Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
1 Ṣé o gbà pé jíjẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́ sinmi gidigidi lórí lílo ìdánúṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ìpèníjà tó wà níbẹ̀ ni pé kí o sọ nǹkan tí yóò fa ẹni náà mọ́ra, kí o sì mú kó fèsì. Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè ṣe èyí lọ́nà gbígbéṣẹ́?
2 Ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé bí a bá sọ gbólóhùn mélòó kan tó bá a mu dáadáa, a lè fi àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa, tí a gbé karí Bíbélì, lọni kí a sì fi wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Àwọn àkọlé wọn fani mọ́ra, àwọn àwòrán wọn jẹ́ aláwọ̀ mèremère tó jojú ní gbèsè. Ìwé àṣàrò kúkúrú kì í kani láyà, tí ẹni náà ì bá fi máa ronú pé àkààkàtán nìwé náà. Síbẹ̀, ìsọfúnni ṣókí tó wà nínú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa máa ń wọni lọ́kàn, a sì lè lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
3 Ẹlẹ́rìí kan ronú lọ́nà yìí pé: “Nínú ayé tọ́wọ́ àwọn èèyàn ti máa ń dí yìí, wọ́n kì í sábà fẹ́ láti kàwé fún àkókò púpọ̀, ṣùgbọ́n ṣókí làwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé àṣàrò kúkúrú, wọ́n pèsè ìsọfúnni pàtàkì tí kò pọ̀ débi pé káwọn èèyàn tó kà á ni yóò ti sú wọn. Mo ka ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wọ̀nyẹn, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Má ṣe fojú kéré agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú àwọn ìhìn ṣíṣe ṣókí, tí a tẹ̀ jáde yìí.—Héb. 4:12.
4 Ọ̀nà Mẹ́rin Tó Rọrùn: Ọ̀pọ̀ ti ṣàṣeyọrí nípa gbígbọ́rọ̀kalẹ̀ lọ́nà tó rọrùn. (1) Fi díẹ̀ lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú han ẹni náà, kí o sì béèrè èyí tó nífẹ̀ẹ́ sí. (2) Lẹ́yìn tí ẹni náà bá ti yan ọ̀kan, béèrè ìbéèrè kan tí o ti múra sílẹ̀ dáadáa, tí ó tẹnu mọ́ kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. (3) Láti dáhùn ìbéèrè náà, ka ìpínrọ̀ tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti inú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. (4) Bó bá fèsì lọ́nà tó dáa, máa bá a lọ láti jíròrò ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà tàbí kí o pàfiyèsí sí ẹ̀kọ́ kan nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí orí kan nínú ìwé Ìmọ̀ tó pèsè àlàyé síwájú sí i. Lọ́nà yìí, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ẹsẹ̀. Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti múra ohun tí wàá sọ nípa lílo mẹ́rin lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà.
5 A lè lo àkọlé ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Ta Ni Ń Ṣakoso Ayé Niti Tootọ?” gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè kan.
◼ Bí ẹni tí o ń bá sọ̀rọ̀ bá dáhùn pé, “Ọlọ́run” tàbí “mi ò mọ̀ ọ́n,” ka gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ lójú ìwé 2 àti ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lójú ìwé 3. Ṣàlàyé 1 Jòhánù 5:19 àti Ìṣípayá 12:9. Yálà ẹni náà ṣiyè méjì lórí pé Sátánì Èṣù wà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tàbí pé ó ń lo agbára lórí ayé tàbí kò lò ó, o lè jíròrò ọ̀nà ìrònú tí a rí lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Ojútùú kan Lati Inu Awọn Ipo Ayé,” láti máa bá ìjíròrò náà lọ. Bó bá fìfẹ́ hàn, sọ pé wàá fẹ́ láti jíròrò nípa ibi tí Èṣù ti wá, kí o lo àwọn kókó tó wà lójú ìwé 3 àti 4 nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà.
6 Ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú?” lè ru ìfẹ́ sókè lójú ẹsẹ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa bíbéèrè pé:
◼ “Ǹjẹ́ o rò pé ìgbà ń bọ̀ tí a óò rí àwọn èèyàn wa tó ti kú bí?” Lẹ́yìn tí ẹni náà bá fèsì, ṣí i sí ìpínrọ̀ kejì lójú ewé 4 nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kí o sì ka Jòhánù 5:28, 29. Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Sọ pé kó jẹ́ kí ẹ jọ jíròrò rẹ̀.
7 Ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Gbadun Igbesi-Aye Idile” máa ń fa ìdílé mọ́ra ní gbogbo gbòò. Bí o bá fẹ́ lò ó, o lè sọ pé:
◼ “Ìwọ náà mọ̀ pé ìṣòro ń kojú ìdílé lónìí. Kí lo rò pé a lè ṣe láti mú kí ìdè ìdílé lágbára sí i?” Lẹ́yìn tí ẹni náà bá ti fèsì, pe àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn kókó tó wà ní ìpínrọ̀ kìíní lójú ìwé 6. Yan ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lójú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kí o sì ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó mọ̀ pé ó lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé rẹ̀, lọ́fẹ̀ẹ́.
8 A lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà, “Idi Tí O Fi Lè Gbẹkẹle Bibeli,” nípa lílo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí:
◼ “Ṣàṣà lèèyàn tí kò tíì gbọ́ nípa ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì rí, ìtàn yìí wà nínú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì tún sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó Kéènì. Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ibi tí ìyàwó rẹ̀ ti wá?” Lo ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn lójú ewé 2 nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti fi dáhùn. Ṣàlàyé pé ìwé àṣàrò kúkúrú náà tún jíròrò àlàyé pàtàkì tí Bíbélì ṣe nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Bẹ̀rẹ̀ láti ìpínrọ̀ kẹta lójú ìwé 5, máa bá ìjíròrò náà lọ, lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fi ti ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn.
9 Kì í ṣòní, kì í ṣàná la ti ń pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí a gbé karí Bíbélì kiri, a sì ti rí i pé ó jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti sọ ìhìn rere náà. Nítorí pé wọ́n rọrùn láti mú dání lọ síbikíbi tí o bá ń lọ, o lè lò wọ́n lọ́nà gbígbéṣẹ́ nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé àti nígbà tí o bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ń kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Rí i dájú pé o ń kó oríṣiríṣi wọn dání, kí o sì máa lò wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò.—Kól. 4:17.