Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 28
Orin 35 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 6 ìpínrọ̀ 9 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 19-22 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Àsọyé. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù May, kí o sì gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn. Lo àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
15 min: “Àwọn Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Wa Tuntun Ṣàrà Ọ̀tọ̀!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn alápá méjì kan. Kí àṣefihàn àkọ́kọ́ dá lórí bá a ṣe lè lo ọ̀kan lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, kí ìkejì sì jẹ́ ìgbà tá a pa dà lọ bẹ ẹni náà wò ká lè máa bá ìjíròrò wa nìṣó.
10 min: “Fídíò Tuntun Tí A Ó Máa Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Àsọyé. Ẹ wo fídíò náà tàbí kí ẹ jẹ́ kí àwọn ará gbọ́ ohùn nìkan. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà lo fídíò náà.
Orin 75 àti Àdúrà