Orin 21
Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú!
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ayọ̀ aláàánú ti pọ̀ tó!
Wọ́n lẹ́wà lójú Ọlọ́run.
Wọ́n ńsọ fáwọn tó fẹ́ òótọ́
Pé Ọlọ́run fẹ́ràn àánú.
Ọlọ́run tipasẹ̀ Jésù,
Pèsè ìràpadà fún wa.
Ó ńṣàánú ọlọ́kàn tútù
Ó mọ àìlera wa dunjú.
2. Àwọn aláàánú níbùkún,
Ìdáríjì ńtù wọ́n nínú.
Wọ́n ńráàánú gbà torí Kristi
Wá síbi ìtẹ́ Ọlọ́run.
Wọ́n ńfi ayọ̀ pín àánú náà
Wọ́n sì ń wàásù Ọ̀rọ̀ náà,
Wọ́n ńsọ fáyé: “Ẹ tújú ká,
Torí Ìjọba náà ti dé.”
3. Aláà’nú yóò rójú rere
Jèhófà nígbà ìdájọ́.
Wọn yóò rí àánú Ọlọ́run,
Torí pé wọ́n ti ńṣe àánú.
Torí náà ẹ jẹ́ aláàánú
Kí àánú wa sì máa pọ̀ síi.
Ọlọ́run òun Kristi ṣe bẹ́ẹ̀;
Ká máa ṣàánú lójoojúmọ́.
(Tún wo Lúùkù 6:36; Róòmù 12:8; Ják. 2:13.)