Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 29, 2012. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Kí ni pẹpẹ tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran dúró fún? (Ìsík. 43:13-20) [Sept. 10, w07 8/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5]
2. Kí ni omi odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣàpẹẹrẹ? (Ìsík. 47:1-5) [Sept. 17, w07 8/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 2]
3. Kí ni gbólóhùn náà “pinnu ní ọkàn àyà rẹ̀” jẹ́ ká mọ̀ nípa ìtọ́ni tẹ̀mí tí Dáníẹ́lì rí gbà nígbà tó wà ní kékeré? (Dán. 1:8) [Sept. 24, dp ojú ìwé 33 àti 34 ìpínrọ̀ 7 sí 9 àti ojú ìwé 36 àti 37 ìpínrọ̀ 16]
4. Kí ni arabaríbí igi inú àlá Nebukadinésárì dúró fún? (Dán. 4:10, 11, 20-22) [Oct. 1, w07 9/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 5]
5. Kí ni ọ̀rọ̀ inú Dáníẹ́lì 9:17-19 kọ́ wa nípa àdúrà? [Oct. 8, w07 9/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
6. Májẹ̀mú wo ló ń “ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀” títí di òpin àádọ́rin ọ̀sẹ̀, tó jẹ́ ọdún 36 Sànmánì Kristẹni? (Dán. 9:27) [Oct. 8, w07 9/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 4]
7. Kí la lè parí èrò sí nípa ohun tí ańgẹ́lì kan sọ fún Dáníẹ́lì pé “ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà” dúró ní ìlòdìsí òun? (Dán. 10:13) [Oct. 15, w11 9/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
8. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo nípa Mèsáyà ló ní ìmúṣẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì 11:20? [Oct. 15, dp ojú ìwé 232 àti233 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
9. Ní ìbámu pẹ̀lú Hóséà 4:11, ewu wo ló wà nínú mímu ọtí lámujù? [Oct. 22, w10 1/1 ojú ìwé 4 àti 5]
10. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló yẹ ká kọ́ látinú ìwé Hóséà 6:6? [Oct. 22, w07 9/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 8; w05 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 11 àti 12]