Ìmọrírì fún Àánú Ọlọ́run
1 Ṣáájú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó fi gbogbo ara ta ko ẹ̀sìn Kristẹni kó má bàa tàn kálẹ̀. Àmọ́, nítorí pé àìmọ̀kan ló sún un ṣe nǹkan tó ṣe, Ọlọ́run fojú àánú hàn sí i. Jèhófà tún fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn, ó sì gbé iṣẹ́ ìwàásù lé Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù ka iṣẹ́ náà sí ìṣúra iyebíye kan. (Ìṣe 26:9-18; 1 Tím. 1:12-14) Ìmọrírì tí Pọ́ọ̀lù ní fún àánú Jèhófà sún un láti forí ṣe fọrùn ṣe kí ó bàa lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láṣeyanjú.—2 Kọ́r. 12:15.
2 Nítorí àánú tí Ọlọ́run ní, ó gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé àwa náà lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 4:1) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe, àwa náà lè fi hàn pé a mọrírì àánú tí Ọlọ́run fi hàn sí wa nípa lílo ara wa tokunratokunra láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣe èyí ni nípa bíbẹ̀rẹ̀ àti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
3 Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Ọ̀nà kan tí a lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni nípa ṣíṣètò láti máa mú ìwé ìròyìn lọ fún àwọn èèyàn déédéé. Bí a ṣe ń dé ọ̀dọ̀ àwọn tí à ń fún láwọn ìwé ìròyìn déédéé, a ó lè túbọ̀ mọ àwọn ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn dáadáa. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó lè jẹ́ àpilẹ̀kọ kan nínú àwọn ìwé ìròyìn náà ló máa yọrí sí bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Láwọn ìgbà tí a bá padà lọ láti fún onílé náà ní ìwé ìròyìn a lè wá máa bá ìjíròrò lọ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè.
4 Àdúrà àti Ìsapá Ṣe Kókó: Àdúrà àti ìsapá aláápọn á jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ múná dóko sí i. Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan tó ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣoṣo gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí òun lè ní sí i. Ó tún ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà tó gbà. Ó ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà tí ó gbà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó wá rí i pé òun kì í fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn nígbà tí òun bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ àwọn èèyàn, bóṣe rẹ́ni méjì sí i tó ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn.
5 Àǹfààní gbáà ló mà jẹ́ o, láti máa kópa nínú sísọ “ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” di mímọ̀ fáwọn èèyàn! (Ìṣe 20:24) Ǹjẹ́ kí ìmọrírì tí a ní fún àánú Ọlọ́run sún wa láti máa fi aápọn ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà.