ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 October ojú ìwé 18-23
  • Ẹ Di Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tó Dá Yín Lójú Mú Ṣinṣin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Di Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tó Dá Yín Lójú Mú Ṣinṣin
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A KÌ Í LỌ́WỌ́ SÍ ÌBỌ̀RÌṢÀ
  • A MÁA Ń BỌ̀WỌ̀ FÚN ORÚKỌ JÈHÓFÀ
  • A NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́
  • A NÍFẸ̀Ẹ́ ARA WA LÁTỌKÀN WÁ
  • OHUN KAN NÁÀ LA GBÀ GBỌ́
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jẹ́ Kí Òtítọ́ Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Wà Nínú Òtítọ́? Kí Nìdí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 October ojú ìwé 18-23

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42

Ẹ Di Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tó Dá Yín Lójú Mú Ṣinṣin

“Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin.”​—1 TẸS. 5:21.

ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe?

ONÍRÚURÚ ṣọ́ọ̀ṣì làwọn èèyàn ń lọ lónìí, wọ́n sì gbà pé àwọn ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Abájọ tí ọ̀pọ̀ wọn ò fi mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe! Wọ́n máa ń béèrè pé, “Ṣé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà àbí gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?” Àmọ́, ṣé ó dá àwa lójú hán-ún pé òótọ́ lohun tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn àti pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń jọ́sìn lónìí? Ṣé ó dá ẹ lójú pé ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn ló tọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí kan yẹ̀ wò.

2. Bí 1 Tẹsalóníkà 1:5 ṣe sọ, kí nìdí tó fi dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú pé òtítọ́ ni òun gbà?

2 Ó dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú hán-ún pé òtítọ́ ni òun gbà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 1:5.) Kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀. Ohun tó mú kó gbà bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó gbà pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tím. 3:16) Àwọn nǹkan wo ni Pọ́ọ̀lù rí nínú Ìwé Mímọ́? Ó rí ẹ̀rí tó dájú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ò gba ẹ̀rí yẹn rárá. Àwọn alágàbàgebè yẹn sọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn fi ń kọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí ni wọ́n ń ṣe. (Títù 1:16) Pọ́ọ̀lù ò ṣe bíi tiwọn. Kò gba èyí tó wù ú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, kó wá fi èyí tó kù sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “gbogbo ìpinnu Ọlọ́run” ló fi ń kọ́ àwọn èèyàn.​—Ìṣe 20:27.

3. Ṣé ó dìgbà tá a bá rí ìdáhùn gbogbo ìbéèrè wa kí òtítọ́ tó dá wa lójú? (Tún wo àpótí náà “Àwọn Iṣẹ́ àti Èrò Jèhófà ‘Pọ̀ Ju Ohun Tí Mo Lè Ròyìn.’”)

3 Àwọn kan ronú pé ó yẹ kí ìsìn tòótọ́ lè dáhùn gbogbo ìbéèrè títí kan àwọn ìbéèrè tí Bíbélì ò dáhùn ní tààràtà. Àmọ́ ṣé ìyẹn ṣeé ṣe ṣá? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Ó gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n “máa wádìí ohun gbogbo dájú,” síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun ò mọ̀. (1 Tẹs. 5:21) Ó sọ pé “a ní ìmọ̀ dé àyè kan . . . à ń ríran fírífírí nínú dígí onírin.” (1 Kọ́r. 13:9, 12) Kì í ṣe gbogbo nǹkan ni Pọ́ọ̀lù mọ̀, bó sì ṣe rí fáwa náà nìyẹn. Àmọ́, ó mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó mọ̀ nípa Jèhófà. Àwọn nǹkan tó mọ̀ yẹn sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́.

Àwọn Iṣẹ́ àti Èrò Jèhófà​—“Pọ̀ Ju Ohun Tí Mo Lè Ròyìn”

Ṣé ìgbà tá a bá rí ìdáhùn gbogbo ìbéèrè wa tàbí tá a bá dáhùn gbogbo ìbéèrè táwọn èèyàn bá bi wá ni òtítọ́ máa tó dá wa lójú? Rárá. Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí ṣe sọ, a ò lè mọ̀ nípa gbogbo iṣẹ́ Jèhófà àti èrò rẹ̀. Títí láé la ó máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nípa Ọlọ́run wa. Àmọ́ ní báyìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti jẹ́ ká mọ̀ nípa ara rẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé, èyí ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó sì ti jẹ́ ká lè ṣàlàyé àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn.

  • Sáàmù 40:5: “Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó,Jèhófà Ọlọ́run mi, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé; tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn, wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!”

  • Oníwàásù 3:11: “Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente ní ìgbà tirẹ̀. Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”

  • Àìsáyà 55:9: “Torí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, èrò mi sì ga ju èrò yín.”

  • Róòmù 11:33: “Ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o! Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó, tí àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì kọjá àwárí!”

4. Báwo la ṣe lè jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé a ti rí òtítọ́, kí la sì máa jíròrò nípa àwọn Kristẹni tòótọ́?

4 Ọ̀nà kan tá a lè gbà jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ dá wa lójú ni pé ká fi ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà jọ́sìn lónìí wé ọ̀nà tí Jésù sọ pé ká máa gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé àwa Kristẹni tòótọ́ (1) kì í lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà, (2) a máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà, (3) a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a sì (4) nífẹ̀ẹ́ ara wa látọkàn wá.

A KÌ Í LỌ́WỌ́ SÍ ÌBỌ̀RÌṢÀ

5. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ nípa ọ̀nà tó tọ́ láti gbà sin Ọlọ́run, báwo la sì ṣe lè lo ohun tó kọ́ wa?

5 Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní fún Jèhófà ló mú kó fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sìn ín nígbà tó wà lọ́run àti nígbà tó wà láyé. (Lúùkù 4:8) Ohun tí Jésù sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ náà nìyẹn. Jésù ò lo ère, kò sì sí ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ tó lo ère nínú ìjọsìn wọn. Bíbélì sọ pé Ẹ̀mí ni Ọlọ́run. Torí pé a ò lè rí Jèhófà, kò sí ẹnì kankan tó lè gbẹ́ ère tó jọ Jèhófà láé! (Àìsá. 46:5) Àmọ́, ṣé ó yẹ ká máa ṣe ère àwọn tí wọ́n ń pè ní ẹni mímọ́ ká sì máa gbàdúrà sí wọn? Nínú Òfin Mẹ́wàá tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ nínú òfin kejì pé: “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé . . . O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn.” (Ẹ́kís. 20:4, 5) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn yé àwọn tó fẹ́ múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì mọ̀ pé kò fẹ́ káwọn máa jọ́sìn ère.

6. Ọ̀nà wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà jọ́sìn Jèhófà lónìí?

6 Àwọn òpìtàn gbà pé Ọlọ́run nìkan ni àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ jọ́sìn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé History of the Christian Church sọ pé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ “ò ní gbà rárá” ká tiẹ̀ sọ pé ẹnì kan dámọ̀ràn pé kí wọ́n gbé ère wá síbi ìjọsìn. Lónìí, ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gbà jọ́sìn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà jọ́sìn. A kì í gbàdúrà sí ère àwọn “ẹni mímọ́” tàbí ti àwọn áńgẹ́lì, kódà a kì í gbàdúrà sí Jésù. Yàtọ̀ síyẹn, a kì í forí balẹ̀ fún àsíá tàbí ṣe àwọn nǹkan míì láti jọ́sìn àwọn orílẹ̀-èdè. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, a ti pinnu pé ọ̀rọ̀ Jésù la máa tẹ̀ lé pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn.”​—Mát. 4:10.

7. Ìyàtọ̀ tó hàn gbangba wo ló wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹlẹ́sìn míì?

7 Lónìí, ọ̀pọ̀ fẹ́ràn láti máa tẹ̀ lé àwọn olórí ẹ̀sìn tó lókìkí. Wọ́n fẹ́ràn wọn débi pé wọ́n ti sọ wọ́n dòrìṣà. Àwọn èèyàn máa ń rọ́ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn, wọ́n máa ń ra ìwé wọn, wọ́n sì máa ń dáwó rẹpẹtẹ fáwọn olórí ẹ̀sìn náà àti ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Gbogbo nǹkan táwọn olórí ẹ̀sìn yẹn bá sọ làwọn kan lára ọmọ ìjọ wọn máa ń ṣe. Kódà, bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn olórí ẹ̀sìn wọn gẹ̀gẹ̀, wọn ò lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Jésù tí wọ́n bá rí i lójúkojú! Àmọ́, àwa tá à ń fi òótọ́ jọ́sìn Jèhófà ò fi èèyàn kankan ṣe olórí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àwọn tó ń ṣe àbójútó wa nínú ètò Ọlọ́run, tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn, a máa ń fi ọ̀rọ̀ Jésù yìí sọ́kàn pé: ‘Arákùnrin ni gbogbo yín.’ (Mát. 23:8-10) A kì í jọ́sìn ẹnikẹ́ni bóyá olórí ẹ̀sìn lẹni náà tàbí olóṣèlú, a kì í sì í ti ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ náà la kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí àwọn nǹkan míì tó ń lọ nínú ayé. Àwọn nǹkan yìí mú ká yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn tó pe ara wọn ní Kristẹni.​—⁠Jòh. 18:⁠36.

A MÁA Ń BỌ̀WỌ̀ FÚN ORÚKỌ JÈHÓFÀ

Fọ́tò: 1. Arákùnrin Gerrit Lösch mú Bíbélì “Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” jáde. 2. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń wàásù kárí ayé.

Àwa Kristẹni tòótọ́ gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 8-10)d

8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká ṣe orúkọ òun lógo, ká sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀?

8 Ìgbà kan wà tí Jésù gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Jèhófà fi ohùn tó dún ketekete dáhùn àdúrà náà, ó sì ṣèlérí pé òun máa ṣe orúkọ òun lógo. (Jòh. 12:28) Jálẹ̀ gbogbo àsìkò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù láyé, ó ṣe orúkọ Bàbá rẹ̀ lógo. (Jòh. 17:26) Torí náà, àwa Kristẹni tòótọ́ gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa lo orúkọ Ọlọ́run ká sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà.

9. Báwo làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run?

9 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, Jèhófà “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.” (Ìṣe 15:14) Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn gbà pé àǹfààní ńlá ni láti lo orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Wọ́n lo orúkọ náà gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn àti nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ.b Wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ èèyàn kan fún orúkọ Ọlọ́run.​—Ìṣe 2:14, 21.

10. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ èèyàn kan fún orúkọ Jèhófà?

10 Ṣé lóòótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ èèyàn kan fún orúkọ rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí kan yẹ̀ wò. Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn olórí ẹ̀sìn ti ṣe káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ tiẹ̀. Wọ́n ti yọ orúkọ náà kúrò nínú àwọn Bíbélì wọn, kódà àwọn kan tiẹ̀ ṣòfin pé ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ náà nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn.c Ó hàn gbangba pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe orúkọ náà lógo. Nínú gbogbo ẹ̀sìn tó wà láyé, àwa là ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà gan-an! Àwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí ló fi hàn pé àwa gangan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Àìsá. 43:10-12) A ti tẹ Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí iye ẹ̀ ju mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240,000,000) lọ. Bíbélì yìí sì lo orúkọ Jèhófà láwọn ibi táwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ti yọ ọ́ kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, à ń tẹ àwọn ìwé tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run jáde ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ!

A NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́

11. Báwo ni àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

11 Jésù nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ yìí. (Jòh. 18:37) Àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an. (Jòh. 4:23, 24) Kódà, àpọ́sítélì Pétérù pe ẹ̀sìn Kristẹni ní “ọ̀nà òtítọ́.” (2 Pét. 2:2) Nítorí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an, wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ èké títí kan àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti àwọn èrò tí ò bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu. (Kól. 2:8) Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ “ń rìn nínú òtítọ́” torí wọ́n ń jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu láìkù síbì kan.​—3 Jòh. 3, 4.

12. Kí ni àwọn tó ń ṣe àbójútó nínú ètò Ọlọ́run máa ń ṣe tí wọ́n bá rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe ohun tá a gbà gbọ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀?

12 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sọ pé gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì ló yé wa pátápátá. Láwọn ìgbà kan, a ti ṣàṣìṣe nínú ọ̀nà tá a gbà ṣàlàyé Bíbélì àti ọ̀nà tá a gbà ṣètò nǹkan nínú ìjọ. Èyí kò yà wá lẹ́nu torí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó ní ìmọ̀ tó péye. (Kól. 1:9, 10) Díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ ká lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, èyí sì gba pé ká ní sùúrù títí dìgbà tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa túbọ̀ yé wa dáadáa. (Òwe 4:18) Tí àwọn tó ń ṣe àbójútó nínú ètò Ọlọ́run bá rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan, wọ́n tètè máa ń ṣe irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe àwọn àyípadà kan ni pé wọ́n fẹ́ tẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́rùn tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe bí ayé ṣe fẹ́. Àmọ́ ní ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń ṣe àyípadà nítorí ká lè sún mọ́ Ọlọ́run àti pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé ọ̀nà tí Jésù ní ká máa gbà jọ́sìn. (Jém. 4:4) Kì í ṣe ohun táráyé ń gbé lárugẹ tàbí ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ló ń mú ká ṣe àyípadà tá à ń ṣe, àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a túbọ̀ lóye ló mú ká ṣe àwọn àyípadà yẹn. Ẹ ò rí i pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an!​—1 Tẹs. 2:3, 4.

A NÍFẸ̀Ẹ́ ARA WA LÁTỌKÀN WÁ

13. Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù wo làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fi hàn láàárín ara wọn, báwo sì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn láàárín ara wa lónìí?

13 Nínú gbogbo ànímọ́ tó dáa táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní, ìfẹ́ la fi dá wọn mọ̀ jù lọ. Jésù sọ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:34, 35) Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan kárí ayé. A yàtọ̀ sáwọn ẹlẹ́sìn tó kù torí pé ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan ni wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti àṣà wa yàtọ̀ síra. Ìfẹ́ tòótọ́ tó wà láàárín wa yìí máa ń hàn láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè wa. Èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀.

14. Bí Kólósè 3:12-14 ṣe sọ, ọ̀nà wo la lè gbà fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wa?

14 Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká ‘ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara wa.’ (1 Pét. 4:8) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká máa dárí ji ara wa, ká sì máa fara dà á táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó sí wa. Ọ̀nà míì tá à ń gbà fìfẹ́ hàn ni pé a máa ń ṣoore fún gbogbo àwọn ará ìjọ, a sì máa ń ṣaájò wọn, kódà a máa ń finúure hàn sáwọn tó ṣẹ̀ wá. (Ka Kólósè 3:12-14.) Irú ìfẹ́ tó lágbára yìí ni ohun àkọ́kọ́ tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀.

OHUN KAN NÁÀ LA GBÀ GBỌ́

15. Àwọn ọ̀nà míì wo la gbà ń tẹ̀ lé ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gbà jọ́sìn?

15 Àwọn ọ̀nà míì tún wà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà tẹ̀ lé ọ̀nà táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gbà jọ́sìn. Bí àpẹẹrẹ, a ní àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ wa. Ètò tá a ṣe yìí bá ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe mu nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (Fílí. 1:1; Títù 1:⁠5) Bákan náà, à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fi lélẹ̀ torí pé à ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó, lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ àti bá a ṣe ń dáàbò bo ìjọ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà.​—Ìṣe 15:28, 29; 1 Kọ́r. 5:11-13; 6:9, 10; Héb. 13:4.

16. Kí la rí kọ́ nínú Éfésù 4:4-6?

16 Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa pe ara wọn ní ọmọ ẹ̀yìn òun, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́. (Mát. 7:21-23) Bíbélì tún kìlọ̀ pé tó bá di ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ èèyàn máa “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.” (2 Tím. 3:1, 5) Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìgbàgbọ́ kan” ló wà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí.​—Ka Éfésù 4:4-6.

17. Àwọn wo ni ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn lọ́nà tó ní ká máa gbà jọ́sìn lónìí?

17 Àwọn wo ló ń jọ́sìn lọ́nà tí Jésù ní ká máa gbà jọ́sìn lónìí? A ti gbé àwọn ẹ̀rí náà yẹ̀ wò. A sì ti rí ọ̀nà tí Jésù ní ká máa gbà jọ́sìn àti bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe tẹ̀ lé ọ̀nà ìjọsìn náà. Kò sí àwọn míì tó ń ṣe ohun tí Jésù sọ àfi àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn èèyàn Jèhófà àti pé a mọ òtítọ́ nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú! Torí náà, ẹ jẹ́ ká di ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó dá wa lójú mú ṣinṣin.

BÁWO NI ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ṢE FI HÀN PÉ . . .

  • Jèhófà nìkan ṣoṣo là ń jọ́sìn, tí a sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀?

  • a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?

  • a nífẹ̀ẹ́ ara wa látọkàn wá?

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀nà tí Jésù sọ pé ká máa gbà jọ́sìn àti báwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe tẹ̀ lé ohun tó sọ. Àá tún rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń tẹ̀ lé ọ̀nà tí Jésù sọ pé ká máa gbà jọ́sìn lónìí.

b Wo àpótí náà “Ǹjẹ́ Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Lo Orúkọ Ọlọ́run?” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2010, ojú ìwé 6.

c Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2008, Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún pàṣẹ pé ‘ẹ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ pè é rárá’ tẹ́ ẹ bá ń kọ́ni, nínú orin tàbí nínú àdúrà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

d ÀWÒRÁN: Ètò Jèhófà ti tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè tó lé ní igba (200) káwọn èèyàn lè rí Bíbélì tó lo orúkọ Ọlọ́run kà lédè wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́