ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 August ojú ìwé 20-25
  • Bá A Ṣe Lè Ṣàánú Ẹni Tó Dẹ́ṣẹ̀, Ká sì Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Ṣàánú Ẹni Tó Dẹ́ṣẹ̀, Ká sì Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÁWỌN ALÀGBÀ ṢE LÈ RAN ẸNI TÓ DẸ́ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ LỌ́WỌ́
  • ‘BÁ ÀWỌN TÓ DẸ́ṢẸ̀ WÍ NÍṢOJÚ GBOGBO ÀWÙJỌ’
  • “JÈHÓFÀ NÍ ÌFẸ́ ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́ TÓ PỌ̀ GAN-AN, Ó SÌ JẸ́ ALÁÀÁNÚ”
  • Báwọn Alàgbà Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Wọ́n Mú Kúrò Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • “Pe Àwọn Alàgbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Báwo Ni Jèhófà Ṣe Fẹ́ Kí Ìjọ Máa Ṣe Sáwọn Tó Dẹ́ṣẹ̀ Tó Burú Jáì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 August ojú ìwé 20-25

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34

ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa

Bá A Ṣe Lè Ṣàánú Ẹni Tó Dẹ́ṣẹ̀, Ká sì Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀

“Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀, fẹ́ darí rẹ sí ìrònúpìwàdà.” —RÓÒMÙ 2:4.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Báwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́ nínú ìjọ.

1. Ìrànlọ́wọ́ wo lẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lè rí gbà?

NÍNÚ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ní kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ní ìjọ Kọ́ríńtì. Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ò ronú pìwà dà, wọ́n sì mú un kúrò nínú ìjọ. Àmọ́, bí ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ṣe sọ, Jèhófà lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà. (Róòmù 2:4) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà?

2-3. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí sì nìdí?

2 Táwọn alàgbà ò bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, wọn ò ní lè ràn án lọ́wọ́. Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tó lè mú kí wọ́n mú un kúrò nínú ìjọ? Ó yẹ ká rọ ẹni náà pé kó lọ sọ fáwọn alàgbà, kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́.—Àìsá. 1:18; Ìṣe 20:28; 1 Pét. 5:2.

3 Àmọ́ tẹ́ni náà bá kọ̀ tí kò lọ sọ fáwọn alàgbà ńkọ́? Ìgbà yẹn làwa fúnra wa máa lọ sọ fáwọn alàgbà, kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ torí a ò fẹ́ kó fi Jèhófà sílẹ̀. Tẹ́ni náà ò bá jáwọ́, tó ṣì ń dẹ́ṣẹ̀ nìṣó, ó máa ba àjọṣe àárín òun àti Jèhófà jẹ́ pátápátá. Bákan náà, ó lè ba ìjọ lórúkọ jẹ́. Torí náà, tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtẹni náà, ó yẹ ká nígboyà, ká sì lọ sọ fáwọn alàgbà.—Sm. 27:14.

BÁWỌN ALÀGBÀ ṢE LÈ RAN ẸNI TÓ DẸ́ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ LỌ́WỌ́

4. Kí ló yẹ káwọn alàgbà máa rántí tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́?

4 Tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ, ìgbìmọ̀ alàgbà máa yan alàgbà mẹ́ta tó kúnjú ìwọ̀n. Àwọn mẹ́ta yìí ló máa wà nínú ìgbìmọ̀ tó máa ran ẹni náà lọ́wọ́.a Àwọn alàgbà tí wọ́n yàn yìí gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wọn, kí wọ́n sì nírẹ̀lẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa ran ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lọ́wọ́ ló ṣe pàtàkì jù, wọ́n mọ̀ pé àwọn ò lè fipá mú un kó ronú pìwà dà. (Diu. 30:19) Àwọn alàgbà mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ ló máa ronú pìwà dà bíi Ọba Dáfídì. (2 Sám. 12:13) Wọ́n sì tún mọ̀ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lè kọ ìmọ̀ràn Jèhófà. (Jẹ́n. 4:6-8) Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tó yẹ káwọn alàgbà máa rántí ni bí wọ́n ṣe máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà. Torí náà, ìlànà wo làwọn alàgbà máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá fẹ́ lọ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́?

5. Ìmọ̀ràn wo ló yẹ káwọn alàgbà máa rántí tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lọ́wọ́? (2 Tímótì 2:24-26) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Ó yẹ káwọn alàgbà mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà dà bí àgùntàn tó sọ nù, ó sì ṣeyebíye lójú Jèhófà. (Lúùkù 15:4, 6) Torí náà, tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́, kò yẹ kí wọ́n máa nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa kanra mọ́ ọn. Wọn ò sì ní rò pé torí kí wọ́n lè gbọ́ tẹnu ẹ̀, kí wọ́n sì mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nìkan ni wọ́n ṣe pè é. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí 2 Tímótì 2:24-26 sọ ló yẹ kí wọ́n ṣe. (Kà á.) Torí náà, ó yẹ káwọn alàgbà fi ìwà tútù, ìwà jẹ́jẹ́ àti ìfẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè yí èrò ẹ̀ pa dà.

Olùṣọ́ àgùntàn kan àtàwọn àgùntàn ẹ̀. Ó ń wá àgùntàn tó sọ nù. Àgùntàn náà há sínú igbó, ó sì fi ẹsẹ̀ ṣèṣe.

Bíi tàwọn olùṣọ́ àgùntàn ìgbà àtijọ́, àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà (Wo ìpínrọ̀ 5)


6. Kí làwọn alàgbà máa ṣe láti múra sílẹ̀ kí wọ́n tó pàdé pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀? (Róòmù 2:4)

6 Ó yẹ káwọn alàgbà múra sílẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà. Ó yẹ kí wọ́n fara wé Jèhófà tí wọ́n bá ń ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀, fẹ́ darí rẹ sí ìrònúpìwàdà.” (Ka Róòmù 2:4.) Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa rántí pé olùṣọ́ àgùntàn làwọn, kí wọ́n má sì gbàgbé pé Kristi ló ń darí àwọn. (Àìsá. 11:3, 4; Mát. 18:18-20) Kí ìgbìmọ̀ náà tó pe ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ láti gbọ́rọ̀ lẹ́nu ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ gbàdúrà, kí wọ́n sì ronú nípa bí wọ́n ṣe máa ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa ṣèwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run, wọ́n á sì gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí nǹkan tó ń ṣe ẹni náà yé àwọn, káwọn lè bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn á sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹni náà àtohun tó ṣeé ṣe kó fà á tó fi ṣe ohun tó ṣe yẹn.—Òwe 20:5.

7-8. Kí làwọn alàgbà lè ṣe kí wọ́n lè máa ní sùúrù bíi Jèhófà?

7 Ó yẹ káwọn alàgbà máa ní sùúrù bíi ti Jèhófà. Ó dáa káwọn alàgbà máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà gba Kéènì nímọ̀ràn, ó ṣe sùúrù fún un, ó sì kìlọ̀ fún un pé tó bá dẹ́ṣẹ̀ ó máa jìyà ẹ̀, àmọ́ tó bá yí pa dà, á rí ojúure òun. (Jẹ́n. 4:6, 7) Jèhófà ní kí wòlíì Nátánì bá Dáfídì wí, wòlíì náà sì lo àpèjúwe kan tó wọ Ọba Dáfídì lọ́kàn. (2 Sám. 12:1-7) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ya aláìgbọràn, Jèhófà “ń rán” àwọn wòlíì ẹ̀ sí wọn “léraléra.” (Jer. 7:24, 25) Kò dúró dìgbà tí wọ́n máa ronú pìwà dà kó tó ràn wọ́n lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n ṣì ń dẹ́ṣẹ̀, ó fìfẹ́ rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà.

8 Àwọn alàgbà máa ń fara wé Jèhófà tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́. Bí 2 Tímótì 4:2 ṣe sọ, wọ́n máa ń fi “ọ̀pọ̀ sùúrù” ran ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ohun tí alàgbà kan máa ṣe, ó ní: “Ó yẹ kó máa kó ara ẹ̀ níjàánu ní gbogbo ìgbà, kó máa fi sùúrù rọ [ẹlẹ́ṣẹ̀ náà] kó lè wù ú láti ṣe ohun tó tọ́. Tí [alàgbà kan] bá jẹ́ kí inú bí òun tàbí tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà sú òun, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà lè má gba ìmọ̀ràn tó bá fún un, [ó] sì lè má ronú pìwà dà.”

9-10. Kí làwọn alàgbà máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́?

9 Ó yẹ káwọn alàgbà gbìyànjú láti mọ ohun tó mú kẹ́ni náà dẹ́ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣé torí pé kò dá kẹ́kọ̀ọ́, kò sì wàásù déédéé mọ́ ló mú kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ má lágbára mọ́? Ṣé kì í ṣe pé ẹni náà ò gbàdúrà déédéé sí Jèhófà mọ́? Ṣé kì í ṣe pé ó ti fàyè gba èròkerò? Ṣé kì í ṣe pé ó ti ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, tó sì ń wo eré ìnàjú tí ò dáa? Ṣé àwọn nǹkan tó ń ṣe ló ṣàkóbá fún un? Ṣé ó tiẹ̀ mọ̀ pé nǹkan tóun ṣe dun Jèhófà rárá?

10 Àwọn alàgbà máa fìfẹ́ bi ẹni náà láwọn ìbéèrè tó máa mú kó ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí kò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára mọ́, tó sì mú kó dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kò yẹ kí wọ́n bi í láwọn ìbéèrè tí ò pọn dandan. (Òwe 20:5) Yàtọ̀ síyẹn, bí Nátánì ṣe lo àpèjúwe láti jẹ́ kí Dáfídì mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa, àwọn alàgbà náà lè lo àpèjúwe láti jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa. Nígbà míì, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kẹ́ni náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kábàámọ̀ ohun tó ṣe nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa pàdé pẹ̀lú ẹ̀. Kódà, ó lè ti ronú pìwà dà.

11. Báwo ni Jésù ṣe ṣe sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?

11 Ó yẹ káwọn alàgbà fara wé Jésù. Nígbà tí Jésù fẹ́ ran Sọ́ọ̀lù ará Tásù lọ́wọ́, ó bi í ní ìbéèrè tó jẹ́ kó ronú jinlẹ̀, ó ní: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Ìbéèrè yìí jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù rí i pé ohun tóun ń ṣe ò dáa. (Ìṣe 9:3-6) Bákan náà, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “Jésíbẹ́lì,”b ó ní: “Mo ní sùúrù fún un kó lè ronú pìwà dà.”—Ìfi. 2:20, 21.

12-13. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Bíi ti Jésù, ó yẹ káwọn alàgbà mú sùúrù fẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n má tètè pinnu pé kò ronú pìwà dà. Àwọn kan lè ronú pìwà dà nígbà àkọ́kọ́ táwọn alàgbà pàdé pẹ̀lú wọn, ó sì lè ju ẹ̀ẹ̀kan lọ káwọn míì tó ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó lè gba pé káwọn alàgbà pàdé pẹ̀lú ẹni náà ju ẹ̀ẹ̀kan lọ. Lẹ́yìn ìjókòó àkọ́kọ́ yẹn, ó ṣeé ṣe kí ẹni náà ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n bá a sọ. Ó lè wá mú kó fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dárí ji òun. (Sm. 32:5; 38:18) Tí wọ́n bá sì wá pàdé pẹ̀lú ẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe kó fẹ̀rí hàn pé òun ti ronú pìwà dà, òun sì ti yí pa dà.

13 Káwọn alàgbà tó lè ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, wọ́n máa fi hàn pé àwọn gba tiẹ̀ rò, àwọn sì ń káàánú ẹ̀. Wọ́n gbà pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà wọn, á sì ran àwọn lọ́wọ́ kí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà lè pe orí ara ẹ̀ wálé, kó sì ronú pìwà dà.—2 Tím. 2:25, 26.

Fọ́tò: 1. Àwọn alagbà mẹ́ta pàdé pẹ̀lú arákùnrin kan. Arákùnrin náà gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan báwọn alàgbà ṣe ń bá a sọ̀rọ̀. 2. Lẹ́yìn náà, àwọn alàgbà tún pàdé pẹ̀lú arákùnrin náà. Arákùnrin náà tẹ́tí sáwọn alàgbà dáadáa nígbà tí wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.

Ó lè gba pé káwọn alàgbà pàdé pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ kó lè fẹ̀rí hàn pé òun ti ronú pìwà dà (Wo ìpínrọ̀ 12)


14. Ta ló yẹ kó gba ògo pé ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà, kí sì nìdí?

14 Kò sí àní-àní pé inú wa máa ń dùn tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà! (Lúùkù 15:7, 10) Àmọ́, ta ló yẹ kó gba ògo náà? Ṣé àwọn alàgbà tó ràn án lọ́wọ́ ni? Ṣé ẹ rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó dẹ́ṣẹ̀? Ó ní: “Bóyá Ọlọ́run lè mú kí wọ́n ronú pìwà dà.” (2 Tím. 2:25) Àlàyé tí wọ́n ṣe nípa ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé: “Tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bá yí èrò àti ìwà ẹ̀ pa dà, kì í ṣe èèyàn èyíkéyìí ló yẹ ká gbé ògo fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà tó jẹ́ kí onítọ̀hún ronú pìwà dà, kó sì yí pa dà ló yẹ ká gbé ògo fún. Pọ́ọ̀lù wá sọ àwọn àǹfààní tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà máa rí tó bá ronú pìwà dà. Ó sọ pé á jẹ́ kó ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́, á pe orí ẹ̀ wálé, á sì jẹ́ kó bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn Èṣù.—2 Tím. 2:26.”

15. Kí ló yẹ káwọn alàgbà ṣe kí wọ́n lè máa ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́?

15 Lẹ́yìn tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà, ìgbìmọ̀ tó bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀ á ṣì lọ máa bẹ̀ ẹ́ wò tàbí kí wọ́n ṣètò pé káwọn alàgbà míì ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ nínú ìdẹkùn Sátánì, kó sì máa hùwà tó tọ́. (Héb. 12:12, 13) Àmọ́ o, kò yẹ kí ìgbìmọ̀ alàgbà jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ohun tí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ṣe. Àmọ́, kí ló ṣeé ṣe kí wọ́n sọ fún ìjọ nípa ẹni náà?

‘BÁ ÀWỌN TÓ DẸ́ṢẸ̀ WÍ NÍṢOJÚ GBOGBO ÀWÙJỌ’

16. “Àwùjọ” wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú 1 Tímótì 5:20?

16 Ka 1 Tímótì 5:20. Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí sí Tímótì tóun náà jẹ́ alàgbà, kó lè mọ bó ṣe máa bójú tó ọ̀rọ̀ “àwọn tó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà.” Ṣé gbogbo ìjọ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà ló ń sọ. Àwọn èèyàn díẹ̀ náà lè jẹ́ àwọn tọ́rọ̀ náà ṣojú wọn tàbí àwọn tóun fúnra ẹ̀ sọ fún. Àwọn alàgbà máa wá sọ fáwọn tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà nìkan pé àwọn ti bójú tó ọ̀rọ̀ yẹn, àwọn sì ti bá ẹni náà wí.

17. Tí ìjọ bá mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tẹ́nì kan dá tàbí táwọn alàgbà rí i pé àwọn ará máa mọ̀ nípa ẹ̀ tó bá yá, ìfilọ̀ wo ni wọ́n máa ṣe, kí sì nìdí?

17 Láwọn ipò kan, ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ìjọ lè ti mọ ohun tẹ́nì kan ṣe tàbí káwọn alàgbà rí i pé wọ́n ṣì máa mọ̀ nípa ẹ̀ tó bá yá. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, “àwùjọ” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ máa jẹ́ gbogbo ìjọ. Ìgbà yẹn ni alàgbà kan máa wá ṣèfilọ̀ fún ìjọ pé wọ́n ti bá arákùnrin tàbí arábìnrin náà wí. Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣèfilọ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn yòókù,” káwọn náà má bàa dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì.

18. Báwo làwọn alàgbà ṣe máa bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí wọn ò sì tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18)? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

18 Táwọn tó ti ṣèrìbọmi, tọ́jọ́ orí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́? Kí làwọn alàgbà máa ṣe? Ìgbìmọ̀ alàgbà máa yan alàgbà méjì kí wọ́n lè lọ rí ọmọ náà àtàwọn òbí ẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.c Àwọn alàgbà máa wádìí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n á sì bi àwọn òbí ẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ti ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà. Táwọn alàgbà méjì náà bá rí i pé ìbáwí táwọn òbí ọmọ náà fún un ti jẹ́ kó yí èrò àti ìwà ẹ̀ pa dà, wọ́n lè pinnu pé kò pọn dandan káwọn yan ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀. Àwọn alàgbà sì mọ̀ pé àwọn òbí ni Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà. (Diu. 6:6, 7; Òwe 6:20; 22:6; Éfé. 6:2-4) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alàgbà á máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òbí ọmọ náà kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ìrànlọ́wọ́ tó nílò ni wọ́n ń fún un. Àmọ́, tọ́mọ tó ti ṣèrìbọmi náà ò bá ronú pìwà dà, tó ṣì ń dẹ́ṣẹ̀ ńkọ́? Àwọn alàgbà máa yan ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀, àwọn òbí ọmọ náà sì máa wà níbẹ̀.

Alàgbà méjì pàdé pẹ̀lú ọmọ tọ́jọ́ orí ẹ̀ ò tíì pé ọdún méjìdínlógún (18) tó ti ṣèrìbọmi àtàwọn òbí ẹ̀ nílé wọn. Alàgbà kan ń ka Bíbélì fún wọn.

Tọ́mọ tọ́jọ́ orí ẹ̀ kò tíì pé ọdún méjìdínlógún (18) bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àwọn alàgbà méjì máa pàdé pẹ̀lú ọmọ náà àtàwọn òbí ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 18)


“JÈHÓFÀ NÍ ÌFẸ́ ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́ TÓ PỌ̀ GAN-AN, Ó SÌ JẸ́ ALÁÀÁNÚ”

19. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Jèhófà tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀?

19 Ojúṣe ìgbìmọ̀ táwọn alàgbà yàn láti ṣèrànwọ́ ni pé kí wọ́n jẹ́ kí ìjọ mọ́. (1 Kọ́r. 5:7) Wọ́n tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà, àmọ́ ọwọ́ ẹ̀ ló kù sí. Táwọn alàgbà bá ń ran ẹni náà lọ́wọ́, ó yẹ kó dá wọn lójú pé á ronú pìwà dà. Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́? Torí wọ́n fẹ́ fara wé Jèhófà tó ní “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an, [tó] sì jẹ́ aláàánú.” (Jém. 5:11) Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù darúgbó, ohun tó sọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ olódodo.”—1 Jòh. 2:1.

20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn?

20 Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà míì, Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ lè má fẹ́ ronú pìwà dà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mú ẹni náà kúrò nínú ìjọ. Kí làwọn alàgbà máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? A máa jíròrò ọ̀rọ̀ yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni Róòmù 2:4 sọ pé ó yẹ káwọn alàgbà máa rántí tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́?

  • Ìmọ̀ràn wo ni 2 Tímótì 2:24-26 sọ pé káwọn alàgbà tẹ̀ lé tí wọ́n bá fẹ́ ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́?

  • Àwùjọ wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nígbà tó sọ pé ‘bá àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ wí níṣojú gbogbo àwùjọ?’

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

a Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ la máa ń pe àwọn alàgbà tá a yàn pé kó bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́ a ò ní pè wọ́n ní ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ mọ́ torí pé kì í ṣe ìyẹn nìkan ni iṣẹ́ wọn. Torí náà láti ìsinsìnyí lọ, ìgbìmọ̀ táwọn alàgbà yàn láti ṣèrànwọ́ la ó máa pè é.

b Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “Jésíbẹ́lì,” ó jọ pé ohun tó ń sọ ni obìnrin kan tàbí àwùjọ àwọn obìnrin tí wọ́n ń ba ìjọ jẹ́.

c Ohun tá a sọ nípa àwọn òbí tún kan àwọn alágbàtọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó ń bójú tó ọmọ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́