Máa Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Wàásù Ìhìn Rere
1. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe lo ìwé àṣàrò kúkúrú nígbà kan rí?
1 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn èèyàn Jèhófà ti ń lo ìwé àṣàrò kúkúrú láti wàásù ìhìn rere. Lọ́dún 1880, arákùnrin C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú jáde lóríṣiríṣi, wọ́n máa ń fún àwọn tó ń ka Ilé Ìṣọ́ pé kí wọ́n pín in fún àwọn èèyàn. Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí ṣe pàtàkì gan-an nígbà yẹn débi pé, nígbà tí arákùnrin C. T. Russell fẹ́ forúkọ àjọ tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1884, àṣàrò kúkúrú (ìyẹn Tract) wà lára orúkọ àjọ náà. Wọ́n pè é ní Zion’s Watch Tower Tract Society, èyí tá a wá mọ̀ sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania lónìí. Nígbà tó fi máa di ọdún 1918, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti pín ìwé àṣàrò kúkúrú tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] mílíọ̀nù. Ẹ̀rí fi hàn látìgbà yẹn pé, ìwé àṣàrò kúkúrú wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù.
2. Kí nìdí táwọn ìwé àṣàrò kúkúrú fi wúlò gan-an?
2 Ìdí Tí Àwọn Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Fi Wúlò Gan-an: Ìwé àṣàrò kúkúrú máa ń láwọ̀ mèremère. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í pọ̀, ó sì máa ń wọni lọ́kàn. Kódà àwọn onílé tí kì í fẹ́ ka ìwé ńlá tàbí àwọn ìwé ìròyìn wa máa ń fẹ́ láti ka àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú. Ó tiẹ̀ máa ń rọrùn fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde àtàwọn ọmọdé pàápàá láti lò ó lóde ẹ̀rí. Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú kì í tóbi, wọ́n sì rọrùn láti fi sápò.
3. Sọ ìrírí tó o ní tàbí èyí tó o kà tó jẹ́ ká mọ bí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ṣe wúlò tó?
3 Ìwé àṣàrò kúkúrú tí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíì kà ló jẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Haiti rí ìwé àṣàrò kúkúrú kan lójú ọ̀nà. Ó mú un, lẹ́yìn tó kà á, tìdùnnú-tìdùnnú ló fi sọ pé “Mo ti rí òtítọ́!” Ká má fọ̀rọ̀ gùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi. Ìrírí yìí jẹ́ ká rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú lágbára gan-an.
4. Kí ni àfojúsùn wa láwọn oṣù tá a bá ń lo ìwé àṣàrò kúkúrú lóde ẹ̀rí?
4 Ìwàásù Ilé-Dé-Ilé: Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù November, àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yóò máa wà lára àwọn ìwé tá a ó máa lò lóde ẹ̀rí látìgbàdégbà, torí pé wọ́n wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù. Àfojúsùn wa kì í ṣe ká kàn ṣáà ti fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú, ṣùgbọ́n a fẹ́ máa fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn. Bí ẹni tá a bá sọ̀rọ̀ nígbà àkọ́kọ́ tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a lè fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án, ká lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì. Báwo la ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé? Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà yàtọ̀ síra, torí náà, ó yẹ ká mọ ohun tó wà nínú àwọn èyí tá a bá fẹ́ lò dáadáa.
5. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé?
5 Ó yẹ ká ronú nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù wa àti ìwé àṣàrò kúkúrú tá a fẹ́ lò, ká lè mọ bá a ṣe fẹ́ gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀. A lè kọ́kọ́ fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Àwòrán mèremère tó wà lára ìwé náà sì lè fà wọ́n mọ́ra. A tún lè fi oríṣiríṣi ìwé àṣàrò kúkúrú han onílé, ká wá sọ fún un pé kó mú èyí tó bá wù ú. Tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn kì í ti í fẹ́ ṣílẹ̀kùn, a lè fi àwòrán tó wà lára ìwé àṣàrò kúkúrú tá a mú dání hàn wọ́n tàbí ká sọ fún wọn pé a fẹ́ fi ìwé náà sábẹ́ ilẹ̀kùn wọn kí wọ́n lè rí i. Tó bá jẹ́ pé ìbéèrè ni àkòrí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, a lè ní kó sọ ohun tó rò nípa ìbéèrè náà. A sì lè bi í ní ìbéèrè tó máa nífẹ̀ẹ́ sí, ká sì fìyẹn bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Lẹ́yìn náà, a lè ka apá kan nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà fún un, ká sì máa dánu dúró níbi tí ìbéèrè bá wà kí onílé náà lè sọ èrò tirẹ̀. A tún lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìpínrọ̀ náà. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jọ ka apá kan nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ẹ lè ṣàdéhùn ìgbà tẹ́ ẹ máa pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni náà. Tí ìjọ yín bá sábà máa ń fi àwọn ìwé sílẹ̀ sẹ́nu ọ̀nà àwọn tí ẹ kì í bá nílé, ẹ lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú sápá ibi tí àwọn ẹlòmíì kò ti ní rí i tí onílé kò bá sí nílé.
6. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tá a bá ń jẹ́rìí ní òpópónà?
6 Ìjẹ́rìí Òpópónà: Ǹjẹ́ o ti lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú rí nígbà tó ò ń jẹ́rìí ní òpópónà? Àwọn míì máa ń kánjú tí wọ́n bá ń rìn ní òpópónà, wọn kì í sì í fẹ́ dúró láti gbọ́ nǹkan kan. Ìyẹn lè mú kó ṣòro láti mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Dípò ká fún wọn ní àwọn ìwé ìròyìn wa tuntun láìmọ̀ bóyá wọ́n máa kà á tàbí wọn kò ní kà á, ì bá dáa ká fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú. Torí pé àwòrán tó wà lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú máa ń fani mọ́ra, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò sì pọ̀, ìyẹn lè mú kó wù wọ́n láti kà á nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tí wọn kò bá kánjú, a lè sọ díẹ̀ nínú ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà fún wọn.
7. Sọ àwọn ìrírí tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà.
7 Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-Bí-Àṣà: Ó rọrùn láti lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tá a bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Arákùnrin kan máa ń kó àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú bíi mélòó kan sínú àpò aṣọ rẹ̀ tó bá ń jáde nílé. Ó sì máa ń fún àwọn tó bá rí níbi tó ń lọ, irú bí akọ̀wé ilé ìtajà. Nígbà táwọn tọkọtaya kan fẹ́ rìnrìn-àjò afẹ́, wọ́n mú ìwé kékeré tá a fi ń wàásù fún àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè dání, ìyẹn Good News for People of All Nations, àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lóríṣiríṣi èdè, torí wọ́n ronú pé àwọn lè bá àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú ilẹ̀ pàdé. Torí náà, tí wọ́n bá gbọ́ tí ẹnì kan sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn bóyá ẹni náà ń tajà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tàbí ó jókòó sí ìtòsí wọn níbi ìṣeré tàbí nílé oúnjẹ, wọ́n máa fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú ní èdè ìbílẹ̀ rẹ̀.
8. Báwo ni àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ṣe dà bí irúgbìn?
8 “Fún Irúgbìn Rẹ”: Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú dà bí irúgbìn. Àwọn àgbẹ̀ máa ń fọ́n irúgbìn wọn ká dáadáa, torí wọn kò mọ èyí tó máa hù, tó sì máa dàgbà nínú wọn. Oníwàásù 11:6 sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa “bá a nìṣó ní títan ìmọ̀ kálẹ̀” nípa lílo àwọn ìwé tó wúlò gan-an yìí.—Òwe 15:7.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù November, àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yóò máa wà lára àwọn ìwé tá a ó máa lò lóde ẹ̀rí látìgbàdégbà, torí pé wọ́n wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù