Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 28, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ May 3 sí June 28, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Àwọn nǹkan wo ló lè máà jẹ́ ká sọ̀rọ̀ bí ẹni ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ tàbí tó máa jẹ́ kó dà bíi pé à ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ pè nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle? [be-YR ojú ìwé 179 ìpínrọ̀ 4]
2. Kí nìdí tí mímú kí ohùn wa sunwọ̀n sí i kì í fi ṣe ọ̀ràn pé ká kàn máa mí-sínú mí-sóde bó ṣe yẹ tàbí pé ká máa dẹ àwọn iṣan tó bá le? [be-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 2]
3. Bá a ti ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn, àwọn ohun wo la lè ṣe láti “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo”? (1 Kọ́r. 9:20–23) [be-YR ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
4. Kí ni títẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa wé mọ́? [be-YR ojú ìwé 187]
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti bọ̀wọ̀ fún gbogbo ẹni tá a bá bá pàdé lóde ẹ̀rí? [be-YR ojú ìwé 190]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí ló yẹ kí àwọn tó ń kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo, báwo sì ni ọwọ́ wa ṣe lè tẹ èyí? (Mát. 5:16; Jòh. 7:16–18) [be-YR ojú ìwé 56 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 2]
7. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní láti máa fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀ràn kan àti òmíràn hàn nígbà tá a bá ń kọ́ni, báwo sì ni Jésù ṣe ṣe èyí nígbà tó ń kọ́ni? [be-YR ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 2]
8. Báwo ni ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ni ṣe wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ní ìyàtọ̀ sí ti àwọn Farisí? [be-YR ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
9. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, láìsí pé à ń ṣe ìpinnu fún wọn? [be-YR ojú ìwé 60 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
10. Báwo ló ṣe yẹ ká dáhùn nígbà táwọn èèyàn bá béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ wa tó jẹ́ pé oníkálukú ló ní láti ṣe ìpinnu fúnra rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 69 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí nìdí tí Mósè fi gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé “àwòṣe àgọ́ ìjọsìn àti àwòṣe gbogbo ohun èlò inú rẹ̀”? (Ẹ́kís. 25:9; Heb. 8:5) [w03–YR 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
12. Kí ni bí wọ́n ṣe sábà máa ń rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi kí wọ́n tó rú ọrẹ ẹbọ sísun fi hàn? (Léf. 8:14, 18; 9:2, 3) [w00–YR 8/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 16; ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 8]
13. Kí la lè rí kọ́ nínú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi ìgbàgbọ́ wọn hàn nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà tó wà ní Ẹ́kísódù 34:23, 24?
14. Kí lohun tí ẹbọ ìdàpọ̀ wà fún? (Léf. 3:1)
15. Kí la lè rí kọ́ látinú Ẹ́kísódù 30:9 nípa bá a ṣe ní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa lónìí? [w00–YR 11/15 ojú ìwé 14]