Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 22
Orin 71 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 28 ìpínrọ̀ 8 sí 15 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Hóséà 1-7 (10 min.)
No. 1: Hóséà 6:1–7:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bá A Ṣe Lè Dá Ìsìn Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Tó Wà Mọ̀—td 14A (5 min.)
No. 3: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Nípa Títẹ́ńbẹ́lú Ìtìjú—Héb. 12:2 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
30 min: “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa?” Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kìíní, ojú ìwé 57 sí 63. Fi ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, kó o sì fi ìpínrọ̀ kejì parí ìjíròrò náà. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ohun tó wà nínú ìwé náà, gba àwọn ará níyànjú, pàápàá àwọn ọ̀dọ́, pé kí wọ́n wo fídíò wa tó dá lórí báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè yan ọ̀rẹ́ tó dáa, ìyẹn Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye ohun tá a jíròrò yìí dáadáa.
Orin 89 àti Àdúrà