ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41
Ọlọ́run “Tí Àánú Rẹ̀ Pọ̀” Là Ń Sìn
“Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá, àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—SM. 145:9.
ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló máa wá sí ẹ lọ́kàn tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláàánú?
TÍ WỌ́N bá pe ẹnì kan ní aláàánú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó máa wá sí wa lọ́kàn ni ẹnì kan tó jẹ́ onínúure, tó tutù, tára ẹ̀ balẹ̀, tó sì lawọ́. Ó tún ṣeé ṣe kí ìtàn tí Jésù sọ nípa aláàánú ará Samáríà wá sí wa lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà kì í ṣe Júù, ó “ṣàánú” Júù kan táwọn olè ṣe léṣe. “Àánú [Júù náà] ṣe” ará Samáríà yẹn, ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa tọ́jú rẹ̀. (Lúùkù 10:29-37) Ìtàn yìí kọ́ wa pé àánú jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ Ọlọ́run tó fani mọ́ra. Ọlọ́run máa ń ṣàánú wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ojoojúmọ́ la sì máa ń rọ́wọ́ àánú Ọlọ́run láyé wa.
2. Ọ̀nà míì wo la lè gbà fi àánú hàn?
2 Ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà fàánú hàn. Ẹni tó jẹ́ aláàánú lè pinnu pé òun ò ní fìyà jẹ ẹnì kan tó yẹ kó jìyà ohun tó ṣe. Jèhófà máa ń fàánú hàn sí wa lọ́nà yẹn. Onísáàmù náà sọ pé: “Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa.” (Sm. 103:10) Àmọ́ láwọn ìgbà míì, Jèhófà máa ń fún ẹni tó bá ṣẹ̀ ní ìbáwí tó yẹ.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́ta: Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fàánú hàn? Ṣé a lè fún ẹnì kan ní ìbáwí tó le, ká sì tún fàánú hàn sí i? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fàánú hàn? Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn.
ÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI MÁA Ń FÀÁNÚ HÀN
4. Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fàánú hàn?
4 Ó máa ń wu Jèhófà láti fàánú hàn. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Àánú [Ọlọ́run] pọ̀.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé aláàánú ni Ọlọ́run torí pé ó fún àwọn èèyàn aláìpé tó jẹ́ ẹni àmì òróró láǹfààní láti ní ìyè ti ọ̀run. (Éfé. 2:4-7) Àmọ́ kì í ṣe àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà fàánú hàn sí. Dáfídì sọ pé: “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá, àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sm. 145:9) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, ó máa ń fàánú hàn nígbàkigbà tó bá yẹ.
5. Báwo ni Jésù ṣe mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà?
5 Torí pé kò sẹ́ni tó sún mọ́ Jèhófà bíi ti Jésù, ó mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti fàánú hàn. Ká má gbàgbé pé Jèhófà àti Jésù ti wà pa pọ̀ ní ọ̀run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí Jésù tó wá sáyé. (Òwe 8:30, 31) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù rí bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sí àwa èèyàn aláìpé. (Sm. 78:37-42) Torí náà, nígbà tí Jésù wá sáyé, léraléra ló máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé Jèhófà jẹ́ aláàánú.
Bàbá náà ò dójú ti ọmọ ẹ̀ onínàákúnàá; ṣe ló gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)c
6. Àpèjúwe wo ni Jésù lò láti fi jẹ́ ká mọ̀ pé Bàbá rẹ̀ jẹ́ aláàánú?
6 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jésù sọ àpèjúwe kan nípa ọmọ onínàákúnàá ká lè mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti fàánú hàn. Ọmọ náà fi ilé sílẹ̀, ó wá lọ ń ‘gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla, ó sì lo àwọn ohun ìní rẹ̀ nílòkulò.’ (Lúùkù 15:13) Nígbà tó yá, ó jáwọ́ nínú ìwàkiwà tó ń hù, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì pa dà sílé. Kí ni bàbá ẹ̀ wá ṣe? Kíá ni bàbá náà gbé ìgbésẹ̀. Jésù sọ pé: “Bó ṣe ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” Bàbá yẹn ò kan ọmọ ẹ̀ lábùkù. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló fàánú hàn sí i, ó dárí jì í, ó sì gbà á pa dà sílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó burú gan-an ni ọmọ náà ṣe, bàbá ẹ̀ dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà. Jèhófà ni Bàbá aláàánú inú àpèjúwe yẹn ṣàpẹẹrẹ. Jésù lo àpèjúwe yìí ká lè mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Lúùkù 15:17-24.
7. Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fàánú hàn ṣe fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni?
7 Jèhófà máa ń fàánú hàn torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun táá ṣe àwa èèyàn láǹfààní. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere.” (Jém. 3:17) Bíi ti òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé tóun bá ṣàánú wa, ó máa ṣe wá láǹfààní. (Sm. 103:13; Àìsá. 49:15) Àánú tí Jèhófà fi hàn sí wa ló mú ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé báyìí. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó máa ń fàánú hàn tó bá rí i pé ìdí wà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gba ìgbàkugbà láyè. Torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kò ní torí pé òun fẹ́ fàánú hàn, kó wá gba ìgbàkugbà láyè.
8. Ìgbésẹ̀ wo ló pọn dandan nígbà míì, kí sì nìdí?
8 Ká sọ pé ìránṣẹ́ Jèhófà kan wá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ìwà burúkú dàṣà, kí la máa ṣe? Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti sọ pé ká “jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú” irú ẹni bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 5:11) Wọ́n máa ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì, ká lè dáàbò bo àwọn ará tó jẹ́ olóòótọ́, kí ìjọ sì lè wà ní mímọ́. Àwọn kan lè rò pé tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ìyẹn fi hàn pé Jèhófà ò fàánú hàn sí i. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
ṢÉ ÌYỌNILẸ́GBẸ́ FI HÀN PÉ A Ò FÀÁNÚ HÀN?
Wọ́n lè ya àgùntàn tó ń ṣàìsàn sọ́tọ̀, síbẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn á ṣì máa bójú tó o (Wo ìpínrọ̀ 9-11)
9-10. Kí ni Hébérù 12:5, 6 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àánú ló mú ká máa yọni lẹ́gbẹ́? Ṣàpèjúwe.
9 Tí a bá gbọ́ ìfilọ̀ kan lẹ́yìn ìpàdé pé ẹnì kan tí a mọ̀, tí a sì nífẹ̀ẹ́ “kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́,” ó máa ń dùn wá gan-an. Nígbà míì, a lè máa ronú pé ṣó le tóyẹn ni. Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ṣé a lè sọ pé wọ́n fàánú hàn sẹ́ni náà? Bẹ́ẹ̀ ni. Tó bá yẹ ká bá ẹnì kan wí, àmọ́ tá ò ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé a ò nífẹ̀ẹ́ ẹni náà, a ò fàánú hàn sí i, ìyẹn ò sì bọ́gbọ́n mu. (Òwe 13:24) Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ṣé ìyẹn lè jẹ́ kó ronú pìwà dà? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ló sọ pé ó dáa báwọn alàgbà ṣe yọ àwọn lẹ́gbẹ́. Ìdí ni pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn ló pe orí àwọn wálé, tó mú káwọn ronú pìwà dà, káwọn sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Ka Hébérù 12:5, 6.
10 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Olùṣọ́ àgùntàn kan kíyè sí pé ọ̀kan lára àwọn àgùntàn òun ń ṣàìsàn, ó mọ̀ pé ó yẹ kóun ya àgùntàn yẹn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó kù títí tára ẹ̀ fi máa yá. Àmọ́, àwọn àgùntàn máa ń fẹ́ wà pa pọ̀, torí náà, wọ́n lè máa ké tí wọ́n bá yà wọ́n sọ́tọ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìkà ni olùṣọ́ àgùntàn náà torí pé ó yà á sọ́tọ̀? Rárá o. Ó mọ̀ pé tóun bá jẹ́ kí àgùntàn tó ń ṣàìsàn yẹn wà láàárín àwọn tó kù, àìsàn yẹn máa ràn wọ́n. Torí náà, bó ṣe ya àgùntàn yẹn sọ́tọ̀ dáàbò bo àwọn tó kù.—Fi wé Léfítíkù 13:3, 4.
11. (a) Báwo ni ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣe dà bí àgùntàn tó ń ṣàìsàn? (b) Àwọn nǹkan wo ni ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ lè ṣe?
11 Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ṣe lẹni náà dà bí àgùntàn tó ń ṣàìsàn yẹn. Ìdí ni pé òun náà ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. (Jém. 5:14) Bí àwọn àìsàn kan ṣe máa ń ràn, bẹ́ẹ̀ náà ni àìsàn tẹ̀mí ṣe máa ń ràn. Nítorí náà, ó pọn dandan nígbà míì kí wọ́n ya ẹni tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí sọ́tọ̀, kó má bàa kó àìsàn tẹ̀mí náà ran àwọn míì nínú ìjọ. Ìbáwí yẹn fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà nínú ìjọ, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bákan náà, ìbáwí yẹn lè pe orí oníwà àìtọ́ náà wálé, kó sì ronú pìwà dà. Ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà ṣì lè máa wá sípàdé kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè pa dà lágbára. Ó tún lè gba àwọn ìtẹ̀jáde tó bá fẹ́ kà, kó sì wo ètò JW Broadcasting®. Táwọn alàgbà bá kíyè sí i pé ó ti ń yí pa dà, wọ́n lè máa fún un nímọ̀ràn látìgbàdégbà, kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì gbà á pa dà sínú ìjọ.b
12. Kí lohun táwọn alàgbà lè ṣe fún ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà táá fi hàn pé wọ́n fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí i?
12 Ká má gbàgbé pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà nìkan ni wọ́n máa ń yọ lẹ́gbẹ́. Àwọn alàgbà mọ̀ pé ìyọlẹ́gbẹ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà kì í báni wí “kọjá ààlà.” (Jer. 30:11) Bákan náà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọn ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọse wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àmọ́ nígbà míì, ohun táwọn alàgbà lè ṣe táá fi ìfẹ́ àti àánú hàn ni pé kí wọ́n yọ oníwà àìtọ́ náà lẹ́gbẹ́ fáwọn àkókò kan.
13. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí wọ́n yọ ọkùnrin kan lẹ́gbẹ́ ní ìjọ Kọ́ríńtì?
13 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe lórí ọ̀rọ̀ oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Arákùnrin kan ní Kọ́ríńtì ń ṣe ìṣekúṣe pẹ̀lú ìyàwó bàbá ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìyẹn burú gan-an! Pọ́ọ̀lù mọ òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn ti dójú ti bàbá rẹ̀. Ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì.” (Léf. 20:11) Òótọ́ ni pé Pọ́ọ̀lù ò lè pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọkùnrin náà, àmọ́ ó sọ pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ìwà ìbàjẹ́ tí ọkùnrin yìí hù ti ń ṣàkóbá fún àwọn tó wà nínú ìjọ, àwọn kan ò sì rí ohun tó burú nínú ohun tí ọkùnrin náà ṣe.—1 Kọ́r. 5:1, 2, 13.
14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fàánú hàn sí ọkùnrin tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ní Kọ́ríńtì, kí sì nìdí? (2 Kọ́ríńtì 2:5-8, 11)
14 Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé ọkùnrin náà ti jáwọ́ nínú ìwà pálapàla yẹn, ó sì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà yẹn pé òun ò fẹ́ “le koko jù.” Ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú.” Ẹ kíyè sí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù má bàa bò ó mọ́lẹ̀.” Àánú ọkùnrin yẹn ṣe Pọ́ọ̀lù. Kò fẹ́ kí ìbànújẹ́ bo ọkùnrin náà mọ́lẹ̀, kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ sì pọ̀ débi táá fi ro ara ẹ̀ pin pé Ọlọ́run ò lè dárí ji òun mọ́.—Ka 2 Kọ́ríńtì 2:5-8, 11.
15. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fún ẹnì kan ní ìbáwí tó yẹ, kí wọ́n sì tún fàánú hàn lẹ́sẹ̀ kan náà?
15 Bíi ti Jèhófà, ó máa ń wu àwọn alàgbà láti fàánú hàn. Tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan kí wọ́n fún ẹnì kan ní ìbáwí tó le, wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ṣì máa ń fàánú hàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tó bá yẹ káwọn alàgbà bá oníwà àìtọ́ kan wí, àmọ́ tí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, àánú kọ́ ni wọ́n fi hàn yẹn, ṣe ni wọ́n gbàgbàkugbà láyè. Àmọ́, ṣé àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó máa fàánú hàn?
OHUN TÁÁ JẸ́ KÁ LÈ MÁA FÀÁNÚ HÀN
16. Kí ni Òwe 21:13 sọ pé Jèhófà máa ṣe sáwọn tí ò bá fàánú hàn?
16 Kí nìdí táwa Kristẹni fi máa ń fàánú hàn bíi ti Jèhófà? Ìdí ni pé Jèhófà ò ní tẹ́tí sí àdúrà àwọn tí ò bá fàánú hàn. (Ka Òwe 21:13.) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, kò yẹ ká fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. Dípò ká dé fìlà má-wo-bẹ̀ tí Kristẹni kan bá ń jìyà, ṣe ló yẹ ká ṣe tán nígbà gbogbo láti tẹ́tí sí “igbe aláìní.” Bákan náà, ó yẹ ká fi ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́.” (Jém. 2:13) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ń fi sọ́kàn pé àwa náà nílò àánú, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ yá wa lára láti máa fàánú hàn. Ní pàtàkì, ó yẹ ká fàánú hàn tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà bá pa dà sínú ìjọ.
17. Àwọn ìgbà wo ni Ọba Dáfídì fàánú hàn?
17 Àpẹẹrẹ àwọn tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fàánú hàn, ká má sì fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ń wá bó ṣe máa pa Dáfídì lójú méjèèjì, Dáfídì ò wá bó ṣe máa gbẹ̀san. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló fàánú hàn sí Ọba tí Jèhófà yàn yìí.—1 Sám. 24:9-12, 18, 19.
18-19. Sọ àwọn ìgbà méjì tí Dáfídì ò fàánú hàn.
18 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Dáfídì máa ń fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn líle ni Nábálì. Nígbà tí Dáfídì rán àwọn ọkùnrin kan pé kí wọ́n lọ béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ Nábálì, ṣe ni Nábálì sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn. Inú bí Dáfídì gan-an, ó sì pinnu pé òun máa pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì tó tètè gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè oúnjẹ fún Dáfídì àtàwọn ọkùnrin ẹ̀. Ìyẹn sì ni ò jẹ́ kí Dáfídì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—1 Sám. 25:9-22, 32-35.
19 Ìgbà kan tún wà tí wòlíì Nátánì sọ fún Dáfídì nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jí àgùntàn kan ṣoṣo tí ọkùnrin aláìní kan ní. Inú bí Dáfídì gan-an, ó sì sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ikú tọ́ sí ọkùnrin tó ṣe irú èyí!” (2 Sám. 12:1-6) Dáfídì mọ ohun tí Òfin sọ pé tẹ́nì kan bá jí àgùntàn kan, ṣe ló máa fi àgùntàn mẹ́rin dípò rẹ̀. (Ẹ́kís. 22:1) Àmọ́ ìdájọ́ ikú ni Dáfídì ṣe fún olè náà. Ká sòótọ́, ìdájọ́ yẹn ti le jù. Àṣé àpèjúwe lásán ni Nátánì fi ọ̀rọ̀ náà ṣe fún Dáfídì. Ó sì lò ó láti jẹ́ kí Dáfídì mọ̀ pé ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú ju ti olè yẹn lọ. Síbẹ̀ Jèhófà fàánú hàn sí Dáfídì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ò fàánú hàn sí olè tó wà nínú àpèjúwe Nátánì!—2 Sám. 12:7-13.
Ọba Dáfídì ò fàánú hàn sí ọkùnrin tí Nátánì sọ̀rọ̀ ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 19-20)d
20. Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì?
20 Ẹ kíyè sí i pé ìbínú mú kí Dáfídì dájọ́ ikú fún Nábálì àtàwọn ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀. Bákan náà, Dáfídì dájọ́ ikú fún ọkùnrin tó wà nínú àpèjúwe Nátánì. Nínú àpẹẹrẹ kejì, a lè máa ṣe kàyéfì pé ṣebí ọlọ́kàn tútù ni Dáfídì, kí wá nìdí tó fi dájọ́ olè náà lọ́nà tó le tóyẹn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Torí pé Dáfídì ti dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ń dá a lẹ́bi. Torí náà, tẹ́nì kan bá ti le jù tàbí tó ń dá àwọn míì lẹ́jọ́, ìyẹn fi hàn pé ẹni náà ò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àbájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́.” (Mát. 7:1, 2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra ká má lọ máa fọwọ́ tó le jù mú àwọn èèyàn. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Ọlọ́run wa ẹni tí “àánú rẹ̀ pọ̀.”
21-22. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fàánú hàn?
21 Kéèyàn jẹ́ aláàánú kọjá kí àánú ẹni tó ń jìyà kàn máa ṣèèyàn. Ó tún gba pé kéèyàn ṣe nǹkan kan láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn tá a lè ràn lọ́wọ́ nínú ìdílé wa, nínú ìjọ wa àti ládùúgbò wa. Ká sòótọ́, onírúurú ọ̀nà la lè gbà fàánú hàn. Ṣé a lè tu ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú? Ṣé a lè ṣe àwọn nǹkan pàtó láti ran ẹnì kan lọ́wọ́, bóyá ká gbé oúnjẹ lọ fún un tàbí ká ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì? Ṣé a lè mú Kristẹni kan tí wọ́n gbà pa dà lọ́rẹ̀ẹ́, ká lè máa tù ú nínú? Ṣé a lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn? Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà fàánú hàn sí gbogbo àwọn tá a bá pàdé nìyẹn.—Jóòbù 29:12, 13; Róòmù 10:14, 15; Jém. 1:27.
22 Tá a bá ń kíyè sí àwọn tó nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀, àá rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fàánú hàn sí wọn. Tá a bá ń fàánú hàn, ó dájú pé àá múnú Jèhófà Baba wa ọ̀run dùn, ẹni tí “àánú rẹ̀ pọ̀.”
ORIN 43 Àdúrà Ìdúpẹ́
a Ọ̀kan lára ànímọ́ Jèhófà tó fani mọ́ra jù ni àánú, ó sì yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní àánú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí Jèhófà fi máa ń fàánú hàn, ìdí tá a fi gbà pé àánú tó ní sí wa ló mú kó máa bá wa wí, àá sì rí báwa náà ṣe lè máa fàánú hàn bíi ti Jèhófà.
b Tó o bá fẹ́ mọ bí àwọn tí wọ́n gbà pa dà ṣe lè mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára àti bí àwọn alàgbà ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́, wo àpilẹ̀kọ náà “Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.
c ÀWÒRÁN: Látorí òrùlé, bàbá náà rí ọmọ rẹ̀ onínàákúnàá tó ń pa dà bọ̀ wálé, ó sì sáré lọ pàdé rẹ̀.
d ÀWÒRÁN: Torí pé ẹ̀rí ọkàn ń dá Ọba Dáfídì lẹ́bi, ó fìbínú dájọ́ ikú fún ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó wà nínú àpèjúwe Nátánì.