Orin 122
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará,
Gbogbo ayé ńwò wá,
Ẹlẹ́rìí òótọ́ ni wá,
A ńdìwà títọ́ mú.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni a jẹ́,
Ogunlọ́gọ̀ ńlá,
Láti gbogbo orílẹ̀-èdè,
A ńyin Ọlọ́run wa.
2. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará,
Ńwàásù jákèjádò
‘Ìhìn rere tó dára,’
Tọ́pọ̀ èèyàn fẹ́ gbọ́.
Báa sì ṣe ńwàásù nìṣó,
Ó ńrẹ̀ wá nígbà míì,
Jésù ńtu ọkàn tó rẹ̀ lára;
Ó ńfún wa nísinmi.
3. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará,
Ọlọ́run ló ńṣọ́ wa,
Níbùjọsìn rẹ̀ láyé,
A ńsìn tọ̀sán-tòru.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni a jẹ́,
A ńwàásù Ìjọba,
Alábàáṣiṣẹ́ Ọlọ́run wa,
Tó ńsìnín láyé níbí.
(Tún wo Aísá. 52:7; Mát. 11:29; Ìṣí. 7:15.)