ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/04 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 6/04 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tí a ó fi lọni ní June: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bí ẹni tó o fẹ́ wàásù fún bá sọ pé òun ò lọ́mọ, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Nígbà tó o bá ń fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọni, sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

◼ A ti ṣe àyípadà sí àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù tí à ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Igieduma àti ọ́fíìsì wa ní Èkó. Àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù wa tuntun nìwọ̀nyí: (Bẹ́tẹ́lì Igieduma) 01–3204850, 01–3204851, 01–3204852, 01–3204853, 01–3204854, 0805–5502368, 0805–5502369, 08055502370, 0805–5502371. Fax [ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni]: 01–3204855. Ọ́fíìsì tó wà ní Èkó: 01–3205227, 01–3205229, 01–5820604. Ẹ̀rọ Fax àti tẹlifóònù: 01–2647656. Bí kò bá ṣeé ṣe fún ọ láti lo ẹ̀rọ FAX láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí Igieduma tàbí Èkó, nígbà náà o lè lo èyíkéyìí lára àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù wa láti bá wa sọ̀rọ̀ ní Igieduma tàbí Èkó, kó o sì sọ fún ẹni tó ń gba ìpè tó ń wọlé láti fún ọ ní nọ́ńbà tó o lè fi lo ẹ̀rọ FAX rẹ.

Nígbà tó o bá tẹ̀ wá láago ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, ẹni tó ń gba ìpè tó ń wọlé á sọ pé, “Jehovah’s Witnesses, Nigeria branch. May I help you?” Láìjáfara, sọ orúkọ rẹ kó já gaara, bóyá kó o tún sọ ibi tó o ti ń pè, àti orúkọ ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ tàbí ẹ̀ka iṣẹ́ tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, “Orúkọ mi ni Jòhánù Máàkù, Èkó ni mo ti ń pè. Jọ̀wọ́, ṣé mo lè bá [dárúkọ ẹni tó ò ń wá tàbí ẹ̀ka iṣẹ́] sọ̀rọ̀.” Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ńṣe lo kàn fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, o wulẹ̀ lè sọ pé, “Jọ̀wọ́, ṣé mo lè bá [dárúkọ onítọ̀hún àti orúkọ bàbá tàbí ọkọ rẹ̀] sọ̀rọ̀.” Kò pọn dandan láti máa ṣe ìkíni ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹni tó ń gba ìpè tó ń wọlé, ká máa béèrè orúkọ tó ń jẹ́, ìdílé rẹ̀ àti bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ sí, tàbí kẹ̀, ká kàn máa sọ pé “Ẹ̀ló-ẹ̀ló” ṣáá tàbí ká máa béèrè àlàáfíà àwọn èèyàn kan tàbí ti ìdílé Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ rẹ̀. Ìdí ni pé kò fẹ́ láti dá àwọn mìíràn tó ń pè wá dúró. Ó ní láti tètè fi àwọn ìpè tó ń wọlé ránṣẹ́ sẹ́ni tó ni wọ́n láìjáfara. A tún fẹ́ rán yín létí pé, bẹ́ ẹ bá fẹ́ fi ìsọfúnni nípa ọ̀ràn ìjọ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ló ní láti bójú tó èyí.

◼ Láti rí i dájú pé a dáàbò bo Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yan arákùnrin kan tó dàgbà dénú láti máa ti gbogbo ilẹ̀kùn àti fèrèsé lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Lára ìwọ̀nyí ni géètì èyíkéyìí tó bá wà lára ògiri tá a kọ́ yí Gbọ̀ngàn Ìjọba ká. Kí ẹni tá a yan iṣẹ́ yìí fún rí i dájú pé a ti ṣe àwọn ohun tó yẹ láti dáàbò bo Gbọ̀ngàn Ìjọba kó tó kúrò níbẹ̀. Kí àwọn alàgbà ní àkọsílẹ̀ tó bágbà mu nípa orúkọ àwọn akéde tó dàgbà dénú tí wọ́n fún ní kọ́kọ́rọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

◼ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù September, a ó sọ bí a ó ṣe ṣàgbéyẹ̀wò fídíò Respect Jehovah’s Authority. Ẹ̀dà fídíò yìí wà ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà àti èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ń rán gbogbo ìjọ létí pé kí wọ́n béèrè iye ẹ̀dà fídíò yìí tí wọ́n fẹ́ nígbà tí wọ́n bá tún ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àfetígbọ́ Tuntun Tó Wà:

Learn From the Great Teacher—On Audiocassette (Kásẹ́ẹ̀tì 5 nínú álúbọ́ọ̀mù kan) —Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́