Bí Àwọn Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn
1 A ṣètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kó lè “ṣeeṣe ki a funni ní afiyesi ara-ẹni pupọ sí idagbasoke olukuluku nipa tẹmi. . . . Níhìn-ín a rí ifihan ifẹ-inuure ati itọju oníkẹ̀ẹ́ Jehofah fun awọn eniyan rẹ̀.” (om-YR ojú ìwé 75; Aísá. 40:11) Alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ń kó ipa pàtàkì nínú pípèsè irú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀.
2 Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la dìídì ṣètò pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ jẹ́ àwùjọ kékeré, èyí mú kó ṣeé ṣe fún alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ láti mọ olúkúlùkù ẹni tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ ní àmọ̀dunjú. (Òwe 27:23) Lọ́pọ̀ ìgbà, àǹfààní máa ń wà láti ní ìfararora pẹ̀lú àwọn mìíràn ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bí oṣù kan bá fi máa parí, á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bá gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ náà sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èyí á mú kí àwọn tó wà nínú àwùjọ náà lè tọ̀ ọ́ wá fàlàlà nígbà tí wọ́n bá ń dojú kọ àdánwò tàbí nígbà tí wọ́n bá nílò ìṣírí.—Aísá. 32:2.
3 Alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ máa ń gbìyànjú láti fún gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ níṣìírí láti kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọ̀nà kan tó máa ń gbà ṣe èyí ni nípa dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà pẹ̀lẹ́tù àti pẹ̀lú ọ̀yàyà. (1 Tẹs. 2:7, 8) O máa ń sapá láti mú kí gbogbo àwùjọ lóhùn sí ìjíròrò náà, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá. Bí ojú bá ń ti àwọn kan láti dáhùn ìbéèrè, ó lè ṣe àkànṣe ìrànwọ́ fún wọn nípa ṣíṣètò ṣáájú àkókò pé, kí wọ́n múra sílẹ̀ láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí kí wọ́n dáhùn ní ìpínrọ̀ kan pàtó. Tàbí kẹ̀, ó lè kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn.
4 Bí olùrànlọ́wọ́ alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ bá jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí alábòójútó náà ṣètò pé kó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín oṣù méjì-méjì. Èyí á fún alábòójútó náà láǹfààní láti rí ìsapá olùrànlọ́wọ́ náà, á sì lè fún un ní àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò. Ìṣètò àtàtà mà lèyí o, láti ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin kí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn lè gbéṣẹ́ sí i!—Títù 1:9.
5 Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Ọ̀kan lára lájorí iṣẹ́ alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ni mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Núm. 27:16, 17) Ó máa ń ṣe àwọn ètò tó gbéṣẹ́ fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀, ó sì máa ń sapá láti rí i pé gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ ń rí ayọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Éfé. 4:11, 12) Láti ṣe èyí, ó máa ń rí i dájú pé òún ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ náà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ó tún máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú alábòójútó iṣẹ́ ìsìn láti ṣètò fún bí àwọn tó fẹ́ mú ẹ̀ka kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sunwọ̀n sí i ṣe máa gba ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ akéde tó jẹ́ onírìírí.
6 Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́: Alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ máa ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tó jẹ́ pé ipa díẹ̀ ni wọ́n lè kó nínú iṣẹ́ ìwàásù nítorí ipò wọn. Ó máa ń rí i dájú pé àwọn tó ní ìṣòro kan pàtó tó ń ṣèdíwọ́ fún wọn, irú bí àwọn arúgbó tàbí àwọn tí kò lè jáde nílé, àtàwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ onígbà kúkúrú nítorí àìsàn lílekoko tàbí ìfarapa, mọ̀ nípa ìṣètò tó fún wọn láǹfààní láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá látorí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sókè bí wọn kò bá lè ròyìn odindi wákàtí kan lóṣù. (Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ló máa pinnu ẹni tó tóótun láti jàǹfààní látinú ìṣètò yìí.) Ó tún máa ń fìfẹ́ hàn sí àwọn tí a yàn sí àwùjọ náà tí wọ́n lè ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, nípa sísapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa déédéé nínú ìgbòkègbodò ìjọ.—Lúùkù 15:4-7.
7 A mà dúpẹ́ fún àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí àwọn alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ń fi hàn o! Ẹ̀mí ìbìkítà tí wọ́n ń fi hàn ń ṣèrànwọ́ fún olúkúlùkù láti “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ . . . , dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.”—Éfé. 4:13.