:5? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù February. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ February, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n tún sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January—February 2013. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé, ‘Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9 àti 10. Ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 95 àti Àdúrà