Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ—Ìdí Tí A Fi Nílò Rẹ̀
1. Báwo ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe bẹ̀rẹ̀?
1 Lọ́dún 1895, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn àwùjọ tó ń pé jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ ni Dawn Circles for Bible Study [Ẹgbẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Òwúrọ̀ Tó Ń Para Pọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì]. Àwọn ìdìpọ̀ ìwé Millennial Dawn ni wọ́n ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tó yá, orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn àwùjọ wọ̀nyí ni Berean Circles for Bible Study [Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Bèréà Tó Ń Para Pọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì]. (Ìṣe 17:11) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwùjọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi máa ń pàdé ní ilé àdáni nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tó rọrùn fún gbogbo wọn. Bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí a ń ṣe lónìí ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
2. Báwo la ṣe lè mú kí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ?
2 Ìṣírí àti Ìrànlọ́wọ́: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la dìídì ṣètò pé kí àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kéré, èyí á túbọ̀ fún àwọn tó wá láǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Àbájáde rẹ̀ ni “pàṣípààrọ̀ ìṣírí . . . láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì.”—Róòmù 1:12.
3, 4. Báwo ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
3 Bá a bá ń wo bí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15) Máa kíyè sí bó ṣe ń tẹnu mọ́ àwọn Ìwé Mímọ́ tí a gbé ẹ̀kọ́ náà kà. Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè ṣàtúnyẹ̀wò níparí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láti fa àwọn kókó pàtàkì yọ bó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀ nítorí irú ìwé tí à ń kẹ́kọ̀ọ́, yóò sì ṣe èyí nípa lílo Bíbélì nìkan. Àpẹẹrẹ rere tó ń fi lélẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni dára sí i.—1 Kọ́r. 11:1.
4 Láfikún sí bí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó tún ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú alábòójútó iṣẹ́ ìsìn láti ṣe àwọn ètò tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn. Ó ń sapá láti ran gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ìyẹn ni wíwàásù ìhìn rere àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20; 1 Kọ́r. 9:16.
5. Ìrànwọ́ wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń rí gbà nípasẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ?
5 Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nífẹ̀ẹ́ pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ rẹ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ó ń fi èyí hàn ní ìpàdé ìjọ àti nígbà tó bá ń bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ó tún máa ń lo àwọn àkókò mìíràn tó bá bẹ àwọn ará wò láti fún wọn níṣìírí tẹ̀mí. Ó yẹ kára tu àwọn ará láti lè lọ bá alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti gba ìrànwọ́ tẹ̀mí nígbàkigbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀.—Aísá. 32:1, 2.
6. (a) Báwo làwọn arákùnrin wa láwọn ilẹ̀ kan ṣe rí okun gbà nípa pípàdé ní àwùjọ kéékèèké? (b) Báwo ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe jàǹfààní látinú ètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ?
6 Ẹ fún Ara Yín Lókun: Láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run, àwọn ará sábà máa ń pàdé ní àwùjọ kéékèèké. Arákùnrin kan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, a máa ń ṣe ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, a sì máa ń jẹ́ àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe yìí ló ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí, bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a sì ń ní ìfararora lẹ́yìn ìpàdé. A máa ń sọ ìrírí tá a ní fúnra wa, èyí sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ohun kan náà ni kálukú wa ń kojú.” (1 Pét. 5:9) Bíi tàwọn arákùnrin wa yìí, ẹ jẹ́ káwa náà máa fúnra wa lókun nípa kíkọ́wọ́ti ètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní kíkún.—Éfé. 4:16.