Jehofa—Ojúlùmọ̀ Rẹ Tabi Ọ̀rẹ́ Rẹ?
“JOHN, ṣe kí ń mú ọ mọ ọ̀rẹ́ mi? Ẹni yii ni—jọwọ, ki ni orukọ yẹn lẹẹkan sii ná?”
Iwọ ha ti gbọ́ iru aṣiṣe ninu ijumọsọrọpọ bi eyi rí bi? Ó funni ni apẹẹrẹ kan nipa bi awọn eniyan ṣe ń ṣi ọrọ naa “ọ̀rẹ́” lò. Niti gidi ohun ti wọn ní lọ́kàn ni “ojúlùmọ̀” tabi nigba miiran ki o má tilẹ jẹ́ iyẹn. Jíjẹ́ ojúlùmọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Lágbájá ni odikeji títì jẹ́ ohun kan; jíjẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ ohun miiran gédégédé.
Iwe atumọ èdè kan ṣetumọ “ojúlùmọ̀” si “eniyan kan ti ẹnikan ni ìbápàdé ẹgbẹ-oun-ọgba diẹ pẹlu ṣugbọn ti oluwaarẹ kò ni isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara pẹlu rẹ̀.” Ó fi “mímọ̀ dunju ìjẹ́tímọ́tímọ́, ìbákẹ́gbẹ́, ati idaniyan rere ti o rẹlẹ si ti Ọ̀RẸ́” hàn.
Aini isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara yii ṣeranwọ lati ṣalaye idi ti a kò fi ń kọbiara si ohun ti ń ṣẹlẹ si awọn ojúlùmọ̀, nigba ti a ń fi tẹ̀ríntẹ̀yẹ lọwọ ninu igbesi-aye awọn ọ̀rẹ́ wa. A ń ṣajọpin awọn ayọ ati ibanujẹ wọn, ní jíjẹ́ kí wọn kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Nitootọ, a gbọdọ ṣọra ki a maṣe jẹ ki ìlọ́wọ́sí onigboonara ṣì wá lọna sinu dídásí awọn àlámọ̀rí ìdákọ́ńkọ́ wọn.—1 Peteru 4:15.
Níní isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara fun awọn ọ̀rẹ́ wa tun ṣalaye idi ti a fi maa ń gbiyanju lọna bibojumu lati tẹ́ wọn lọ́rùn. Bi ìwà wa kò bá dùn mọ́ ojúlùmọ̀ kan tabi kò bojumu, ibinu rẹ̀ ni kò ṣeeṣe ki o sún wa lati yipada. Ṣugbọn ọ̀rẹ́ kan lè lo agbara idari lilagbara gan-an, ìbáà jẹ́ ninu awọn ọ̀ràn iwọṣọ, ìwà, tabi iṣarasihuwa.
Niti ọ̀ràn igbẹkẹle, ifẹni, ọ̀wọ̀, ati iduroṣinṣin, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ beere fun ìwọ̀n ẹru-iṣẹ giga ju bi ipo ojúlùmọ̀ ti ṣe lọ. Ẹni ti o beere fun ìbádọ́rẹ̀ẹ́ laini ẹru-iṣẹ kankan ninu, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe o jẹ́, niti gidi fẹ́ ojúlùmọ̀ nikan, kì í ṣe ọ̀rẹ́ kan. Awọn ọ̀rẹ́ timọtimọ a maa layọ lati mú awọn ẹru-iṣẹ tí isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara ní ninu ṣẹ, ni mímọ̀ pe iwọnyi fun wọn ni anfaani lati fẹ̀rí ipo ọ̀rẹ́ wọn han.
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pẹlu Ọlọrun
Gẹgẹ bi Ẹlẹdaa, Jehofa ni Baba ọ̀run iran eniyan ó sì yẹ ni fífẹ́ràn, ṣiṣegbọran si, ati bibọwọ fun. Ṣugbọn ó fẹ́ ki awọn eniyan ṣe eyi nitori isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara kan, ki i wulẹ ṣe nitori èrò ojuṣe lasan. (Matteu 22:37) Ó tun fẹ́ ki wọn nifẹẹ oun gẹgẹ bi Ọ̀rẹ́ kan. (Orin Dafidi 18:1) “Nitori oun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa,” oun funraarẹ ti fi ipilẹ pipe lélẹ̀ fun iru ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹẹ.—1 Johannu 4:19.
Awọn obi wa akọkọ, Adamu ati Efa, mọ Jehofa dunju. Ibeere naa ni pe: Wọn yoo ha tẹwọgba ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti o nawọ rẹ̀ si wọn bi? Ó dunni lati sọ pe, wọn kò ṣe bẹẹ. Iháragàgà onimọtara-ẹni nikan wọn fun idaduro lominira kuro lọdọ Ọlọrun kò fi imọlara isopọmọra ti ara-ẹni lilagbara hàn. Wọn muratan lati tẹwọgba awọn ibukun ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti ó ń nawọ rẹ̀ si wọn, wọn kò muratan lati mú ẹru-iṣẹ rẹ̀ ṣẹ. Ńṣe ni ó dabi pe wọn fẹ́ lati gbadun awọn itura ati aabo ti ile Paradise onigbẹdẹmukẹ wọn laimuratan lati san owo ile gbígbé.
Gbogbo wa, awọn kan dé ìwọ̀n ti ó ga ju ti awọn miiran lọ, ti jogun ẹmi alaimọriri ati onidaaduro lominira yii. (Genesisi 8:21) Awọn ọ̀dọ́ eniyan kan, fun apẹẹrẹ, ti fààyè gba ifẹ-ọkan àdánidá wọn fun idaduro-lominira lati mu ki wọn di alainimọriri fun awọn obi wọn. Eyi ti yọrisi iwolulẹ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ṣiṣeyebiye julọ ti o lè wà laaarin wọn ati awọn obi wọn jalẹ igbesi-aye. Bi o ti wu ki o ri, bi eyi ti banininujẹ tó, iwolulẹ ninu ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹlu Baba wa ọ̀run ni o burujai lọpọlọpọ jù. Nitootọ, ó lè jẹ aṣekupani!
Awọn Ohun Ti Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Beere Fun
Laisi igbẹkẹle, kò sí ipo ibatan ti o lè tọ́jọ́, ìbáà jẹ́ pẹlu awọn eniyan tabi pẹlu Ọlọrun. Olori idile naa Abrahamu loye eyi, idi sì niyẹn ti o fi fi igbẹkẹle patapata ninu Ọlọrun han leralera. Ka Genesisi 12:1-5 ati 22:1-18, ki o sì rí awọn apẹẹrẹ titayọ meji nipa igbẹkẹle rẹ̀ ninu Jehofa. Bẹẹni, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, a sì kà á sí ododo fun un.” Idi niyẹn ti a fi “pè é ni ọ̀rẹ́ Ọlọrun.”—Jakọbu 2:23.
Ohun kan siwaju sii tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu Ọlọrun beere fun ni dídójú ìlà awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yii wémọ́. Nitori ipo rirẹlẹ wa ni ifiwera si Jehofa, awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe wọnyi pọ̀ gidigidi lọna ti o ba ọgbọn mu ju bi wọn yoo ti rí ninu ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu eniyan kan. Wọn lọ rekọja fífẹ́ ti a fẹ́ lati wù ú ninu awọn ohun melookan—gẹgẹ bi a o ti ṣe pẹlu ọ̀rẹ́ eniyan kan. Wọn ní fífẹ́ ti a fẹ́ lati wù ú ninu ohun gbogbo ninu. Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun ati ọ̀rẹ́ timọtimọ julọ, fi eyi han nigba ti o sọ nipa Jehofa pe: “Emi ń ṣe ohun ti o wù ú nigba gbogbo.”—Johannu 8:29.
Nipa bayii, ìbádọrẹ̀ẹ́ pẹlu Jehofa, tabi pẹlu Ọmọkunrin rẹ̀, ni kò ṣeeṣe lori ipilẹ igí-dá-ẹyẹ́-fò; ó sinmi lori gbigbe ni ibamu pẹlu ohun akọkọ-beere fun ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti wọn ti gbekalẹ. (Wo Orin Dafidi 15:1-5.) Jesu fi eyi han kedere ninu ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. “Ọ̀rẹ́ mi ni ẹyin íṣe,” ni o sọ fun wọn, “bi ẹ bá ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun yin.”—Johannu 15:14.
Ohun miiran ti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ beere fun ni ijumọsọrọpọ ti o ṣe fàlàlà ati olotiitọ-inu. Ni ọjọ iku rẹ̀, Jesu sọ fun awọn aposteli rẹ̀ oluṣotitọ pe: “Emi kò pè yin ni ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ ohun ti oluwa rẹ̀ ń ṣe: ṣugbọn emi pè yin ni ọ̀rẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi han fun yin.” (Johannu 15:15) Ni ṣiṣajọpin èrò rẹ̀ pẹlu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Jesu ń tẹle apẹẹrẹ Baba rẹ̀ ọ̀run, nipa ẹni ti Amosi 3:7 sọ pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ki yoo ṣe nǹkan kan, ṣugbọn o fi ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ han awọn wolii iranṣẹ rẹ̀.”
Eyi ha kọ ni ohun ti a saba maa ń rí laaarin awọn ọ̀rẹ́ bi? A lè má ní ìsúnniṣe kankan lati ṣajọpin awọn iriri wa pẹlu Ọ̀gbẹ́ni Lágbájá ti ó wà lodikeji títì. O sì daju hán-ún-hán-ún pe awa ki yoo fẹ́ lati sọ awọn èrò ati imọlara inu wa lọhun-un fun un. Ó ṣetan, ojúlùmọ̀ lasan ni. Ṣugbọn fun awọn ọ̀rẹ́ wa, eeṣe, niye ìgbà ekukáká ni a fi lè duro lati sọ iru awọn nǹkan bẹẹ fun wọn!
Bakan naa ni ó rí ninu ipo ọ̀rẹ́ wa pẹlu Ọlọrun. Ekukáká ni a fi lè duro lati tọ̀ ọ́ lọ ninu adura, ní ṣíṣí awọn aini wa, awọn ifẹ-ọkan wa, ati awọn imọlara inu lọhun-un julọ wa payá fun un. Dajudaju, bi ijumọsọrọpọ bá jẹ́ alapakan, ipo ọ̀rẹ́ yoo parẹ laipẹ. Nitori naa a gbọdọ tun muratan lati jẹ ki Ọlọrun bá wa sọrọ. Eyi ni a ń ṣe nipa fifi tiṣọratiṣọra fetisilẹ si Ọrọ Ọlọrun, ni rironu jinlẹ lori imọran rẹ̀, ati lẹhin naa ki a fi i silo bi a ṣe lè ṣe daradara julọ tó.
Bawo ni Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Jehofa Ṣe Ṣe Pataki Fun Ọ Tó?
Lati ràn ọ́ lọwọ lati dahun ibeere yii, gbé iru akanṣe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ eniyan kan yẹwo. Bi iwọ bá jẹ ọdọ eniyan, boya o nifẹẹ-ọkan ninu ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti ó lè ṣamọna si igbeyawo. Dajudaju, iwọ mọ pe wiwulẹ dojulumọ pẹlu ẹnikeji ti a fojusọna fun ni ó ṣoro ki o jẹ́ ipilẹ bibojumu fun igbeyawo. Ipo ojúlùmọ̀ ni a kọ́kọ́ gbọdọ yipada si ìbádọ́rẹ̀ẹ́. Ipo ọ̀rẹ́ yii ni a lè mú dagba lẹhin naa ki a sì yí i pada si ipo ibatan ti o tubọ ṣe timọtimọ ti yoo di ipilẹ bibojumu lẹhin-ọ-rẹhin fun igbeyawo alayọ kan.
Wàyí o, gbé eyi yẹwo. Bawo ni isapa tí ọpọ julọ eniyan ń fi sinu mímú iru ìbádọrẹ̀ẹ́ yii dagba ti pọ̀ tó? Bawo ni akoko ati owo ti wọn ń ná ninu fifidi rẹ mulẹ ati pipa a mọ́ ti pọ̀ tó? Bawo ni akoko ti wọn ń lo lati ronu nipa rẹ̀ ti pọ̀ tó? Dé ìwọ̀n àyè wo ni wọn ń ṣe awọn iwewee—tabi fi imuratan lati yí awọn iwewee pada han—fun ète mímú un sunwọn sii tabi pipa ipo ibatan yii mọ?
Lẹhin naa beere lọwọ araarẹ: ‘Bawo ni eyi ṣe ṣeefiwera pẹlu awọn isapa mi lati mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu Ẹlẹdaa mi dagba tabi lati mú un sunwọn sii ki ń si fún un lokun? Bawo ni akoko ti mo ń lò ninu ṣiṣe bẹẹ ti pọ̀ tó? De iwọn àyè wo ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu Jehofa ń gba awọn ironu mi? Dé ìwọ̀n àyè wo ni mo ń ṣe awọn iwewee—tabi fi imuratan han lati yí awọn iwewee pada—fun ète mimu un sunwọn sii ati pipa ipo ibatan yii mọ́ lẹhin naa?’
Awọn Kristian ọ̀dọ́ gbọdọ mọ̀ ni kikun pe gbogbo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ eniyan, ti ó ní ninu ọ̀kan ti ń yọrisi igbeyawo lẹhin-ọ-rẹhin, jẹ́ ipo keji ni ijẹpataki si ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti o yẹ ki wọn ní pẹlu Ẹlẹdaa wọn. Idi niyẹn ti a fi rọ̀ wọn ni Oniwasu 12:1 pe: “Ranti Ẹlẹdaa rẹ nisinsinyi ni ọjọ èwe rẹ.” Ọpọlọpọ ń ṣe eyi nipa ṣiṣiṣẹsin ni gbangba gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun, iye ti ń pọ sii ṣáá ninu wọn gẹgẹ bi oniwaasu alakooko kikun, tabi aṣaaju-ọna.
Laika ìwà ìṣáátá ati àìlẹ́mìí-ìsìn ti ń gbilẹ layiika wọn sí, awọn wọnyi fi tigboyatigboya gbèjà Jehofa nigba ti wọn bá gbọ́ awọn ẹ̀gàn ati ẹ̀sùn èké ti a ṣe lodisi i. Eyi ki i ha ṣe ohun ti Jehofa gbọdọ fi ẹ̀tọ́ lè reti lati ọ̀dọ̀ awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bi? Ki i ha ṣe eyi ni ohun ti awa pẹlu yoo reti lọdọ awọn ọ̀rẹ́ wa? Kì yoo ha sì mú ọkan-aya wa yọ̀ nigba ti a bá ri i ti awọn ọ̀rẹ́ wa ń ṣe é titaratitara ati pẹlu idaniloju bi?—Fiwe Owe 27:11.
Bẹẹni, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu Ọlọrun—ani gẹgẹ bi o ti rí pẹlu awọn eniyan paapaa—ń mú awọn ẹru-iṣẹ ti a gbọdọ muṣẹ dani bi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ naa yoo bá tọ́jọ́. Ẹnikan ti kò muratan lati tẹwọgba awọn ẹru-iṣẹ wọnyi, tabi ti kò ṣetan lati ṣe iyasimimọ si Ọlọrun ki ó sì wá mú un ṣẹ lẹhin naa, lè jẹ́ ojúlùmọ̀ niti gidi pẹlu Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, oun kò tíì niriiri, ayọ ti níní In gẹgẹ bi Ọ̀rẹ́ kan sibẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Abrahamu gbẹkẹle Ọlọrun ati nitori naa ó di ẹni ti a ń pè ni ọ̀rẹ́ Jehofa