Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 21
Orin 132 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 6 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 15-18 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 15:20–16:5 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àbájáde Jíjọ́sìn Ère—td 9B (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure—lr orí 15 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Bá A Ṣe Lè Fèsì Tẹ́nì Kan Ò Bá Fẹ́ Gbọ́ Ìwàásù Wa. Ìjíròrò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Sọ ohun méjì tàbí mẹ́ta tí àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù yín, àmọ́ tí kò sí nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe lè fèsì. Ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
15 min: Máa Fi Ọ̀yàyà Wàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 118, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 119, ìpínrọ̀ 5. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 92 àti Àdúrà