Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 29
Orin 13 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 28 ìpínrọ̀ 16 sí 22 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Hóséà 8-14 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: “Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àpótí ojú ìwé 6, ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan táwọn ará máa ń pàdé nílé rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo ló máa ń ṣe káwọn ará lè máa rí ilé rẹ̀ lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìpàdé náà? Kí nìdí tó fi mọyì bí àwọn ará ṣe ń lo ilé rẹ̀ fún ìpàdé yìí?
15 min: “Ohun Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ìdáhùn àti ìbéèrè. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá jíròrò ìpínrọ̀ 6, ní kí àwọn ará tí wọ́n ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú sọ ayọ̀ tí wọ́n ní, bí ẹni tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú.
Orin 122 àti Àdúrà