Orin 106
Bá A Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 15)
1. Ta ni ọ̀rẹ́ rẹ Jáà?
Táá máa gbé àgọ́ rẹ?
Ta lo mú lọ́rẹ̀ẹ́? Tóo fọkàn tán?
Tó sì mọ̀ ọ́ dunjú?
Àwọn tó ńgbọ́rọ̀ rẹ,
Tó sì tún nígbàgbọ́,
Àwọn olóòótọ́, olódodo,
Adúróṣinṣin ni.
2. Ta ni ọ̀rẹ́ rẹ Jáà?
Ta ni yóò tọ̀ ọ́ wá?
Táá múnú rẹ dùn, Tóo sì láyọ̀?
Tí wàá forúkọ mọ̀?
Àwọn tó ńgbé ọ ga,
Tó ńpa Ọ̀rọ̀ rẹ mọ́,
Àwọn tó ńsòótọ́, tí kìí purọ́
Tó ṣeé fọkàn tán ni.
3. Gbogbo àníyàn wa,
La kó wá o Baba.
O ńfà wá mọ́ra, o sì fẹ́ wa,
O sì ń tọ́jú wa,
A fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ.
Ká jọ rẹ́ títí láé.
Kò sí Ọ̀rẹ́ míì tó ju tìrẹ,
Kò s’Ọ́rẹ̀ẹ́ míì t’áó ní.
(Tún wo Sm. 139:1; 1 Pét. 5:6, 7.)