Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko
1. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní ṣe máa gbilẹ̀ tó?
1 Kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bàa lè di oníwàásù “ìhìn rere” tó já fáfá, Jésù kọ́ wọn ní gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ láìkù síbì kan. (Mát. 4:23; 9:35) Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà wáyé nígbà tí Jésù ń wàásù ní Palẹ́sìnì. Àmọ́, kí Jésù tóó padà sí ọ̀run, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù yìí máa kárí ibi gbogbo ká bàa lè “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát. 28:19, 20.
2. Kí ni ìtumọ̀ àṣẹ tí Jésù pa pé ká ‘sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’?
2 Ìṣẹ́ yẹn máa kan pípadà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì kọ́ wọn láti máa pa ohun tí Kristi pa láṣẹ mọ́. Kí irú pípadà lọ bẹ́ẹ̀ tó lè múná dóko, a ní láti máa múra sílẹ̀ dáadáa.
3. Bó o bá wàásù fẹ́nì kan nígbà àkọ́kọ́, báwo lo ṣe lè ṣe é tó fi máa gbà pé kó o padà wá?
3 Múra Sílẹ̀: Káwọn akéde kan tóó kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí wọ́n wàásù fún nígbà àkọ́kọ́, wọ́n máa ń sapá láti bi í ní ìbéèrè kan, wọ́n á wá ṣàdéhùn láti dáhùn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá padà lọ. Bí wọ́n sì ṣe máa ń fi àlàyé látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni dáhùn irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.
4. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ dúró dìgbà tí ìwé ìròyìn tuntun bá jáde ká tó lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò?
4 Pé oríṣi ìwé ìròyìn kan là ń lò lóṣù kan kò ní ká wá dúró dìgbà tí ìwé ìròyìn míì bá dé ká tó padà lọ bẹ àwọn èèyàn wò. A lè mú kí ìfẹ́ tẹ́ni náà ní túbọ̀ pọ̀ sí i tá a bá padà lọ bá a jíròrò kókó kan látinú ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.
5. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn múra sílẹ̀ dáadáa kó tó lọ ṣèpadàbẹ̀wò?
5 Ní Àfojúsùn: Kó o tó padà lọ, fi àkókò díẹ̀ yẹ àkọsílẹ̀ rẹ wò, kó o sì pinnu ohun tó o fẹ́ kẹ́ni náà mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, jíròrò kókó kan látinú ìtẹ̀jáde tó o fún onílé kẹ́yìn. Tàbí kó o fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì tó bá ohun tẹ́ ẹ jọ sọ mu. Tó o bá ṣàdéhùn láti dáhùn ìbéèrè kan nígbà tó o bá padà lọ, kó o rí i dájú pé o dáhùn rẹ̀. Tó o bá ń sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ti ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí lẹ́yìn, gbìyànjú láti kà á jáde ní tààràtà látinú Bíbélì.
6. Kí nìdí tá a fi ń ṣe ìpadàbẹ̀wò?
6 Ìdí Tá A Fi Ń Ṣèpadàbẹ̀wò: Kò sídìí míì tá a fi ń padà lọ bẹ àwọn ẹni tá a wàásù fún wò ju pé ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Onílé kan kọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí arákùnrin wa kan ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí arákùnrin wa yìí máa tún padà lọ, ó mú ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde dání, ó sì sọ fún ọkùnrin náà pé, “Ìbéèrè kan tí ìdáhùn rẹ̀ wà nínú Bíbélì là ń ṣàlàyé fáwọn èèyàn ládùúgbò yín.” Lẹ́yìn tí ọkùnrin náà ti fèsì, arákùnrin yìí wá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan àti ìpínrọ̀ kan tó bá a mu látinú ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a fí ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ àwọn èèyàn. Látìgbà náà, ni wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé.
7. Báwo ni mímúrasílẹ̀ dáadáa ṣe ràn ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan?
7 Àkókò tá à ń lò láti múra ìpadàbẹ̀wò tá a fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣe ni inú wa á túbọ̀ máa dùn, àá sì lè tipa bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti ran ẹnì tó bá ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Ìṣe 13:48.