ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/12 ojú ìwé 5-6
  • Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀ Ń Mú Ayọ̀ Wá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àwọn Ọ̀nà Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Gbà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 10/12 ojú ìwé 5-6

Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́

1. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ àti nínú àwọn àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ báyìí?

1 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o pàdánù nǹkan kan látìgbà tí ètò ṣíṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti kásẹ̀ nílẹ̀? Iye àwọn tó wà nínú àwùjọ náà kì í pọ̀ rárá, ó sì máa ń mára tuni gan-an. Èyí jẹ́ kó rọrùn gan-an láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun. (Òwe 18:24) Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ń mọ ipò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wà, ó sì máa ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìṣírí tó nílò. (Òwe 27:23; 1 Pét. 5:2, 3) Irú àwọn àǹfààní yìí là ń gbádùn nínú àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ báyìí.

2. Báwo la ṣe lè lo ìdánúṣe láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó máa jẹ́ ká túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nínú àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́?

2 Máa Lo Ìdánúṣe: Bíi ti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, iye èèyàn tó máa ń wà nínú àwọn àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ báyìí kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Tá a bá jọ ń ṣiṣẹ́ “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa dáadáa. (Fílí. 1:27) Ẹni mélòó lo ti bá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ní àwùjọ tí ò ń dara pọ̀ mọ́? Ǹjẹ́ o lè “gbòòrò síwájú” nípa bíbá àwọn ẹlòmíì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? (2 Kọ́r. 6:13) A tún lè pe ẹnì kan látinú àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ pé kó wá sí Ìjọsìn Ìdílé wa tàbí kó wá kí wa nílé. Láwọn ìjọ kan, àwọn àwùjọ máa ń pín ṣíṣe àlejò olùbánisọ̀rọ̀ tó bá wá láti ìjọ míì láàárín ara wọn. Àwọn tó wà nínú àwùjọ tó bá kàn láti gbàlejò olùbánisọ̀rọ̀ máa ń kóra jọ kí wọ́n lè jọ jẹun, kí wọ́n sì tún jọ fún ara wọn níṣìírí yálà olùbánisọ̀rọ̀ wá síbi ìkórajọ náà tàbí kò wá.

3. Àwọn àǹfààní wo la ní láti gbádùn àbójútó àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì ni ìjọ ń ṣe ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ báyìí, èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn alàgbà máa dín iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń ṣe lórí àwọn akéde kù. Àwọn alábòójútó àwùjọ tá a yàn sí àwùjọ kọ̀ọ̀kan yóò máa fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìṣírí àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu ìṣẹ́ ìsìn pápá. Bí ìwọ àti alábòójútó àwùjọ rẹ kò bá tí ì jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, o ò ṣe sọ fún un pé wàá fẹ́ bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? Láfikún sí i, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa ń jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú àwùjọ tó bá ń bẹ̀ wò ní òpin ọ̀sẹ̀ kan lóṣù. Láwọn ìjọ tí kò ní akéde púpọ̀, tí iye àwùjọ tí wọ́n ní kò sì pọ̀, ó lè ṣètò láti máa bẹ àwùjọ kọ̀ọ̀kan wò lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ǹjẹ́ o máa ń ṣètò àkókò rẹ kó o lè jáde òde ẹ̀rí nígbà tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá ń bẹ àwùjọ yín wò?

4. (a) Báwo la ṣe lè ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká yọ̀ǹda ilé wa fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá?

4 Àǹfààní wà nínú kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan máa pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Bá a ṣe ní àwọn ibi tá a ti ń pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní àkókò kan náà lè jẹ́ kó rọrùn fún àwọn akéde láti wá síbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì lè lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ó máa rọrùn láti tètè pín àwọn ará, wọ́n á sì lè tètè lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn láìfi àkókò ṣòfò. Ó tún máa ń rọrùn fún alábòójútó àwùjọ láti fún akéde kọ̀ọ̀kan tó wà ní àwùjọ tó ń bojú tó ní àfiyèsí tó yẹ. Àmọ́ ṣá o, nítorí àwọn ìdí kan, àwùjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè máa pàdé pọ̀. Bí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ bá pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù tàbí lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ó máa dáa táwọn tó wà nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan bá jókòó pa pọ̀ kí alábòójútó àwùjọ kọ̀ọ̀kan lè pín àwọn tó wà nínú àwùjọ tó ń bojú tó kẹ́ ẹ tó gba àdúrà ìparí nígbà ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá.—Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ O Lè Gbà Ká Máa Pàdé Ní Ilé Rẹ?”

5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mọ́, kí ló yẹ kó dá wa lójú?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mọ́, Jèhófà ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò ká lè túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Héb. 13:20, 21) Torí pé Jèhófà ló ń bójú tó wa, a kò ṣaláìní nǹkan kan. (Sm. 23:1) Ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń rí nínú àwùjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́. Tá a bá lo ìdánúṣe, tá a sì “fúnrúgbìn yanturu,” a ó “ká yanturu.”—2 Kọ́r. 9:6.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ǹjẹ́ O Lè Gbà Ká Máa Pàdé Ní Ilé Rẹ?

Torí pé kò sí ibi tí wọ́n ti lè máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ibì kan náà làwọn àwùjọ tó wà láwọn ìjọ kan ti máa ń pàdé lópin ọ̀sẹ̀. Ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá wà lára ètò tí ìjọ ṣe, torí náà, àǹfààní ńlá ló jẹ́ tó o bá yọ̀ǹda ilé rẹ. Ǹjẹ́ o lè gbà ká máa pàdé ní ilé rẹ? Má ṣe rò pé ilé rẹ kò dáa tó. Bó o bá yọ̀ǹda ilé rẹ, àwọn alàgbà máa ronú nípa rẹ̀, wọ́n á sì ṣe ìpinnu tó bá yẹ, irú èyí tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n pinnu àwọn ilé tá a lò nígbà tá a ṣì ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Tó o bá fẹ́ ká máa pàdé ní ilé rẹ, jọ̀wọ́ sọ fún alábòójútó àwùjọ tí ò ń dara pọ̀ mọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́