Ìwọ́ Lè Gbádùn Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pípẹ́ Títí
ÀWỌN ìdènà fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wà. Ní tòótọ́, Bibeli sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, kì yóò sí ìfẹ́, ìfẹ́ni àdánidá, àti ìdúróṣinṣin. (2 Timoteu 3:1-5; Matteu 24:12) Àwọn ipò yìí ti fa ìyọnu ìdánìkanwà tí kò sí irú rẹ̀ rí. Ẹnì kan wí pé: “Ní àdúgbò mi, ṣe ni ó dà bí áàkì Noa. Bí o kò bá tí ì ṣe ìgbéyàwó, o kò lè wà pẹ̀lú wa.” A kò lè di gbogbo ẹ̀bi yìí lé ẹni tí ó nímọ̀lára ìdánìkanwà náà. Ní àwọn apá ibì kan nínú ayé, àwọn ìṣòro tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pípẹ́ títí kan àwọn nǹkan bíi ìṣíkiri léraléra àwọn ènìyàn, ìwólulẹ̀ ìdílé, àwọn ìlú ńlá eléwu tí kò sí ọ̀yàyà, àti àìsí àkókò ọwọ́dilẹ̀ tí ń pọ̀ sí i.
Iye ènìyàn tí ẹnì kan tí ń gbé ní ìlú ńlá ní òde òní bá ní ìbáṣepọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan lè ju iye tí ẹnì kan tí ó gbé abúlé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún rí ní odindi ọdún kan tàbí ní gbogbo ìgbésí ayé pàápàá lọ! Síbẹ̀, lónìí ìbáṣepọ̀ sábà máa ń jẹ́ ti ojú ayé. Ọ̀pọ̀ máa ń ri ara wọn bọnú afẹ́ ṣíṣe, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti gbádùn ara wọn. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ gbà pé, ṣíṣe àríyá asán pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí a kò yàn dáradára, dà bíi lílo ẹ̀gún fún ohun ìdáná. Oniwasu 7:5, 6 wí pé: “Ó sàn láti gbọ́ ìbáwí ọlọgbọ́n ju kí ènìyàn kí ó fetí sí orin aṣiwèrè. Nítorí pé bí ìtapàpà ẹ̀gún lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín aṣiwèrè: asán ni èyí pẹ̀lú.” Ẹ̀gún máa ń tan iná tí ó mọ́lẹ̀ tí ó sì ń pariwo fún ìgbà kúkúrú, ṣùgbọ́n kò ní agbára tó láti mú wa gbooru. Bákan náà, alábàákẹ́gbẹ́ aláriwo, tí ń rẹ́rìn-ín lè máà mú kí ọkàn wa pa pọ̀ fún àkókò kúkúrú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò lé gbogbo ìdánìkanwà wa lọ kí wọ́n sì tẹ́ àìní wa fún àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ lọ́rùn.
Wíwà ní ipò ìparọ́rọ́ yàtọ̀ sí ìdánìkanwà. Àwọn ipò ìparọ́rọ́ kan pọn dandan fún wa láti mú ìtura wá fún ara wa, kí a sì ní púpọ̀ sí i láti fún ọ̀rẹ́. Nígbà tí àwọn kan bá dojú kọ ìdánìkanwà, ọ̀pọ̀ máa ń yíjú sí àwọn ọ̀nà ìfẹ̀rọ-oníná-mànàmáná dára yá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìròyìn ìwádìí kan sọ pé, wíwo tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ohun kan tí ó wọ́ pọ̀ nínú ìhùwàpadà sí ìdánìkanwà. Síbẹ̀, àwọn olùwádìí náà parí èrò sí pé, wíwo tẹlifíṣọ̀n fún ìgbà pípẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó burú jù lọ tí a lè ṣe nígbà tí a bá dá nìkan wà. Ó ń mú ìdágunlá, ìsúni, àti àlá asán dàgbà, ní dídi ohun àfirọ́pò aláìgbéṣẹ́ fún ìbáṣepọ̀ ara ẹni pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Ní tòótọ́, ipò ìparọ́rọ́ lè ṣàǹfààní púpọ̀, kìkì bí a bá lo àkókò wa lọ́nà tí ó dára. A lè ṣe èyí nípa kíkàwé, kíkọ lẹ́tà, ṣíṣe àwọn nǹkan, àti sísinmi. Ipò ìparọ́rọ́ tí a lò lọ́nà dídára kan gbígbàdúrà sí Ọlọrun, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, àti ṣíṣàṣàrò lé e lórí. (Orin Dafidi 63:6) Àwọn wọ̀nyí ni ọ̀nà tí a fi lè sún mọ́ Jehofa Ọlọrun sí i, ẹni tí yóò jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa pàtàkì jù lọ.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Nínú Bibeli
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára láti bá ọ̀pọ̀ ènìyàn dọ́rẹ̀ẹ́, Bibeli rán wa létí pé “ọ̀rẹ́ kan sì ń bẹ tí ó fi ara mọ́ni ju arákùnrin lọ.” (Owe 18:24) Gbogbo wa ni a nílò àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ díẹ̀, tí wọ́n bìkítà nípa wa ní tòótọ́, tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn ń fún wa ní ayọ̀, okun, àti àlàáfíà. Bí irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ ṣọ̀wọ́n lónìí, àwọn àpẹẹrẹ ìgbàanì kan ni a tọ́ka sí ní pàtàkì nínú Bibeli. Fún àpẹẹrẹ, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ títayọ lọ́lá wà láàárín Dafidi àti Jonatani. Kí ni a lè kọ́ láti inú rẹ̀? Èé ṣe tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn fi pẹ́ títí?
Ìdí kan ni pé, Dafidi àti Jonatani ní ọkàn-ìfẹ́ pàtàkì kan náà. Pàtàkì jù lọ ni pé, wọ́n jọ ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ fún ìfọkànsìn Jehofa Ọlọrun. Nígbà tí ó ṣàkíyèsí ìgbàgbọ́ tí Dafidi ní nínú Ọlọrun àti àwọn ìṣe rẹ̀ ní gbígbèjà àwọn ènìyàn Jehofa, “ọkàn Jonatani sì fà mọ́ ọkàn Dafidi, Jonatani sì fẹ́ ẹ bí òun tìkara rẹ̀.” (1 Samueli 18:1) Nígbà náà, ìfẹ́ àjùmọ̀ní fún Ọlọrun ń ṣèrànwọ́ láti so àwọn ọ̀rẹ́ pọ̀ mọ́ra wọn.
Jonatani àti Dafidi jẹ́ alágbára, tí ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọrun. Nítorí náà, wọ́n lè bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (1 Samueli 19:1-7; 20:9-14; 24:6) A jẹ́ ẹni ìbùkún ni ti gidi, bí a bá ní àwọn ọ̀rẹ́ olùṣèfẹ́ Ọlọrun, tí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ń darí.
Àwọn kókó abájọ mìíràn dá kún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Dafidi àti Jonatani. Ìbáṣepọ̀ wọn jẹ́ aláìlábòsí, ó sì ṣe tààrà, ẹnì kọ̀ọ̀kan sì mú ẹnì kejì bí ẹni tí ó ṣeé finú tán. Jonatani fi pẹ̀lú ìdúróṣinṣin fi ọkàn-ìfẹ́ Dafidi ṣáájú tirẹ̀. Kò jowú nítorí pé a ti ṣèlérí pé Dafidi ni yóò jọba; kàkà bẹ́ẹ̀, Jonatani tì í lẹ́yìn ní ti èrò ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí. Dafidi sì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. (1 Samueli 23:16-18) Dafidi àti Jonatani fi ìmọ̀lára wọn hàn fún ara wọn ní àwọn ọ̀nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn oníwà-bí-Ọlọ́run ni a gbé karí ìmọrírì tòótọ́ àti ìfẹ́ni. (1 Samueli 20:41; 2 Samueli 1:26) Ọ̀rẹ́ wọn kò ṣeé tú ká, nítorí pé àwọn ọkùnrin méjèèjì dúró bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun. Mímú irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ lò, lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ dàgbà kí a sì máa bá a lọ.
Bí A Ṣe Lè Mú Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Dàgbà
O ha ń wá àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ bí? O lè máà ní láti wò jìnnà. Àwọn kan lára àwọn tí o máa ń bá kẹ́gbẹ́ nígbà gbogbo lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ, wọ́n sì lè nílò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ. Ó bọ́gbọ́n mu láti fi ìmọ̀ràn aposteli Paulu sílò pé kí a “gbòòrò síwájú,” ní pàtàkì ní ti àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni. (2 Korinti 6:11-13) Ṣùgbọ́n, má ṣe banú jẹ́ bí gbogbo ìgbìyànjú láti ní ọ̀rẹ́ kò bá yọrí sí àjọṣepọ̀ jíjinlẹ̀. Ó máa ń gba àkókò láti mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ dàgbà, kì í sì í ṣe gbogbo ìbáṣepọ̀ ni yóò jinlẹ̀ bákan náà. (Oniwasu 11:1, 2, 6) Ní tòótọ́, láti gbádùn ojúlówó ìbádọ́rẹ̀ẹ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan, a sì ní láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jesu pé: “Gbogbo ohun tí ẹ̀yin bá fẹ́ kí awọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ̀yin pẹlu gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Matteu 7:12.
Ta ní nílò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ? Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ojúgbà rẹ, àwọn ọmọ kékeré tàbí àgbàlagbà ń kọ́? Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Dafidi àti Jonatani, Rutu àti Naomi, àti Paulu òun Timoteu, jẹ́ ti àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n jìnnà síra wọn. (Rutu 1:16, 17; 1 Korinti 4:17) O ha lè nawọ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ sí àwọn opó àti àwọn tí wọn kò tí ì ṣe ìgbéyàwó bí? Tún ronú nípa àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni tuntun ní àdúgbò rẹ. Ṣíṣí kúrò ní àdúgbò, tàbí yíyí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà, ti lè mú kí wọ́n jáwọ́ nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ tàbí gbogbo ọ̀rẹ́ wọn. Má ṣe dúró kí àwọn mìíràn wá ọ wá. Bí o bá jẹ́ Kristian, ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pípẹ́ títí nípa fífi ìmọ̀ràn Paulu sílò pé: “Ninu ìfẹ́ ará ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nìkínní kejì. Ninu bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nìkínní kejì ẹ mú ipò iwájú.”—Romu 12:10.
A lè ronú nípa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbà fúnni. Jesu wí pé bí a bá sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò fún wa. Ó tún tọ́ka sí i pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ. (Luku 6:38; Ìṣe 20:35) O ha ti pàdé àwọn ènìyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀ síra bí? Àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi hàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àṣà ìbílẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra lè mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ tí ó pẹ́ títí dàgbà, nígbà tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn Ọlọrun bá rí bákan náà.
Mímú Kí Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Máa Bá A Lọ
Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn mìíràn tí a kà sí ọ̀rẹ́, máa ń fa ìbànújẹ́ fún ara wọn, nígbà míràn. Òfófó apanilára, títú àṣírí, àìnímọrírì—ìwọ̀nyí wà lára àwọn ohun tí ń dunni gan-an nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí a kà sí ọ̀rẹ́ tòótọ́. Kí ni a lè ṣe nínú irú ipò bẹ́ẹ̀?
Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti yẹra fún dídá irú ìbánújẹ́ bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Ní àwọn ibì kan, ó wọ́pọ̀ kí àwọn ọ̀rẹ́ máa fi àṣìṣe ọ̀rẹ́ wọn ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n bíbáni lò lọ́nà rírorò tàbí lọ́nà ẹ̀tàn kì yóò fa àwọn ọ̀rẹ́ pa pọ̀, àní bí wọ́n bá rò pé ‘eré ni àwọ́n ń ṣe.’—Owe 26:18, 19.
Ṣiṣẹ́ kára láti lè mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ máa bá a nìṣó. Èdè-kò-yedè máa ń jẹ yọ nígbà míràn, nígbà ti àwọn ọ̀rẹ́ bá ti ń retí ju bí ó ti yẹ lọ lọ́dọ̀ ara wọn. Ó dájú pé ọ̀rẹ́ tí ara rẹ̀ kò yá, tàbí tí ọwọ́ rẹ̀ dí nítorí pé ó ń dojú kọ ìṣòro gbígbópọn, kì yóò lè fi ọ̀yàyà hàn bíi ti tẹ́lẹ̀. Ni irú àwọn ìgbà báyìí, gbìyànjú láti gba tirẹ̀ rò, kí o sì ṣètìlẹyìn.
Ẹ yanjú aáwọ̀ kíákíá àti pẹ̀lú inú rere. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ níkọ̀kọ̀ bí ó bá ṣeé ṣe. (Matteu 5:23, 24; 18:15) Rí i dájú pé ọ̀rẹ́ rẹ mọ̀ pé o fẹ́ kí ìbáṣepọ̀ dídára máa bá a nìṣó. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń dárí ji ara wọn. (Kolosse 3:13) Ìwọ yóò ha jẹ́ irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ bí—èyí tí ń sún mọ́ni ju arákùnrin lọ?
Kíkà nípa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti ríronú nípa rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ni. Bí a bá ń nímọ̀lára ìdánìkanwà, ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ, a kì yóò sì dánìkan wà fún ìgbà pípẹ́. Bí a bá tiraka, a lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. A óò ní ìbáṣepọ̀ àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn kan nínú wọn. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó lè gba àyè Ọlọrun, Ọ̀rẹ́ pàtàkì jù lọ. Jehofa nìkan ni ó lè mọ̀, ni ó lè lóye, kí ó sì tì wá lẹ́yìn pátápátá. (Orin Dafidi 139:1-4, 23, 24) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nawọ́ àgbàyanu ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la—ayé tuntun, níbi tí yóò ti ṣeé ṣe láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ títí láé.—2 Peteru 3:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Dafidi àti Jonatani gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́, àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀