Orin 101
Sísọ Òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run Di Mímọ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ìgbà kan wà tí a kò mọ
Ọ̀nà tó yẹ kí Kristẹn’ tọ̀.
Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀
Òótọ́ Ìjọba kedere.
A wá mọ̀ pé ìfẹ́ Rẹ̀ ni
Pé ká sin Olódùmarè,
Ká pòkìkí Jèhófà,
Ká fògo fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.
A ńwàásù fún gbogbo èèyàn,
Nílé délé, ní òpópó.
A tún ńkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òótọ́;
Tó ńsọni di òmìnira.
Báa ti ńsapá níbi gbogbo
Kíjọsìn Jáà kárí ayé,
Ká máa sin Jáà níṣọ̀kan
Títí Jèhófà yóò sọ pé ó tó.
(Tún wo Jóṣ. 9:9; Aísá. 24:15; Jòh. 8:12, 32.)