ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 October ojú ìwé 14-17
  • Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN ÌṢÒRO WO LO LÈ KOJÚ?
  • MỌ ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE LÁTI ṢÀTÚNṢE
  • MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ!
  • “Pe Àwọn Alàgbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ṣafarawe Aanu Ọlọrun Lonii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Fara Wé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 October ojú ìwé 14-17
Nǹkan tojú sú arákùnrin kan bó ṣe ń ronú nípa àkókò tó máa gba òun àti iṣẹ́ tóun máa ṣe láti tún ilé rẹ̀ tó bà jẹ́ ṣe.

Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé

LỌ́DỌỌDÚN, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ronú pìwà dà là ń gbà pa dà sínú ìjọ. “Inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn” gan-an tí ẹnì kan bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Lúùkù 15:7, 10) Tí wọ́n bá ti gbà ẹ́ pa dà sínú ìjọ, mọ̀ dájú pé inú Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì dùn sí ẹ pé o pa dà sínú òtítọ́. Síbẹ̀, bó o ṣe ń sapá láti mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà pa dà gún régé, o lè kojú àwọn ìṣòro kan. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó o kojú, kí ló sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

ÀWỌN ÌṢÒRO WO LO LÈ KOJÚ?

Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n pa dà sínú ìjọ ṣì máa ń ní èrò tí kò tọ́ nípa ara wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Ọba Dáfídì ló rí lára ẹ. Kódà lẹ́yìn tí Jèhófà ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í, ó sọ pé: “Àwọn àṣìṣe mi pọ̀.” (Sm. 40:12; 65:3) Bákan náà lónìí, lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ojú ṣì lè máa tì í, kó sì máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n yọ Isabelle lẹ́gbẹ́, àmọ́ ó ju ogún (20) ọdúna lọ kó tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti gbà pé Jèhófà lè dárí jì mí.” Tó o bá jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú ẹ, àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà tún lè má lágbára mọ́. (Òwe 24:10) Torí náà, má ṣe gba ìrẹ̀wẹ̀sì láyè rárá.

Àwọn kan máa ń rò pé ó máa gba ọ̀pọ̀ iṣẹ́ kí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Jèhófà tó lè gún régé pa dà. Lẹ́yìn tí wọ́n gba Arákùnrin Antoine pa dà, ó sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé mo ti gbàgbé gbogbo ohun tí mo mọ̀ àtohun tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run.” Irú èrò yìí ti jẹ́ káwọn kan fà sẹ́yìn, kò sì jẹ́ kí wọ́n kópa déédéé mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.

Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà yìí. Ká sọ pé ìjì líle ba ilé ẹnì kan jẹ́. Nǹkan lè tojú sú u tó bá ronú nípa iṣẹ́ tóun máa ṣe àti àkókò tó máa gba òun láti tún ilé náà ṣe. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó o dá bá ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́. O lè rò pé ó máa gba àkókò àti ìsapá kó o tó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́, ìrànlọ́wọ́ wà fún ẹ.

Jèhófà rọ̀ wá pé: “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa.” (Àìsá. 1:18) O ti sapá gan-an láti “yanjú ọ̀rọ̀” tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà, Jèhófà sì mọyì gbogbo ohun tó o ṣe. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohun tó o ṣe yìí máa jẹ́ kí Jèhófà lè fún Sátánì tó ń pẹ̀gàn rẹ̀ lésì?​—Òwe 27:11.

Ohun tó o ṣe yìí fi hàn pé o ti sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì ṣèlérí pé òun máa sún mọ́ ẹ. (Jém. 4:8) Àmọ́, ohun tó o máa ṣe kọjá kó o jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé o ti pa dà sínú ìjọ. O gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó máa mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà tó jẹ́ Bàbá àti Ọ̀rẹ́ rẹ túbọ̀ jinlẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

MỌ ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE LÁTI ṢÀTÚNṢE

Gbìyànjú láti mọ àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Ó dájú pé o ò tíì gbàgbé gbogbo ohun tó o kọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Àmọ́, o tún gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o gbọ́dọ̀ máa lọ sípàdé, òde ẹ̀rí, kó o sì máa wà pẹ̀lú àwọn ará. Àwọn nǹkan tó o máa ṣe rèé.

Máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Bàbá rẹ ọ̀run mọ̀ pé bí ẹ̀rí ọkàn ẹ ṣe ń dá ẹ lẹ́bi lè mú kó má rọrùn fún ẹ láti gbàdúrà sí òun. (Róòmù 8:26) Síbẹ̀, “máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” kó o sì jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti òun pa dà gún régé. (Róòmù 12:12) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Andrej rántí bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun. Ó ní: “Ojú tì mí gan-an, mo sì ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá. Àmọ́ gbogbo ìgbà tí mo bá ti gbàdúrà lọkàn mi máa ń balẹ̀, tára sì máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀.” Tó ò bá mọ ohun tó o máa sọ nínú àdúrà, wo àdúrà ìrònúpìwàdà tí Ọba Dáfídì gbà nínú Sáàmù 51 àti 65.

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á sì jinlẹ̀ sí i. (Sm. 19:7-11) Arákùnrin Felipe sọ pé: “Ohun tó jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà má lágbára mọ́, tí mo sì já Jèhófà kulẹ̀ ni pé mi ò ní ètò tí mo ṣe láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, mo pinnu láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ torí ìyẹn ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa tún ṣàṣìṣe.” Ohun tó yẹ kíwọ náà ṣe nìyẹn. Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o lè fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, o lè bi ọ̀rẹ́ rẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀.

Jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ará pa dà gún régé. Ó máa ń ṣe àwọn kan tí wọ́n pa dà sínú ìjọ bíi pé àwọn ará máa fojú burúkú wò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Larissa sọ pé: “Ojú tì mí gan-an, ó sì ń ṣe mí bíi pé mo ti já àwọn ará kulẹ̀. Ó pẹ́ gan-an kí n tó gbé èrò yìí kúrò lọ́kàn.” Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn alàgbà àtàwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lè lágbára sí i. (Wo àpótí náà “Ohun Táwọn Alàgbà Lè Ṣe.”) Inú gbogbo àwọn ará dùn pé o ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ kíwọ náà láyọ̀!​—Òwe 17:17.

Kí ló lè jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará ìjọ? Máa ṣe gbogbo ohun táwọn ará ń ṣe, máa lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. Báwo lèyí ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Arákùnrin Felix sọ pé: “Àwọn ará ti ń retí pé kí n pa dà sínú ìjọ torí pé wọ́n mọyì mi. Wọ́n tún jẹ́ kí n pa dà di ara ìdílé Jèhófà, wọ́n jẹ́ kí n rí i pé ó ti dárí jì mí, wọ́n sì fẹ́ kí n tẹ̀ síwájú.”​—Wo àpótí náà “Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe.”

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe

Máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà pa dà gún régé

Alàgbà kan ń gbàdúrà pẹ̀lú arákùnrin tó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ DÉÉDÉÉ

Jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti òun pa dà gún régé. Àwọn alàgbà máa gbàdúrà pẹ̀lú ẹ, wọ́n á sì tún máa gbàdúrà fún ẹ

Alàgbà náà ń lo ìwé “Sún Mọ́ Jèhófà” láti fi kọ́ arákùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ DÉÉDÉÉ

Tó o bá ṣètò láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á jinlẹ̀ sí i

Arákùnrin náà ń bá àwọn ará ìjọ sọ̀rọ̀ níbi ìkórajọ kan.

JẸ́ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ ÀWỌN ARÁ PA DÀ GÚN RÉGÉ

Máa lọ sí gbogbo ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé pẹ̀lú àwọn ará

MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ!

Gbogbo ìgbà tó o bá ń sapá láti mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà pa dà gún régé ni Sátánì á máa kó ọ̀pọ̀ ìṣòro tó dà bí “ìjì líle” bá ọ kó o lè rẹ̀wẹ̀sì. (Lúùkù 4:13) Torí náà, àsìkò yìí gan-an ló yẹ kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára.

Jèhófà sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Màá wá èyí tó sọ nù, màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára.” (Ìsík. 34:16) Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára.

Ohun Táwọn Alàgbà Lè Ṣe

Alàgbà náà ń bá arákùnrin yẹn tún ilé rẹ̀ tó bà jẹ́ ṣe.

Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn alàgbà lè ṣe láti ran àwọn tó pa dà sínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n tún lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí wọ́n lè ṣe fáwọn tó pa dà sínú ìjọ.

Ẹ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé “ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù” lè bo ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà mọ́lẹ̀. (2 Kọ́r. 2:7) Ojú lè máa tì í, kó sì máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi nígbà gbogbo. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará ìjọ níyànjú pé: “Ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú.” Ó yẹ ká jẹ́ káwọn tó pa dà sínú ìjọ mọ̀ pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Tá a bá ń gbóríyìn fún wọn, tá a sì ń ṣe nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, wọn ò ní rẹ̀wẹ̀sì.

Ẹ máa gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Bíbélì sọ pé: “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.” (Jém. 5:16) Larissa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Mo sọ gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù fáwọn alàgbà, wọ́n sì ń gbàdúrà fún mi. Ìyẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn alàgbà ń bínú sí mi, wọ́n kàn fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ni.” Arákùnrin Theo ní tiẹ̀ sọ pé: “Àdúrà táwọn alàgbà ń gbà fún mi jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ń kíyè sí ibi tí mo dáa sí, kì í ṣe ibi tí mo kù sí nìkan ló ń wò.”

Ẹ mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn tó pa dà sínú ìjọ máa ń fẹ́ ká mú àwọn lọ́rẹ̀ẹ́. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Justin sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ̀ ń bá wọn jáde òde ẹ̀rí déédéé, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ lọ máa kí wọn nílé. Torí ó pọn dandan ká mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́.” Alàgbà míì tó ń jẹ́ Henry sọ pé: “Táwọn ará nínú ìjọ bá rí i pé àwọn alàgbà ń mú àwọn tó pa dà sínú ìjọ lọ́rẹ̀ẹ́, àwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè ran ẹnì kan tó pa dà sínú ìjọ lọ́wọ́ kó lè ṣètò bá á ṣe máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Darko sọ pé: “Inú mi máa ń dùn láti sọ àwọn ohun tí mo rí kọ́ nígbà tí mò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ fún wọn, mo sì máa ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé mo máa ń gbádùn láti dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, mo máa ń ṣètò pé ká jọ jíròrò àwọn àpilẹ̀kọ kan.” Alàgbà míì tó ń jẹ́ Clayton sọ pé: “Mo máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ka Bíbélì, kí wọ́n lè rí àpẹẹrẹ àwọn tó ti kojú irú ìṣòro tí wọ́n ní, kí wọ́n sì wo ohun tí wọ́n lè kọ́ lára wọn.”

Ẹ máa bẹ̀ wọ́n wò déédéé. Ojú àwọn tó ń gbẹ́jọ́ làwọn tó pa dà sínú ìjọ máa fi ń wo àwọn alàgbà. Àmọ́ ní báyìí, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n rí i pé olùṣọ́ àgùntàn làwọn. (Jer. 23:4) Torí náà, ẹ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kí ẹ sì máa gbóríyìn fún wọn. Ẹ máa bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí alàgbà kan tó ń jẹ́ Marcus sọ pé àwọn máa ń ṣe táwọn bá lọ ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ó ní: “A jọ máa ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àá sì ṣàlàyé ẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, àá gbóríyìn fún wọn, àá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì bí wọ́n ṣe sapá láti pa dà sínú ìjọ àti pé inú Jèhófà náà ń dùn sí wọn. Ká sì tó kúrò níbẹ̀, a máa ń sọ ọjọ́ tá a máa pa dà wá bẹ̀ wọ́n wò.”

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́