Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 14
Orin 56
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì tó bá ipò àdúgbò mu nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! August 8 lọni ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí.
15 min: Báwo Ni Ìjọsìn Jèhófà Ṣe Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Wa Sunwọ̀n Sí i? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìjọsìn tòótọ́ ṣe kókó kí ìgbésí ayé ẹni tó lè láyọ̀, kó sì nítumọ̀. (1) Á jẹ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro àti àníyàn ìgbésí ayé. (Fílí. 4:6, 7) (2) Ó ń fún wa níṣìírí láti ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí. (2 Pét. 1:5-8) (3) Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo àkókò wa àti ohun ìní wa lọ́nà tó ṣàǹfààní jù lọ. (1 Tím. 6:17-19) (4) Ó mú ká ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la. (2 Pét. 3:13) (5) Ó ń jẹ́ ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Ják. 4:8) Jẹ́ kí àwọn ará mọ bí àwọn tí ò mọ Jèhófà tàbí tí wọn ò sìn ín ṣe ṣaláìní àwọn nǹkan wọ̀nyí.
20 min: “Ìmọrírì fún Àánú Ọlọ́run.”a Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, dábàá àwọn ọ̀nà tí a lè gbà ṣètò bí a óò ṣe máa mú ìwé ìròyìn lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn déédéé, nípa lílo ìsọfúnni tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1998, ojú ìwé 8. Ní kí akéde kan tàbí méjì tó dáńgájíá sọ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wọ́n ń gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n fi ṣe góńgó wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì máa darí rẹ̀.—om-YR ojú ìwé 90, ìpínrọ̀ 3.
Orin 176 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 21
Orin 184
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min “Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ilé Rẹ fún Lílò?” Àsọyé tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sọ. Fi àlàyé tó wà nínú Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2001 àti ti April 1990 kún un. Sọ iye Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó wà nínú ìjọ àti ìpíndọ́gba iye àwọn tó ń pésẹ̀. Jẹ́ kí akéde kan tàbí méjì sọ bí òun àti ìdílé rẹ̀ ṣe ń jàǹfààní nítorí pé à ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nínú ilé wọn. Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ yọ̀ǹda ilé rẹ̀ fún lílò fi tó alábòójútó olùṣalága létí.
20 min: Fara Wé Ẹ̀mí Àìṣojo Tí Wọ́n Fi Ń Wàásù. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 170 àti 171. Jẹ́ kí àwùjọ dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 7, kí wọ́n sì fa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí náà yọ nínú ìdáhùn wọn. Ka díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, kí o sì sọ bí wọ́n ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ̀nà nípa iṣẹ́ ìwàásù tí a gbé lé wa lọ́wọ́.
Orin 201 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 28
Orin 45
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá tí ìparí oṣù July sílẹ̀. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ August 1 lọni. Nínú àṣefihàn náà, jẹ́ kí akéde náà jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà.
15 min: Jíròrò “Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Kárí Ayé Láwọn Orílẹ̀-Èdè Mélòó Kan Nílẹ̀ Yúróòpù.” Mẹ́nu kàn án pé ọrẹ tá à ń rí látinú àpótí Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ àti láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
20 min: “Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀ Ń Mú Ayọ̀ Wá.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àlàyé tó wà nínú Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2001 kún un. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan lẹ́nu wò. Ní kó sọ ètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá tó ti ṣe fún àwùjọ rẹ̀, kí ó sì sọ bí àwọn tó wà nínú àwùjọ náà ṣe ń jàǹfààní látinú jíjẹ́rìí pa pọ̀.
Orin 36 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 4
Orin 178
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ àwọn ìwé tí a óò fi lọni ní oṣù yìí. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì tí a lè lò.
20 min: “Fífi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn kan ní èdè àjèjì tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín, tí kò sì sí ìjọ kankan tó ń sọ èdè náà.—km-YR 7/02 ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 4.
15 min: Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Yin Jèhófà! Àsọyé tó ní ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò nínú. Inú wa máa ń dùn nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá ń dáhùn ìbéèrè tí wọ́n ti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa láwọn ìpàdé. Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláápọn àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń mú wa láyọ̀. Wọ́n ń fi hàn pé àwọ́n ní ojúlówó ìgbàgbọ́ bí wọ́n ṣe ń wàásù lọ́nà tó múná dóko lóde ẹ̀rí. Wọ́n ń bu ọlá fún Jèhófà nípa híhùwà tí inú rẹ̀ dùn sí. (yb88-E ojú ìwé 53 àti 54) Ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí á jẹ́ kí wọ́n lè ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ iwájú. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀dọ́ Kristẹni kan tàbí méjì tó ń kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ lẹ́nu wò. Gbóríyìn tọ̀yàyàtọ̀yàyà fún àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ nítorí ipa tí wọ́n ń sà láti yin Jèhófà.
Orin 49 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.