Orin 108
Ẹ Yin Jèhófà Nítorí Ìjọba Rẹ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà ti fi Ọmọ rẹ̀
Jẹ ọba gbogbo ẹ̀dá.
Ìtẹ́ òdodo ni ìtẹ́ rẹ̀
Kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Jáà torí Àyánfẹ́ rẹ̀.
Ẹ kókìkí Jésù pẹ̀lú,
Ẹ̀yin àgùntàn tó ńtọ̀ọ́ lẹ́yìn ṣáá
tó sì ńpa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Ẹ yin Jáà torí Àyánfẹ́ rẹ̀,
tó jọba nísàálú ọ̀run,
Táa fún ní agbára tayọ̀tayọ̀
láti gbórúkọ Jáà ga.
2. Àwọn arákùnrin Kristi,
Jáà yàn wọ́n, ó tún wọn bí.
Ọba ni aya Jésù yìí náà.
Wọn yóò mú Párádísè wá.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Jáà torí Àyánfẹ́ rẹ̀.
Ẹ kókìkí Jésù pẹ̀lú,
Ẹ̀yin àgùntàn tó ńtọ̀ọ́ lẹ́yìn ṣáá
tó sì ńpa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Ẹ yin Jáà torí Àyánfẹ́ rẹ̀,
tó jọba nísàálú ọ̀run,
Táa fún ní agbára tayọ̀tayọ̀
láti gbórúkọ Jáà ga.
(Tún wo Òwe 29:4; Aísá. 66:7, 8; Jòh. 10:4; Ìṣí. 5:9,10.)