Orin 104
Ẹ Bá Mi Yin Jáà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Bá mi yin Jáà;
Ẹ yìnín lógo!
Ó fún wa lẹ́mìí, àtohun rere.
Lójoojúmọ́,
La ńfọpẹ́ fúnun.
Agbára rẹ̀ gbé ìfẹ́ wọ̀ délẹ̀.
A ńkọrin yìnín, a ńkéde oókọ rẹ̀.
2. Bá mi yin Jáà.
Olóore ni.
Ó ńgbọ́ àdúrà wa fún ìrànwọ́.
Ó ńfagbára
Fún aláàárẹ̀;
Ẹ̀mí rẹ̀ ńgbé gbogbo ońrẹ̀lẹ̀ ró.
Oókọ rẹ̀ la ńyìn; iṣẹ́ rẹ̀ la ńsọ.
3. Bá mi yin Jáà.
Olóòótọ́ ni.
Ó ńtù wá nínú, a gbọ́kàn wa lée.
Yóò mú nǹkan tọ́;
Ọkàn balẹ̀.
Ìjọba rẹ̀ yóò fún wa níbùkún.
Jẹ́ ká fayọ̀ yìnín pẹ̀lú ìtara!
(Tún wo Sm. 94:18, 19; 145:21; 147:1; 150:2.)