Àwọn Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Wa Tuntun Ṣàrà Ọ̀tọ̀!
1. Àwọn nǹkan tuntun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo la máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
1 Ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun márùn-ún ló jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!” ti ọdún 2013. Bákan náà, a ti fi Ìròyìn Ìjọba No. 38, tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?” kún àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa. A ṣe àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́fà yìí lọ́nà tuntun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí nìdí tá a fi ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun tá a ṣe lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé?
2. Kí nìdí tá a fi ṣe àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
2 Kí Nìdí Tá A Fi Ṣe Wọ́n Lọ́nà Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀?: Àwọn nǹkan mẹ́rin yìí ló sábà máa ń mú kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé: (1) Kọ́kọ́ béèrè ìbéèrè kan tó máa jẹ́ kó o mọ èrò ẹni tó o fẹ́ wàásù fún. (2) Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. (3) Fún un ní ìwé kan tó máa kà. (4) Béèrè ìbéèrè kan tó o máa wá dáhùn nígbà míì, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ. Ọ̀nà tuntun tá a gbà ṣe àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà máa mú kó rọrùn láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin tá a sọ yìí.
3. Báwo la ṣe lè fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
3 Bó O Ṣe Máa Lò Wọ́n: (1) Lẹ́yìn tó o bá kí onílé, fi ìbéèrè tó wọni lọ́kàn tó wà níwájú ìwé náà àti onírúurú ìdáhùn tá a kọ síbẹ̀ hàn án, kí o sì ní kó sọ èrò rẹ̀. (2) Ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kó o sì jíròrò “Ohun tí Bíbélì Sọ.” Tó bá ṣeé ṣe, inú Bíbélì ni kó o ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Bí onílé náà bá ráyè, jíròrò àkòrí tá a pè ní “Àǹfààní Tí Ọ̀rọ̀ Yẹn Lè Ṣe fún Ẹ.” (3) Fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kó o sì ní kó gbìyànjú láti ka àwọn ibi tó kù nígbà tó bá ráyè. (4) Kó o tó fi ibẹ̀ sílẹ̀, fi ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé náà hàn án, nibi tá a pè ní “Rò Ó Wò Ná,” kó o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè náà.
4. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà nígbà tá a bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò?
4 Ó tún rọrùn láti lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà fún ìpadàbẹ̀wò. Lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti dáhùn ìbéèrè tó o bi onílé nígbà tẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. Kó o tó kúrò níbẹ̀, tọ́ka sí àwòrán ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ tó wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà, fi ìwé náà àti ẹ̀kọ́ tó ṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa kókó tẹ́ ẹ jọ jíròrò hàn án, kó o sì fún un ní ìwé náà. Tó bá gba ìwé náà, ṣètò láti pa dà wá jíròrò rẹ̀ nígbà míì. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lo bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn! Ohun míì tó o tún lè ṣe ni pé, dípò kó o fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú míì, kó o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò rẹ̀.
5. Báwo làwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ṣe wúlò tó lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
5 Ó ti lé ní àádóje [130] ọdún báyìí tá a ti ń lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Lóòótọ́, àwọn kan fẹ̀, àwọ́n míì sì kéré, ọ̀nà tá a sì gbà ṣe wọ́n yàtọ̀ síra, síbẹ̀ wọ́n wúlò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ ká máa lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun yìí lọ́nà rere ká lè máa bá a nìṣó láti mú kí ìmọ̀ Bíbélì lọ káàkiri ayé.—Òwe 15:7a.