Ran Àwọn Tó Ní “Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́” Lọ́wọ́
1. Àwọn wo ni Jèhófà ń kó jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lọ́jọ́ wa?
1 Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ìṣesí kan tó ti fìdí múlẹ̀ nínú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀. (Mát. 12:35) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí “ọkàn-àyà rẹ̀ ti ṣe tán láti jà.” (Sm. 55:21) Àwọn kan wà tí wọ́n “fi ara fún ìhónú.” (Òwe 29:22) Àmọ́, àwọn kan tún wà tí wọ́n ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Lọ́jọ́ òní, Jèhófà ń kó irú àwọn tó ní ìtẹ̀sí- ọkàn títọ́ bẹ́ẹ̀ jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Hág. 2:7) Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di olùjọ́sìn Jèhófà?
2. Kí ni ṣíṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní nínú?
2 Máa Fi Tọkàntọkàn Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Níní èrò tó tọ́ nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò ṣe pàtàkì kó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí a gbé lé wa lọ́wọ́. (Mát. 28:19, 20) Ǹjẹ́ à ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ran àwọn tó fìfẹ́ hàn tí à ń rí lọ́wọ́? Ṣé a máa ń lọ padà bẹ gbogbo àwọn tó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tàbí tí wọ́n fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere náà wò? Ṣé a máa ń tẹra mọ́ ìsapá wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà nípa tẹ̀mí? Níwọ̀n bí ọ̀ràn yìí ti wé mọ́ ìwàláàyè, ó yẹ ká wá ọ̀nà láti ran gbogbo àwọn tó fìfẹ́ hàn tí à ń rí lọ́wọ́.
3. Kí ló yẹ ká ṣe lẹ́yìn tí a bá bá ẹnì kan jíròrò tán nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
3 Nígbà tí ìjíròrò tó o ní pẹ̀lú ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn ṣì wà lọ́kàn rẹ, wá àyè díẹ̀ láti kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ sílẹ̀. Ṣe àkọsílẹ̀ kókó tẹ́ ẹ jọ jíròrò, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ èyíkéyìí tẹ́ ẹ kà àti irú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ẹni náà gbà. Lẹ́yìn ìgbà náà, rí i dájú pé o tètè padà lọ bó bá ti lè yá tó.
4. Báwo la ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò tó gbéṣẹ́?
4 Bí A Ṣe Lè Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Nígbà tó o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò, jíjẹ́ ẹni tára rẹ̀ yá mọ́ni tó sì kóni mọ́ra àti fífi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí onílé náà á ṣèrànwọ́. Mú ìjíròrò náà rọrùn, kó o sì jẹ́ kó dá lórí Ìwé Mímọ́. Múra kókó ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kan tó máa gbádùn mọ́ onílé náà sílẹ̀, lẹ́yìn tó o bá sì ti parí ìpadàbẹ̀wò náà, béèrè ìbéèrè kan tí wàá dáhùn rẹ̀ nígbà tó o bá tún padà wá. Ó dára láti yẹra fún bíbá onílé náà jiyàn láìnídìí lórí èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tó ṣeé ṣe kó sọ jáde. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ìjíròrò rẹ máa dá lórí àwọn nǹkan tí ẹ̀yin méjèèjì jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí.—Kól. 4:6.
5. Ìsapá wo ni aṣáájú ọ̀nà kan ṣe, kí sì ni àwọn àbájáde rẹ̀?
5 Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò ń béèrè ìsapá, àmọ́ àwọn àbájáde rẹ̀ máa ń mú ayọ̀ wá. Aṣáájú ọ̀nà kan ní ilẹ̀ Japan gbé góńgó kan kalẹ̀ láti máa ṣe ọ̀pọ̀ ìpadàbẹ̀wò lóṣooṣù. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ àkọsílẹ̀ nípa gbogbo àwọn tó bá sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ó sì padà lọ bẹ̀ wọ́n wò láàárín ọjọ́ méje. Ó múra ohun tó máa sọ sílẹ̀ dáadáa, ó sì fi ìgbọ́kànlé kíkún ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tó ń ṣe ọ̀kan lára àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹnì kan tó ti máa ń sọ pé: “Ńṣe ni mo máa ń lé àwọn èèyàn yín dà nù tẹ́lẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá tẹ́tí sílẹ̀.” Bí aṣáájú ọ̀nà náà ṣe fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò mú àbájáde rere wá. Nígbà tó fi máa di òpin oṣù náà, ó ti ń ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́wàá.
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò?
6 Ìgbà gbogbo ni ipò àwọn èèyàn ń yí padà. (1 Kọ́r. 7:31) Ó sábà máa ń béèrè pé ká lọ lọ́pọ̀ ìgbà ká tó tún lè bá ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn nílé. Nípa fífi tọkàntọkàn ṣe ìpadàbẹ̀wò, a lè ran àwọn tó ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ lọ́wọ́ láti bọ́ sí ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 7:13, 14.