Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa?
Jèhófà dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi lè jọ máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, ká sì tún ní àwọn tá à ń bá ṣọ̀rẹ́. (Òwe 18:1; 18:24) Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ irú àwọn tá a máa fi ṣe ọ̀rẹ́, kí àwa àtàwọn tá a bá fi ṣe ọ̀rẹ́ bàa lè jàǹfààní látinú bá a ṣe jọ ń kẹ́gbẹ́. (Òwe 13:20) Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló so àwọn ọ̀rẹ́ méjì pọ̀, wọn ò ní jẹ́ kí mìmì kankan mi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn. Ìwé Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Tí èdèkòyédè bá wáyé, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa yanjú rẹ̀ lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Báwo la ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa?
Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí pé, ó máa ń rọrùn fáwọn tá a bá jọ ń ṣe wọlé wọ̀de láti sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fọgbọ́n yan àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́. Tá a bá ń yan àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́, tá a sì ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ràn, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dáa jù lọ ló máa yí wa ká. Àwọn ẹ̀kọ́ tá a bá rí kọ́ lára wọn máa jẹ́ ká lè rọ̀ mọ́ ìpinnu tá a ti ṣe pé a fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn. Torí náà, àwọn tí kò ní jẹ́ kí ọ̀rẹ́ tó ju gbogbo ọ̀rẹ́ lọ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa fi ṣe ọ̀rẹ́ wa, ìyẹn àwọn tó máa jẹ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà!—Sm. 15:1, 4; Aísá. 41:8.