Àwọn Ọ̀nà Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Gbà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
1. Àǹfààní wo là ń rí láwọn ìpàdé márùn-ún tá à ń ṣe lọ́sẹ̀?
1 Ìpàdé márùn-ún tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yàtọ̀ síra, ọ̀nà tá a gbà ń darí rẹ̀ àti ohun tí ìpàdé kọ̀ọ̀kan wà fún sì yàtọ̀. Síbẹ̀, kò sí èyí tó ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú wọn tó bá dọ̀rọ̀ báwọn ìpàdé náà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24, 25) Àwọn nǹkan wo ló ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì ṣàǹfààní nípa Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ?
2. Àǹfààní wo ló wà nínú bí iye àwọn tó máa ń wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kì í ṣeé pọ̀?
2 Ó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run: Iye èèyàn tó máa ń wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ń kéré gan-an sí iye tó ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ yòókù. Èyí máa ń jẹ́ kó rọrùn láti dọ̀rẹ́ àwọn tó lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Òwe 18:24) Ṣó ò ń sapá láti mọ àwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan náà níkọ̀ọ̀kan, bóyá kó o máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tún máa ń jẹ́ kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láǹfààní láti túbọ̀ mọ àwọn ará tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀, kó sì tún lè gbà wọ́n níyànjú lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Òwe 27:23.
3. Kí ló ń mú kó rọrùn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kí wọ́n sì dáhùn?
3 Ṣó o máa ń pe ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ? Nítorí bí èrò kì í ṣeé pọ̀ níbẹ̀, àgàgà bó bá jẹ́ pé ilé àdáni la ti ń ṣe é, ó lè rọrùn fáwọn olùfìfẹ́hàn kan láti máa wá, ìyẹn àwọn tí kì í fẹ́ wà láwọn ìpàdé wa yòókù térò ti máa ń pọ̀. Torí pé àwọn tó wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan náà túbọ̀ máa ń mọwọ́ ara wọn, kì í ṣòro fáwọn ọmọdé tàbí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wa láti dáhùn. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń láǹfààní láti dáhùn lọ́pọ̀ ìgbà torí pé àwọn tó wà níbẹ̀ kì í pọ̀, nípa báyìí, à ń fìyìn fún Jèhófà.—Sm. 111:1.
4. Láwọn ọ̀nà wo ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè gbà rọ àwọn ará lọ́rùn?
4 A máa ń rí i pé ibi tó lè rọ àwọn ará lọ́rùn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ la sábà máa ń gbé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn ará láti wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó sún mọ́ wọn jù lọ, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kí ìrìn tí wọ́n máa rìn bí wọ́n bá ń lọ sípàdé ìjọ mìíràn jìn ju èyí tí wọ́n máa rìn bí wọ́n bá ń lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. A tún lè máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá níbi tá à ń lò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
5. Bí ohun kan ò bá yé wa nípa iṣẹ́ ìwàásù, ọ̀nà wo ni alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè gbà ràn wá lọ́wọ́?
5 Ìrànlọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ń rí i pé òun ran gbogbo ẹni tó wà lábẹ́ àbójútó òun lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú, láti máa jáde òde ẹ̀rí déédéé àti láti máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nítorí náà, ó máa ń gbìyànjú láti rí i pé òun ń bá gbogbo ẹni tó wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ náà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ó sì máa ń ran olúkúlùkù wọn lọ́wọ́ láti túbọ̀ já fáfá nínú onírúurú apá tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà pín sí. Bí èyíkéyìí lára iṣẹ́ ìwàásù bá fẹ́ ṣòro fún ẹ, bí ìpadàbẹ̀wò, kàn sí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ. Ó ṣeé ṣe kó ṣètò pé kó o bá akéde kan tó já fáfá ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín ṣiṣẹ́. Wàá sì túbọ̀ mọ bá a ṣeé kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó o bá ń fiyè sí ọ̀nà dídára tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín gbà ń kọ́ni ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.—1 Kọ́r. 4:17.
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó yẹ ká lè máa jàǹfààní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
6 Àǹfààní tá à ń rí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mà pọ̀ o! Ìpàdé tí Jèhófà fìfẹ́ ṣètò yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìjọsìn Ọlọ́run lákòókò tó kún fún ìṣòro tá à ń gbé yìí.—Sm. 26:12.