Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 20
Orin 73 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 27 ìpínrọ̀ 19 sí 22, àti àpótí tó wà lójú ìwé 279 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 12-14 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 12:21-30 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù—Ják. 4:7 (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkọ Àtàwọn Baba Lọ́wọ́?—igw ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 àti 2 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ —Mát. 28:19, 20.
20 min: Àwọn Àpéjọ Ọdọọdún Tó Ń Múni Láyọ̀. Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ September 15, 2012, ojú ìwé 31 àti 32, ìpínrọ̀ 15 sí 19. Sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kí àwọn ará nífẹ̀ẹ́ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tó ń bọ̀. Mú kí wọ́n máa wọ̀nà fún ohun tí wọ́n máa gbádùn níbẹ̀, fún wọn níṣìírí láti wo àwọn kókó tá a máa gbọ́ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè tá a gbé sórí ìkànnì jw.org/yo.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò.
Orin 74 àti Àdúrà