ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/02 ojú ìwé 2-7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 28
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 4
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 10/02 ojú ìwé 2-7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 14

Orin 103

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 7, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! November 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 7 láti fi Jí! November 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Mo mọ̀ nípa iṣẹ́ yín dáadáa.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Bí Àwọn Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn.” Kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣàlàyé ní ṣókí bí ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ṣe bẹ̀rẹ̀. (jv-E ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 4) Ṣètò ṣáájú pé kí àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta sọ bí wọ́n ti ṣe jàǹfààní látinú ìfẹ́ àtọkànwá tí a fi hàn sí wọn nípasẹ̀ ìṣètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

Orin 65 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 21

Orin 206

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run.” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Ṣètò láti ka ìpínrọ̀ 5, kí o sì rí i pé àwùjọ lóye kókó náà dáadáa.

20 min: “Ẹ Bẹ̀rù Ọlọ́run, Kí Ẹ sì Fi Ògo fún Un.” (Ìṣí. 14:7) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n rí kọ́ àti bí ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti fi wọ́n sílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé. (A lè yan àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ lórí apá kọ̀ọ̀kan ṣáájú.) Jíròrò àwọn apá tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” Báwo la ṣe lè ran àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì di ògbóṣáṣá ìránṣẹ́ Jèhófà? (2) “Ìbẹ̀rù Jèhófà Túmọ̀ sí Kíkórìíra Ibi.” (w87-YR 4/15 16-18) Báwo ni Òwe 6:16-19 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra—ìgbéraga, irọ́ pípa, lílépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, eré ìnàjú tí kò bójú mu tàbí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí kò yẹ? (3) “Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́.” A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jésù, àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa, àtàwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ; báwo ni sísúnmọ́ wọn ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ayé? (4) “Bẹ̀rù Jèhófà, Má Ṣe Bẹ̀rù Èèyàn.” Báwo ni ìbẹ̀rù mímú Jèhófà bínú ti ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ojo nínú iṣẹ́ ìwàásù, láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run níbi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí láti má ṣe jẹ́ kí ọ̀gá rẹ níbi iṣẹ́ mú ọ pa àwọn ìpàdé ìjọ jẹ, àwọn àpéjọ àyíká, àwọn àpéjọ àkànṣe, àtàwọn àpéjọ àgbègbè? (5) “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run.” (Sm. 119:37; Héb. 4:13) Kí nìdí tó fi yẹ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run sún wa láti yàgò fún mímu ọtí lámujù, wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tàbí dídá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn níkọ̀kọ̀? (6) “Ẹ Máa Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Ìbẹ̀rù Jèhófà.” Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà bù kún ọ nítorí bó o ṣe gba ẹ̀mí rẹ̀ láyè láti máa ṣiṣẹ́ ní kíkún nínú ìgbésí ayé rẹ?—Sm. 31:19; 33:18; 34:9, 17; 145:19.

Orin 171 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 28

Orin 110

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù October sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 7, jẹ́ kí arábìnrin kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 1 lọni, kí arákùnrin kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! November 8 lọni. Lo àbá kejì ní ojú ìwé 7 láti fi Jí! November 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ní ṣókí, tẹnu mọ́ kókó pàtàkì kan tó gbéṣẹ́ nínú ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

12 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ké sí àwọn ará láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, nígbà tí wọ́n lọ rajà, àti láwọn ìgbà mìíràn.

25 min: “Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Fífarasin Tó Wà Nínú Ṣíṣílọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Láìbófinmu.” Kí alàgbà kan tó tóótun bójú tó ìjíròrò yìí lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣètò láti ka ìpínrọ̀ 6, 7, àti 10.

Orin 67 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 4

Orin 66

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá díẹ̀ látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002 fún fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ lọni. Ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

13 min: Má Ṣe Tijú Ìhìn Rere. (Róòmù 1:16) Ọ̀dọ́ kan lọ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lọ bàbá rẹ̀. Ọ̀dọ́ náà kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ìbẹ̀rù pé káwọn ojúgbà rẹ̀ má bàa fi ṣe ẹlẹ́yà. Bàbá rẹ̀ yìn ín fún bó ṣe sọ tinú rẹ̀ jáde. Ó sọ fún un nípa bí Pétérù ṣe hùwà nígbà kan nítorí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. (Mát. 26:69-74) Bàbá fún un ní ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí: A kò gbọ́dọ̀ tijú jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni láé. (Máàkù 8:38) Ó ṣàǹfààní láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní ilé ẹ̀kọ́. Bó o bá sọ irú ẹni tó o jẹ́ fáwọn olùkọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn ni yóò bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ, wọn ò sì ní gbìyànjú láti mú ọ lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tó o mọ̀ pé ó lòdì. Bákan náà làwọn ọ̀dọ́ oníwàkiwà kò ní máa rọ̀ ọ́ láti hùwàkiwà. Á rọrùn fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ yòókù láti tètè lóye ìdí tó o fi pinnu láti má ṣe dájọ́ àjọròde, láti má ṣe kópa nínú àwọn eré ìdárayá ilé ẹ̀kọ́, àti láti má ṣe kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀yìn ilé ẹ̀kọ́. Bí àkókò bá ṣe wà sí, kí bàbá àti ọ̀dọ́ náà jíròrò àwọn kókó tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Pipolongo Ibadọrẹẹ Rẹ Pẹlu Ọlọrun Ni Gbangba” látinú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè, ojú ìwé 315 sí 318. Ọ̀dọ́langba náà fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún ìmọ̀ràn àtàtà tó rí gbà náà.

22 min: Ẹ Fi Ara Yín Sábẹ́ Ọlọ́run—Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù. (Ják. 4:7) Nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí, kí alàgbà kan darí ìjíròrò yìí pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà tó ń tani jí, èyí tí a gbé ka ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tá a ṣe kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (A lè yan àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ lórí apá kọ̀ọ̀kan ṣáájú.) Jíròrò àwọn apá tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Fífi Ara Ẹni Sábẹ́ Ọlọ́run Nínú Ayé Tó Ti Di Ẹrú Yìí.” Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo ká má bàa kó sínú ìdẹkùn ayé? (2) “Bí Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Ṣe Lè Fi Ara Wọn Sábẹ́ Ọlọ́run.” Kí nìdí tó fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú nínú ètò àjọ Jèhófà pé kí àwọn ìdílé ṣọ̀kan dáadáa? Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (3) “Ran Àwọn Tí Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ọmọ Ẹ̀yìn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-In Sọ́dọ̀ Jèhófà.” Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti borí àwọn ìdènà tó lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò? (4) “Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Kọjú Ìjà sí Èṣù.” Kí lohun pàtàkì tó lè mú wa ṣàṣeyọrí nínú kíkọjú ìjà sí Èṣù? Báwo ni ìhámọ́ra tẹ̀mí tí Éfésù 6:11-18 ṣàpèjúwe ṣe lè dáàbò bò wá? (w92-YR 5/15 21 sí 23) (5) “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ti Kọjú Ìjà sí Èṣù” àti “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ń Jàǹfààní Nínú Fífi Ara Wọn Sábẹ́ Ọlọ́run.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n àyínìke Sátánì táwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? Báwo làwọn èwe ṣe ń rí ìbùkún gbà nítorí fífi ara wọn sábẹ́ Jèhófà? (w90-YR 8/1 13 àti 14, ìpínrọ̀ 15 sí 17) (6) “Bí A Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Títẹríba fún Ọlọ́run.” Ṣàlàyé bí àwọn Kristẹni ṣe lè fi ìtẹríba hàn sí àwọn aláṣẹ ìjọba, sí àwọn ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́, nínú agbo ìdílé, àti nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn ànímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

Orin 185 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́