Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 15
Orin 101 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 28 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 10-12 (10 min.)
No. 1: Dáníẹ́lì 11:15-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Kì Í Fi Í Gbẹ̀san—Róòmù 12:18-21 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Lè San Ìràpadà Náà—td 27B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé, ‘Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí I.’ Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8 àti 9. Ẹ jíròrò díẹ̀ lára àwọn àbá tó wà níbẹ̀ nípa bí a ṣe lè dá ẹni tó bá sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa lóhùn àtàwọn nǹkan míì táwọn ará ti ṣe láṣeyọrí nígbà tí wọ́n bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé. Ṣe àṣefihàn méjì.
20 min: “Máa Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Wàásù Ìhìn Rere.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ karùn-ún, sọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ fẹ́ lò lóde ẹ̀rí lóṣù November, kó o sì ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 7, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú láti fi jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà.
Orin 97 àti Àdúrà