Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
“Èmi àti ọ̀rẹ́ mi jùmọ̀ ń ṣàjọpín ọkàn-ìfẹ́ àti ìgbòkègbodò púpọ̀; a ń gbádùn lílo àkókò pọ̀. Ṣùgbọ́n lójijì, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa kò dán mọ́rán mọ́. Ìyẹ́n mú mi sorí kọ́ gan-an.”—Maria.
O TI rí ọ̀rẹ́ kan nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ẹnì kan tí ó lóye rẹ, tí kò wulẹ̀ ń dá ọ lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n lójijì, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín bẹ̀rẹ̀ sí í yìnrìn. O sapá láti gbà á là, ṣùgbọ́n o kò ṣàṣeyọrí.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ kò ṣeé díye lé. (Owe 18:24) Pípàdánù ọ̀kan sì lè dunni wọra. Bibeli sọ fún wa pé, nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó kédàárò pé: “Àwọn àjọbí mi fà sẹ́yìn, àwọn àfaramọ́ ọ̀rẹ́ mi sì di onígbàgbé mi.” (Jobu 19:14) O lè nímọ̀lára másùnmáwo kan náà bí o bá ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan tí ó bà jẹ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Gẹ́gẹ́ bí Patrick ọ̀dọ́ ṣe sọ ọ́, “ó máa ń dà bíi pé ẹnì kan tí o fẹ́ràn kú.” Ṣùgbọ́n bí ó bá hàn kedere pé gbogbo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí o tí ì ní ń forí ṣánpọ́n ńkọ́?
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Ẹlẹgẹ́
Ìwé Adolescence tí Eastwood Atwater kọ ṣàkíyèsí pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́langba “kì í dúró sójú kan, tí ó sì máa ń fa ìyípadà òjijì, tí ó hàn gbangba àti ìmọ̀lára ìbànújẹ́ nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ náà bá tú ká.” Kí ló mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́langba gbẹgẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, bí o ti ń dàgbà sí i, àwọn ìmọ̀lára, ojú ìwòye, ohun àfojúsùn, àti ọkàn-ìfẹ́ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. (Fi wé 1 Korinti 13:11.) O lè rí i pé o ń fò fẹ̀rẹ̀ lọ níwájú àwọn ojúgbà rẹ—tàbí pé o ń pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn wọn—ní àwọn ọ̀nà kan.
Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ bá ń dàgbà, ìbátan tímọ́tímọ́ wọn máa ń dín kù—kì í ṣe nítorí pé wọ́n bá ara wọn jà, bí kò ṣe nítorí pé wọ́n ní ohun àfojúsùn, ọkàn-ìfẹ́, àti ohun ìdíyelé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó tilẹ̀ lè dára jù lọ láti fòpin sí àjọṣepọ̀ náà. Bí o ṣe ń dàgbà sí i, tí o sì ń fọwọ́ ìjẹ́pàtàkì mú àwọn ohun tẹ̀mí lọ́nà tí ó jinlẹ̀ sí i, o lè wá mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́ kò nípa rere lórí rẹ. (1 Korinti 15:33) O bìkítà nípa wọn, àmọ́, o kì í gbádùn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ wọn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.
Àwọn Ohun Tí Ń Ba Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Jẹ́
Èwo wá ni ṣíṣe bí o bá ṣáà ń pàdánù ọ̀rẹ́ léraléra ṣáá—ipò ìbátan kan tí ìwọ ì bá fẹ́ láti ṣìkẹ́? Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó lè jẹ́ pé o ní àbùkù ìhùwàsí tí o ní láti borí. Fún àpẹẹrẹ, owú ń ba ìbádọ́rẹ̀ẹ́ jẹ́. Ronú pé o ní ọ̀rẹ́ kan tí ó ní ọlá, ẹ̀bùn nǹkan ṣíṣe, ẹwà, tàbí òkìkí jù ọ́ lọ. O ha ń bínú nítorí àfiyèsí tí ó lè gbà jù ọ́ lọ bí? “[Owú, NW] ni ìbàjẹ́ egungun.” (Owe 14:30) Keenon ọ̀dọ́ jẹ́wọ́ pé: “Ní ti gidi, mo máa ń ṣe ìlara òkìkí ọ̀rẹ́ mi àti gbogbo ohun tí ó ní tí n kò ní, ó sì nípa lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa.”
Ìrònú ẹ-máà-bá-mi-dù-ú lè jẹ́ ànímọ́ mìíràn tí ń ba nǹkan jẹ́. Bí o bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan ń lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ju ìwọ lọ ńkọ́? Èwe kan jẹ́wọ́ pé: “Mo tilẹ̀ máa ń jowú bí àwọn mìíràn bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi kan sọ̀rọ̀.” O lè wo ìbákẹ́gbẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn mìíràn bí ìwà ọ̀dàlẹ̀.
Ríretí ìjẹ́pípé pẹ̀lú lè mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ forí ṣánpọ́n. Fún àpẹẹrẹ, o lè gbọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan ń sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, bóyá tí ó tilẹ̀ ń tú àṣírí àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ rẹ. (Owe 20:19) O lè fìbínú sọ pé: “N kò lè finú hàn án mọ́ láéláé!”
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́—Gbígbà Tàbí Fífúnni?
Bí owú, ìrònú ẹ-máà-bá-mi-dù-ú, tàbí ìrètí ìjẹ́pípé bá ti ba àwọn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ jẹ́, bi ara rẹ pé, ‘Kí ni mo ń fẹ́ nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan?’ O ha ń ronú pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ mímú ẹnì kan wà lárọ̀ọ́wọ́tó, bí ìránṣẹ́ kan láti máa ṣe ohun tí o bá ti fẹ́ bí? O ha ń fẹ́ ọ̀rẹ́ fún iyì, òkìkí, tàbí èrè bí? O ha ń retí ìfọkànsìn àyàsọ́tọ̀ lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ kan láìfàyè púpọ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn nínú àjọṣepọ̀ náà bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ó yẹ kí o ṣàtúnṣe èrò rẹ nípa ìbádọ́rẹ̀ẹ́.
Láti inú ohun tí Bibeli kọ́ni, a mọ̀ pé ipò ìbátan rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kò sinmi lórí rírí gbà, bí kò ṣe lórí fífúnni! Ní Matteu 7:12, Jesu Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé: “Nitori naa, gbogbo ohun tí ẹ̀yin bá fẹ́ kí awọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ̀yin pẹlu gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” Ó wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu láti retí àwọn ohun kan lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹni. Ìwé Understanding Relationships gbà pé: “Nígbà gbogbo ni a ń retí kí ọ̀rẹ́ kan jẹ́ aláìlábòsí àti aláìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí ń fi ìfẹ́ni hàn, tí ń fi àwọn àṣírí àti ìṣòro rẹ̀ hanni, tí ń ranni lọ́wọ́ nígbà tí a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, tí ń fọkàn tánni, tí ó sì . . . ń múra tán láti yanjú èdèkòyédè.” Bí ó ti wù kí ó rí, kò tán síbẹ̀. Ìwé náà fi kún un pé: “Àwọn nǹkan kan ń bẹ tí àwọn ènìyàn ń retí kí ọ̀rẹ́ ṣe fún wọn àti kí àwọn náà padà ṣe fún ọ̀rẹ́.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Kíyè sí ọ̀nà tí Jesu fúnra rẹ̀ gbà bá àwọn tí wọ́n sún mọ́ ọn lò. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Emi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nitori pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn emi ti pè yín ní ọ̀rẹ́.” Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ karí ohun tí wọ́n lè ṣe fún un bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Ó wí pé: “Kò sí ẹni kan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹni kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nitori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Johannu 15:13, 15) Bẹ́ẹ̀ ni, ojúlówó ìpìlẹ̀ fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ni ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ! Nígbà tí ìfẹ́ bá jẹ́ ìpìlẹ̀, àjọṣepọ̀ kán lè la rúkèrúdò àti ìṣòro já.
Nígbà Tí Ìṣòro Bá Wà
Fún àpẹẹrẹ, ronú pé ọ̀rẹ́ rẹ ní owó, ọpọlọ, tàbí ẹ̀bùn nǹkan ṣíṣe jù ọ́ lọ. Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan yóò sún ọ láti bá ọ̀rẹ́ rẹ yọ̀. Ó ṣe tán, Bibeli sọ pé, “ìfẹ́ kì í jowú.”—1 Korinti 13:4.
Tàbí jẹ́ ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ ń sọ tàbí ṣe ohun kan tí ń bà ọ́ nínú jẹ́. Ṣé ó túmọ̀ sí pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yín gbọ́dọ̀ forí ṣánpọ́n? Dandan kọ́. A já aposteli Paulu kulẹ̀ gan-an nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀, Marku, pa á tì nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì kan. Ó le tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi gbà pé kí Marku bá òun lọ nínú ìrìn àjò tí ó tẹ̀ lé e! Paulu àti mọ̀lẹ́bí Marku, Barnaba, tilẹ̀ sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn nítorí ọ̀rọ̀ náà. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Paulu sọ̀rọ̀ ìfẹ́ni nípa Marku, tí ó tilẹ̀ ké sí i láti wá máa jíṣẹ́ fún òun ní Romu. Ó ṣe kedere pé, wọ́n ti yanjú èdèkòyédè wọn.—Ìṣe 15:37-39; 2 Timoteu 4:11.
O kò ṣe gbìyànjú ṣe ohun kan náà nígbà tí ìṣòro bá wà nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ? Má ṣe jẹ́ kí nǹkan máa burú sí i. (Efesu 4:26) Dípò kíkánjú ṣèpinnu tàbí fífẹ̀sùn kanni pẹ̀lú ìbínú, fetí sí ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ ní láti sọ. (Owe 18:13; 25:8, 9) Bóyá ẹ ṣi ara yín lóye ni. Ṣùgbọ́n bí ọ̀rẹ́ rẹ bá jẹ̀bi kíkánjú dórí ìpinnu ní tòótọ́ ńkọ́? Rántí pé, ẹ̀dá ènìyàn lásán ni ọ̀rẹ́ rẹ. (Orin Dafidi 51:5; 1 Johannu 1:10) Gbogbo wa ni a ń jẹbi sísọ àti ṣíṣe àwọn ohun tí a wá ń dẹ̀yìn kábàámọ̀ wọn.—Fi wé Oniwasu 7:21, 22.
Láìka ìyẹn sí, o lè sọ inú rẹ jáde nípa bí ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe ti pa ọ́ lára tó. Ìyẹ́n lè sún ọ̀rẹ́ rẹ láti tọrọ àforíjì tọkàntọkàn. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeléṣe,” bóyá o lè gbọ́kàn fo ọ̀ràn náà. (1 Korinti 13:5) Ní bíbojú wẹ̀yìn wo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan tí ó ti pàdánù, Keenon ọ̀dọ́ sọ pé: “Bí mo bá ní láti tún un ṣe, n kò ní retí ìjẹ́pípé nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa. N óò túbọ̀ fetí sílẹ̀ sí i, n óò sì tì í lẹ́yìn, n kì yóò sì fẹ àwọn àṣìṣe rẹ̀ lójú. Ó yé mi nísinsìnyí pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ aláṣeyọrí ń wá nípa kíkojú àwọn àdánwò àti ìpèníjà.”
Ṣùgbọ́n, bí ọ̀rẹ́ rẹ kò bá máa lo àkókò pẹ̀lú rẹ tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ tàbí tó bí o ti fẹ́ ńkọ́? Ó ha lè jẹ́ pé o fẹ́ gba àkókò àti àfiyèsí ọ̀rẹ́ rẹ ju bí ó ti yẹ lọ bí? Èyí lè fún àjọṣepọ̀ yín pa. Àwọn ènìyàn máa ń fún ara wọn ní ìwọ̀n òmìnira láti ṣe nǹkan bí wọ́n ṣe fẹ́ nínú àjọṣepọ̀ aláṣeyọrí. (Fi wé Owe 25:17.) Wọ́n ń fàyè gba àwọn ẹlòmíràn láti gbádùn ara wọn! Ó ṣe tán, Bibeli rọ àwọn Kristian láti mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn “gbòòrò síwájú.” (2 Korinti 6:13) Nítorí náà, bí ọ̀rẹ́ kan bá ṣe èyí, kò sídìí láti wò ó bí aláìṣòótọ́.
Dájúdájú, kì í ṣe èrò tí ó dára láti gbára lé ẹni pàtó kan jù lọ́nàkọnà. (Orin Dafidi 146:3) Ó bọ́gbọ́n mu láti mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn mìíràn tí kì í ṣe ojúgbà rẹ, irú bí àwọn òbí rẹ, àwọn alàgbà, àti àwọn àgbàlagbà adàgbàdénú mìíràn tí ń bìkítà. Ana sọ̀rọ̀ tìfẹ́nitìfẹ́ni pé: “Ìyá mi ni ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jù lọ. Kò sí ohun tí n kò lè bá a sọ̀rọ̀ lé lórí.”
A Lè Gbádùn Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pípẹ́ Títí!
Ní 1 Peteru 3:8, Bibeli sọ pé: “Lákòótán, gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan naa, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò-inú.” Bẹ́ẹ̀ ni, fi inú rere, ìyọ́nú, àìyẹhùn ìwà rere, àti ojúlówó àníyàn hàn fún àwọn mìíràn, ìwọ yóò sì máa ní ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́! A gbà pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pípẹ́ títí gba ìsapá àti ìpinnu. Ṣùgbọ́n èrè rẹ̀ mú wọn tọ́ fún ìsapá náà.
Ó dùn mọ́ni pé, Bibeli sọ nípa Dafidi àti Jonatani. Wọ́n gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ títayọ. (1 Samueli 18:1) Wọ́n borí owú pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti àléébù ìhùwàsí. Èyí ṣeé ṣe nítorí Dafidi àti Jonatani gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti ìdúróṣinṣin wọn lé Jehofa Ọlọrun ju lé orí ohunkóhun mìíràn lọ. Ṣe bákan náà, o kì yóò sì ní ìṣòro tó bẹ́ẹ̀ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tí ń bẹ̀rù Ọlọrun!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ sábà ń tú ká bí ẹnì kan bá ka níní àwọn ọ̀rẹ́ mìíràn sí àìṣòótọ́