ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36
ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
“Pe Àwọn Alàgbà”
“Pe àwọn alàgbà ìjọ.”—JÉM. 5:14.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.
1. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ gan-an?
JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì ń bójú tó wa bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn ẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ Jésù ló fi rà wá, ó sì ní káwọn alàgbà máa bójú tó wa. (Ìṣe 20:28) Jèhófà yan Jésù pé kó máa darí ìjọ, àwọn méjèèjì sì fẹ́ káwọn alàgbà máa fìfẹ́ bójú tó wa. Torí náà bíi Jésù, àwọn alàgbà máa ń mára tù wá, wọ́n sì máa ń dáàbò bò wá kí àjọṣe àwa àti Jèhófà má bàa bà jẹ́.—Àìsá. 32:1, 2.
2. Àwọn wo ni Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16 sọ pé Jèhófà máa ń ràn lọ́wọ́?
2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, àmọ́ ó túbọ̀ máa ń kíyè sí àwọn tí ìyà ń jẹ lára wa. Àwọn kan lè máa jìyà torí àṣìṣe tí wọ́n ṣe, àwọn alàgbà ni Jèhófà sì máa ń lò láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16.) Síbẹ̀, ó fẹ́ ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Nírú àsìkò yẹn, ó yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì tún ní káwọn “olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́” nínú ìjọ ràn wá lọ́wọ́.—Éfé. 4:11, 12.
3. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn alàgbà máa ràn wá lọ́wọ́. A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Ìgbà wo ló yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́? Kí nìdí tó fi yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà? Báwo ni wọ́n ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Tá ò bá tiẹ̀ níṣòro tó lè jẹ́ ká lọ bá àwọn alàgbà báyìí, ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ètò tí Jèhófà ṣe, ó sì lè gbẹ̀mí wa là lọ́jọ́ iwájú.
ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ “PE ÀWỌN ALÀGBÀ”?
4. Kí ló mú ká gbà pé ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ni Jémíìsì 5:14-16, 19, 20 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Nígbà tí Jémíìsì ń sọ̀rọ̀ nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe pé káwọn alàgbà máa ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó sọ pé: “Ṣé ẹnikẹ́ni ń ṣàìsàn láàárín yín? Kó pe àwọn alàgbà ìjọ.” (Ka Jémíìsì 5:14-16, 19, 20.) Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó sì yẹ kó ṣàtúnṣe ni Jémíìsì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kì í ṣe ẹni tó ń ṣàìsàn ibà tàbí àìsàn míì. Ìdí ni pé Jémíìsì ò sọ pé kí ẹni tó ń ṣàìsàn náà pe dókítà, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn alàgbà ló ní kó pè. Bákan náà, Jémíìsì sọ pé tí ara ẹni tó ń ṣàìsàn náà bá máa yá, àfi kí Jèhófà dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í. Àwọn nǹkan tí ẹni tó ń ṣàìsàn máa ṣe tó bá fẹ́ kí ara òun yá jọ ohun tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ máa ṣe kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Tára wa ò bá yá, a máa ń lọ sọ́dọ̀ dókítà, àá sọ bó ṣe ń ṣe wá fún un, àá sì ṣe ohun tó bá sọ fún wa. Lọ́nà kan náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà, ká jẹ́wọ́ ohun tá a ṣe, ká sì fi ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n bá fún wa sílò.
Tí ara wa ò bá yá, a máa ń lọ sọ́dọ̀ dókítà. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ tàbí tá a ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ó yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 4)
5. Báwo la ṣe lè mọ̀ tí ìgbàgbọ́ wa ò bá fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́?
5 Ètò tí Jèhófà ṣe tí Jémíìsì orí karùn-ún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ gbà wá níyànjú pé ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé á dáa tá a bá tètè ní kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́! Tó o bá nírú ìṣòro yìí, má tan ara ẹ jẹ, ṣe ni kó o lọ bá àwọn alàgbà. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa rò pé a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí kò sì rí bẹ́ẹ̀. (Jém. 1:22) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn kan níjọ Sádísì ṣe irú àṣìṣe yẹn, àmọ́ Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọn ò ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ mọ́. (Ìfi. 3:1, 2) Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a ṣì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? Bá a ṣe lè mọ̀ ni pé ká fi ìtara tá a ní tẹ́lẹ̀ wé ìtara tá a ní báyìí nínú ìjọsìn Jèhófà. (Ìfi. 2:4, 5) A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń gbádùn bí mo ṣe ń ka Bíbélì tí mo sì ń ṣàṣàrò bíi ti tẹ́lẹ̀, àbí mi ò gbádùn ẹ̀ mọ́? Ṣé mo ṣì máa ń lọ sípàdé déédéé, ṣé mo sì máa ń múra ẹ̀ sílẹ̀ àbí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́? Ṣé mo ṣì máa ń fìtara wàásù bíi ti tẹ́lẹ̀? Ṣé kì í ṣe gbogbo àkókò ni mo fi ń gbádùn ara mi àbí owó ni mò ń lé kiri?’ Tó o bá rí i pé o ò ṣe ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó fi hàn pé àwọn àtúnṣe kan wà tó yẹ kó o ṣe. Tí o ò bá ṣe àwọn àtúnṣe yẹn, ó ṣeé ṣe kó ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́. Tó ò bá lè yanjú ìṣòro náà fúnra ẹ tàbí tó ti mú kó o dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ kó o tètè lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
6. Kí ló yẹ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá ṣe?
6 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tá a lè torí ẹ̀ mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ. Tó o bá ti dá irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 5:11-13) Ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá kò ní lè dá yanjú ìṣòro náà, àfi tí wọ́n bá ràn án lọ́wọ́ kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá nípasẹ̀ ìràpadà Kristi, a gbọ́dọ̀ máa ṣe “àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.” (Ìṣe 26:20) Ara àwọn iṣẹ́ náà ni pé ká lọ sọ fáwọn alàgbà tá a bá ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá.
7. Àwọn wo ló yẹ kó tún lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́?
7 Kì í ṣe àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá nìkan làwọn alàgbà máa ń ràn lọ́wọ́, wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣe ohun tó lè mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá. (Ìṣe 20:35) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́, kó o sì rò pé o ò ní lè borí ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ o máa ń lo oògùn olóró, o máa ń wo àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe tàbí kó jẹ́ pé o máa ń ṣèṣekúṣe, ó lè nira gan-an láti borí ìṣòro ẹ. Torí náà, ó yẹ kó o sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. O lè sọ fún alàgbà kan tó máa fara balẹ̀ gbọ́ ẹ, táá gbà ẹ́ nímọ̀ràn, táá sì jẹ́ kó o mọ̀ pé tó o bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ó yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti borí ìṣòro ẹ. (Oníw. 4:12) Tó bá ṣì ń wù ẹ́ láti ṣe ohun tó lè mú kó o dẹ́ṣẹ̀ ńlá, àmọ́ tó o sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n máa jẹ́ kó o mọ̀ pé inú Jèhófà dùn sí ẹ torí pé o ò fẹ́ dá yanjú ìṣòro náà.—1 Kọ́r. 10:12.
8. Ṣé gbogbo àṣìṣe tá a bá ṣe ló máa gba pé ká lọ bá àwọn alàgbà? Ṣàlàyé.
8 Kì í ṣe gbogbo àṣìṣe tá a bá ṣe ló máa gba pé ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé a sọ ohun tó bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú tàbí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó mú ká gbaná jẹ. Dípò ká lọ bá àwọn alàgbà, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn Jésù sílò pé ká wá àlàáfíà láàárín àwa àtàwọn arákùnrin wa. (Mát. 5:23, 24) O lè ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run kó o lè túbọ̀ ní ìwà tútù, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Àmọ́ tó o bá rí i pé o ò lè dá yanjú ìṣòro ẹ, á dáa kó o sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sáwọn ará Fílípì, ó sọ fún alàgbà kan tí kò dárúkọ ẹ̀ pé kó ran Yúódíà àti Síńtíkè lọ́wọ́ kí wọ́n lè yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn. Tíwọ náà bá nírú ìṣòro yìí, alàgbà kan nínú ìjọ ẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro náà.—Fílí. 4:2, 3.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ LỌ BÁ ÀWỌN ALÀGBÀ?
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tijú láti lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́? (Òwe 28:13)
9 Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká tó lè lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá tàbí tá a rí i pé ó ṣòro fún wa láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ tá a ní. Kò yẹ ká tijú láti lọ bá àwọn alàgbà. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tijú? Ìdí ni pé àwọn alàgbà ni Jèhófà ní kó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. Torí náà, tá a bá ṣàṣìṣe tá a sì lọ bá àwọn alàgbà, ó máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì ń ṣègbọràn. Á sì tún fi hàn pé Jèhófà ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣohun tó tọ́. (Sm. 94:18) Torí náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá, tá a jẹ́wọ́, tá ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, Jèhófà máa fàánú hàn sí wa.—Ka Òwe 28:13.
10. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ń bo ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀?
10 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tá a sì sọ fáwọn alàgbà, Jèhófà máa dárí jì wá, àá sì pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Àmọ́ tá ò bá jẹ́wọ́, ṣe lọ̀rọ̀ náà á máa burú sí i. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Dáfídì bo ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ mọ́lẹ̀, àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́, ó ní ẹ̀dùn ọkàn, ó sì ṣàìsàn. (Sm. 32:3-5) Tá a bá ń ṣàìsàn àmọ́ tá ò tọ́jú ara wa, ńṣe ni àìsàn náà á máa burú sí i. Lọ́nà kan náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tá ò sì sọ fáwọn alàgbà, ó lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. Jèhófà ò fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, ìdí nìyẹn tó fi ní ká lọ bá àwọn alàgbà láti “yanjú ọ̀rọ̀” láàárín àwa àti òun, ká sì lè pa dà di ọ̀rẹ́.—Àìsá. 1:5, 6, 18.
11. Tá a bá bo ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tá a dá mọ́lẹ̀, àkóbá wo nìyẹn máa ṣe fáwọn ará ìjọ?
11 Tá a bá bo ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tá a dá mọ́lẹ̀, tá ò sì jẹ́wọ́, ó lè ṣàkóbá fáwọn ará ìjọ. Ó lè má jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ nínú ìjọ, ó sì lè má jẹ́ káwọn ará wà níṣọ̀kan mọ́. (Éfé. 4:30) Bákan náà, tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ, ó yẹ ká rọ ẹni náà pé kó lọ sọ fáwọn alàgbà.a Tá a bá bo ẹ̀ṣẹ̀ ẹni náà mọ́lẹ̀, àwa náà máa jẹ̀bi. (Léf. 5:1) Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó yẹ ká lọ sọ fáwọn alàgbà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá dáàbò bo àwọn ará ìjọ, á sì jẹ́ kí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
BÁWO LÀWỌN ALÀGBÀ ṢE MÁA Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́?
12. Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń ran àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára lọ́wọ́?
12 Bíbélì sọ pé káwọn alàgbà máa ran àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára lọ́wọ́. (1 Tẹs. 5:14) Tó o bá dẹ́ṣẹ̀, àwọn alàgbà máa bi ẹ́ láwọn ìbéèrè kan kí wọ́n lè ‘mọ’ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. (Òwe 20:5) Ó lè má rọrùn fún ẹ láti sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí bóyá torí pé ojú ń tì ẹ́ àbí nítorí àṣà ìbílẹ̀ ẹ, àmọ́ á dáa kó o sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má bẹ̀rù pé o lè ‘sọ̀rọ̀ tó le.’ (Jóòbù 6:3; àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn alàgbà ò ní fi ohun tó o bá sọ dá ẹ lẹ́jọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n máa fara balẹ̀ gbọ́ ẹ kí wọ́n lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n sì lè mọ bí wọ́n ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 18:13) Wọ́n mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kí wọ́n tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́, torí náà wọ́n lè bá ẹ sọ̀rọ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ kó o tó lè borí ìṣòro ẹ.
13. Táwọn alàgbà bá gbàdúrà fún ẹ, tí wọ́n sì fi Bíbélì tọ́ ẹ sọ́nà, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Tó o bá lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà, wọn ò ní dá kún ẹ̀dùn ọkàn ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa gbàdúrà fún ẹ. Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé àdúrà tó “lágbára gan-an” tí wọ́n bá gbà fún ẹ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun míì tí wọ́n máa ṣe ni pé wọ́n á “fi òróró pa [ẹ́ lára] ní orúkọ Jèhófà.” (Jém. 5:14-16) Òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni “òróró” yìí. Àwọn alàgbà máa fi Bíbélì tù ẹ́ nínú kó o lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Àìsá. 57:18) Ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n bá fún ẹ á jẹ́ kó o pinnu pé wàá máa ṣe ohun tó tọ́. Nípasẹ̀ àwọn alàgbà, wàá gbọ́ bí Jèhófà ṣe ń sọ fún ẹ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà, máa rìn nínú rẹ̀.’—Àìsá. 30:21.
Àwọn alàgbà máa ń fi Bíbélì tọ́ àwọn tó níṣòro sọ́nà kára lè tù wọ́n (Wo ìpínrọ̀ 13-14)
14. Bí Gálátíà 6:1 ṣe sọ, báwo làwọn alàgbà ṣe máa ran ẹni tó “ṣi ẹsẹ̀ gbé” lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ka Gálátíà 6:1. Tí Kristẹni kan bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé,” ó fi hàn pé kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Tẹ́nì kan bá ṣi ẹsẹ̀ gbé, ó lè túmọ̀ sí pé ó ṣe ìpinnu tí kò tọ́ tàbí ó dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Torí pé àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ ẹni náà, wọ́n á ‘sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́ ọ sọ́nà.’ Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí ‘tọ́ sọ́nà’ tún lè túmọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń dá egungun tó yẹ̀ pa dà sáyè ẹ̀, kó lè tò. Tí dókítà tó mọṣẹ́ dáadáa bá fẹ́ to egungun aláìsàn kan, ó máa rọra ṣe é kí ìrora náà má bàa pọ̀ jù. Lọ́nà kan náà, bí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ṣe máa pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ló jẹ àwọn alàgbà lógún, wọn ò sì ní dá kún ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀. Bíbélì tún sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n “máa kíyè sí ara [wọn].” Bí wọ́n ṣe ń ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n má gbàgbé pé aláìpé làwọn, àwọn náà sì lè ṣàṣìṣe. Wọn ò gbọ́dọ̀ máa rò pé àwọn dáa ju ẹni náà lọ, kò sì yẹ kí wọ́n ṣe òdodo àṣelékè tàbí kí wọ́n máa dá ẹni náà lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n nírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì fàánú hàn sẹ́ni náà.—1 Pét. 3:8.
15. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá níṣòro?
15 Ó yẹ ká fọkàn tán àwọn alàgbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa pa àṣírí mọ́, kí wọ́n máa fi Bíbélì tọ́ wa sọ́nà dípò èrò ara wọn, kí wọ́n sì máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro. (Òwe 11:13; Gál. 6:2) Ìwà àwọn alàgbà yàtọ̀ síra, ó pẹ́ táwọn kan ti di alàgbà, àwọn míì sì ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà ni. Síbẹ̀, kò sẹ́ni tá ò lè sọ ìṣòro wa fún nínú wọn. Àmọ́, ìyẹn ò sọ pé ká máa lọ láti ọ̀dọ̀ alàgbà kan sí òmíì kí wọ́n lè gbà wá nímọ̀ràn títí tá a fi máa rẹ́ni táá sọ ohun tó wù wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa dà bí àwọn tó fẹ́ káwọn ẹlòmíì ‘sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́,’ dípò kí wọ́n fetí sí “ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tím. 4:3) Tá a bá sọ ìṣòro wa fún alàgbà kan, ó lè bi wá bóyá a ti sọ fáwọn alàgbà míì tẹ́lẹ̀ àti pé ìmọ̀ràn wo ni wọ́n fún wa. Tí alàgbà náà bá nírẹ̀lẹ̀, tó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó lè lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ alàgbà míì, kó lè mọ bó ṣe máa ran ẹni náà lọ́wọ́.—Òwe 13:10.
OJÚṢE ẸNÌ KỌ̀Ọ̀KAN WA
16. Ojúṣe wo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní?
16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà máa ń bójú tó wa, wọn kì í ṣèpinnu fún wa tá a bá níṣòro. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti máa ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn. Ká má gbàgbé pé a máa jíhìn ohun tá a bá sọ tàbí tá a bá ṣe fún Jèhófà. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́. (Róòmù 14:12) Torí náà, dípò káwọn alàgbà sọ ohun tá a máa ṣe fún wa, ńṣe ni wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá gbàmọ̀ràn tí wọ́n fún wa látinú Bíbélì, a máa kọ́ “agbára ìfòyemọ̀” wa, àá sì lè ṣèpinnu tó tọ́.—Héb. 5:14.
17. Kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe?
17 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà! Jèhófà rán Jésù, “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” pé kó wá rà wá pa dà ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 10:11) Jèhófà ṣèlérí pé: “Màá fún yín ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ọkàn mi fẹ́, wọ́n á sì fi ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye bọ́ yín.” (Jer. 3:15) Àwọn alàgbà ìjọ ni Jèhófà ń lò lónìí láti mú ìlérí yìí ṣẹ. Tá a bá ń ṣe ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ ńlá tàbí tá a ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó yẹ ká tètè sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa tẹ̀ lé ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní.
ORIN 31 Bá Ọlọ́run Rìn!
a Tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ò bá lọ sọ fáwọn alàgbà lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó yẹ kó o lọ sọ fáwọn alàgbà kó o lè fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.