ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/03 ojú ìwé 1
  • Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀ Ń Mú Ayọ̀ Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀ Ń Mú Ayọ̀ Wá
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 7/03 ojú ìwé 1

Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀ Ń Mú Ayọ̀ Wá

1 Nígbà tí Jésù ń rán àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn jáde láti wàásù, ó fún wọn ní ìtọ́ni nípa ohun tí wọn yóò sọ, ó pín wọn ní méjì-méjì, ó sì sọ ibi tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́ fún wọn. Èyí mú kí wọ́n láyọ̀. (Lúùkù 10:1-17) Bákan náà lónìí, ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ máa ń mú àwọn èèyàn Ọlọ́run gbára dì fún iṣẹ́ ìwàásù, ó ń mú kí wọ́n ṣètò ara wọn fún iṣẹ́ náà, ó sì ń fún wọn níṣìírí nínú rẹ̀.

2 Àwọn Alàgbà Ń Mú Ipò Iwájú: Àwọn alàgbà ń kó ipa pàtàkì nínú ríran gbogbo akéde lọ́wọ́ láti máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Alábòójútó iṣẹ́-ìsìn ni yóò mú ipò iwájú ní ṣíṣètò ìjẹ́rìí àárín ọ̀sẹ̀. Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa ṣètò bí àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ á ṣe máa jáde òde ẹ̀rí, pàápàá jù lọ ní òpin ọ̀sẹ̀. Láwọn ìgbà tí ìjọ lápapọ̀ bá pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, irú bíi lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣètò àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀.

3 “Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”: Ó yẹ kí ẹni tí a yàn láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bẹ̀rẹ̀ lákòókò, kí ó sì fi ìpàdé náà mọ sí ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ohun tó dáa jù ni pé, kí ó tó gbàdúrà ìparí, kí ó ṣètò àwọn tó máa lọ wàásù kí ó sì fún wọn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́ (àyàfi tó bá jẹ́ pé àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ni yóò bójú tó o, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú). Èyí ò ní mú káwọn akéde máa kóra jọ síta gbangba, nítorí pé ó lè bu iyì iṣẹ́ tá à ń ṣe kù. Èyí sì tún wà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́r. 14:40) Kí ìpàdé náà lè kẹ́sẹ járí, ó yẹ kí gbogbo àwọn tó ń wá síbẹ̀ kọ́wọ́ tì í, nípa dídé lákòókò, nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ẹni tó ń mú ipò iwájú àti nípa lílọ sí ibi tí a ti ní kí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ní gbàrà tí a bá ti sọ pé kí wọ́n máa lọ.

4 Á Mú Kí Wọ́n Wà ní Ìṣọ̀kan: Ìṣètò ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ á jẹ́ ká túbọ̀ láǹfààní láti dojúlùmọ̀ àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú bí a bá ṣètò ṣáájú pé a óò bá ẹnì kan ṣiṣẹ́, á ṣe wá láǹfààní bí a bá lọ́ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá láìṣètò ṣáájú pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Wọ́n lè sọ pé ká bá ẹnì kan tá ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa ṣiṣẹ́, èyí á sì jẹ́ ká lè mú ìfẹ́ wa “gbòòrò síwájú.”—2 Kọ́r. 6:11-13.

5 Ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ máa ń fún wa níṣìírí, ó sì ń mú ká wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 8) Ẹ jẹ́ ká ṣe é lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ o!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́