Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2003
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 2003, àwọn ètò tó wà nísàlẹ̀ yìí ni a ó tẹ̀ lé bí a bá ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR] àti Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR].
Kí a fi orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, kí á sì darí rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí:
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun yóò jíròrò ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan tí a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí kò bá sí alàgbà tó pọ̀ tó, kí wọ́n lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun.) Kí ó fi àwọn ọ̀rọ̀ inú àpótí tó fara hàn lójú ìwé tí a ti yanṣẹ́ fún un kún ìjíròrò náà, àyàfi bí a bá sọ pé kí ó má ṣe sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà. Kí ó fi àwọn ìdánrawò sílẹ̀, kò sí lára apá tí yóò bójú tó. Ìwọ̀nyí wà fún ìlò ara ẹni àti ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó èyí, a ó sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí á ṣe iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá láìsí pé à ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwùjọ. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti wulẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí ibi tí a yàn fúnni nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti pe àfiyèsí sí ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ tí à ń jíròrò náà, kí olùbánisọ̀rọ̀ sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí ó lò.
A retí pé kí àwọn arákùnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún kíyè sára kí wọ́n má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bó bá ṣe yẹ.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Fún ìṣẹ́jú mẹ́fà àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tóótun mú kí ìsọfúnni náà bá àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ mu lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà tí a yàn fún ọ̀sẹ̀ náà, níwọ̀n bí arákùnrin tó máa bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì kò ti ní sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá kà. Èyí kò kàn ní jẹ́ ṣíṣe àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà lásán. Olórí ète iṣẹ́ yìí ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣe pàtàkì àti ọ̀nà tó gbà ṣe pàtàkì fún wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, fún ìṣẹ́jú mẹ́rin, olùbánisọ̀rọ̀ yóò ké sí àwùjọ láti kópa nínú ìjíròrò náà nípa ṣíṣe àlàyé ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí àwọn ìbéèrè méjì yìí: “Kí lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tó máa ṣe ọ́ láǹfààní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ tàbí nínú ìgbésí ayé rẹ?” àti “Kí ló fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun tó sì jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìmọrírì fún Jèhófà?” Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́rin. Arákùnrin kan ni yóò bójú tó ìwé kíkà yìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì ni a óò máa ka. Lẹ́ẹ̀kan lóṣù, a óò fa iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí yọ látinú Ilé Ìṣọ́. Kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ka ibi tí a yàn fún un láìṣe ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí sọ ọ̀rọ̀ àsọparí. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ibi tí a óò yàn fúnni láti kà lè gùn tàbí kó kúrú, àmọ́ ìwé kíkà náà kò ní gbà ju ìṣẹ́jú mẹ́rin lọ tàbí kó dín díẹ̀ ní ìṣẹ́jú mẹ́rin. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa wo iṣẹ́ tó máa yàn fúnni ṣáájú kó tó fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ṣe, kí ó jẹ́ kí iṣẹ́ náà bá ọjọ́ orí àti òye akẹ́kọ̀ọ́ náà mu. Ohun tó máa jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, kí wọ́n sì lè ní àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ bíi, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a fún ní iṣẹ́ yìí yóò yan ìgbékalẹ̀ kan tàbí kí a yan ọ̀kan fún wọn látinú oríṣiríṣi ìgbékalẹ̀ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un, kí ó sì mú un bá ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn pápá tó gbéṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Bí a kò bá tọ́ka sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan tí a gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní láti kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ nípa ṣíṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè. Àwọn iṣẹ́ tí a tọ́ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé wọn kà ni kí á yàn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun. Ohun tó máa jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ìsọfúnni náà àti bó ṣe ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti láti lóye àwọn kókó pàtàkì inú ìjíròrò náà. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún ní láti mọ̀wéé kà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún ni yóò wá àlàyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un. Bí a kò bá tọ́ka sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan tí a gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní láti kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ nípa ṣíṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè. Bí a bá yàn án fún arákùnrin, ó lè sọ ọ́ bí àsọyé, kí ó sì ní àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́kàn, kó lè ṣe wọ́n láǹfààní. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kí ó ṣe é níbàámu pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bí a bá sàmì oníràwọ̀ (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, arákùnrin nìkan ni kí ẹ yàn án fún kó lè sọ ọ́ bí àsọyé.
ÀKÓKÒ: Iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ kọjá àkókò, bákan náà ni arákùnrin tó ń gbani nímọ̀ràn pẹ̀lú kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Kí á fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì, Ìkẹta àti Ìkẹrin dúró bí àkókò bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, irú bí ọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, bá kọjá àkókò tí a yàn fún wọn, kí á fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ máa kíyè sí àkókò wọn dáradára. Iye àkókò tí a ó fi ṣe gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta, láìní orin àti àdúrà nínú.
ÌMỌ̀RÀN: Ìṣẹ́jú kan ṣoṣo. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kò ní lò ju ìṣẹ́jú kan ṣoṣo lọ lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti fi sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nípa àkíyèsí tó ṣe lórí apá dídára kan lára iṣẹ́ náà. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti kàn sọ pé “o ṣe dáadáa,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ láti pe àfiyèsí sí àwọn ìdí pàtàkì tí apá tí ó ṣàkíyèsí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi gbéṣẹ́. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí a retí látọ̀dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, a tún lè fúnni ní ìmọ̀ràn tí ń gbéni ró láfikún sí i lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà mìíràn.
OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lè yan alàgbà kan tó dáńgájíá, bí ó bá wà, ní àfikún sí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Ojúṣe rẹ̀ ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó máa fúnni nímọ̀ràn ní gbogbo ìgbà tí àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ti ṣe iṣẹ́ yìí. Ìṣètò yìí ni a ó tẹ̀ lé ní ọdún 2003, a sì lè ṣàtúnṣe rẹ̀ bó bá yá.
ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún Ilé Ẹ̀kọ́ náà.
ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁFẸNUSỌ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ṣáájú èyí, ìjíròrò lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ lókè ni yóò kọ́kọ́ wáyé. A óò gbé àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ yìí ka àwọn ohun tí a ti jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì tó ṣáájú, títí kan ti ọ̀sẹ̀ tí àtúnyẹ̀wò náà máa wáyé.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 6 Bíbélì kíkà: Mátíù 1 sí 6 Orin 91
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ẹ Káàbọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Mátíù 4:1-22
No. 3: Ohun Tí Pípadà Di Erùpẹ̀ Túmọ̀ sí Ní Ti Gidi (kl-YR ojú ìwé 82 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 10)
No. 4: Kí Ni Jésù Ń Ṣe Nísinsìnyí?
Jan. 13 Bíbélì kíkà: Mátíù 7 sí 11 Orin 40
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ (be-YR ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: “Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀” (w01-YR 1/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Mátíù 9:9-31
No. 3: Ìdí Tí A Fi Ń Wàásù fún Àwọn Ẹlòmíràn
No. 4: Ipò Wo Ni Àwọn Òkú Wà? (kl-YR ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 11 sí ojú ìwé 84 ìpínrọ̀ 14)
Jan. 20 Bíbélì kíkà: Mátíù 12 sí 15 Orin 133
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 1: O Mà Lè Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì! (w01-YR 2/1 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: Mátíù 13:1-23
No. 3: Gbogbo Àwọn Tó Wà ní Ìrántí Jèhófà Ni A Óò Jí Dìde (kl-YR ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 87 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Yí Padà?
Jan. 27 Bíbélì kíkà: Mátíù 16 sí 21 Orin 129
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 84 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Bí A Ṣe Lè ní Ìwà Funfun (w01-YR 1/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: w01-YR 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 24
No. 3: Kí Ló Máa Mú Kí Ayé Wà ní Ìṣọ̀kan?
No. 4: Àjíǹde sí Ibo? (kl-YR ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 22)
Feb. 3 Bíbélì kíkà: Mátíù 22 sí 25 Orin 139
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Ketekete (be-YR ojú ìwé 86 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 1: “Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀” (be-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Mátíù 22:15-40
No. 3: Ìjọba Ọlọ́run àti Ète Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 91 ìpínrọ̀ 5)
No. 4: Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye Náà Ní Ti Gidi?
Feb. 10 Bíbélì kíkà: Mátíù 26 sí 28 Orin 27
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Béèyàn Ṣe Lè Sọ̀rọ̀ Ketekete (be-YR ojú ìwé 87 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́ (w01-YR 3/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Mátíù 26:6-30
No. 3: Ìdí Tí Mi Ò Ṣe Ń Lo Oògùn Líle
No. 4: Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́ Àkóso Kan (kl-YR ojú ìwé 91 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 92 ìpínrọ̀ 7)
Feb. 17 Bíbélì kíkà: Máàkù 1 sí 4 Orin 137
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Pípe Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Tọ́—Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Gbé Yẹ̀ Wò (be-YR ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Àwọn Ìbùkún Ìjọba Náà Lè Jẹ́ Tìrẹ (w01-YR 4/1 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: w01-YR 2/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 14
No. 3: Bí A Ṣe Mọ̀ Pé Ìjọba Gidi Ni Ìjọba Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 92 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 93 ìpínrọ̀ 11)
No. 4: Ìdí Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ò Fi Dára
Feb. 24 Bíbélì kíkà: Máàkù 5 sí 8 Orin 72
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Pe Ọ̀rọ̀ Sunwọ̀n Sí I (be-YR ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 92)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Mar. 3 Bíbélì kíkà: Máàkù 9 sí 12 Orin 195
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mímú Kí Ọ̀rọ̀ Yọ̀ Mọ́ni Lẹ́nu (be-YR ojú ìwé 93 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Fífetísílẹ̀ sí Àwọn Àsọyé, Nígbà Ìjíròrò, àti ní Àwọn Àpéjọ (be-YR ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 5)
No. 2: Máàkù 10:1-22
No. 3: Bí A Ṣe Lè Rí Okun Gbà Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
No. 4: Ìdí Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Jẹ́ Ìrètí Kan Ṣoṣo Tí Aráyé Ní (kl-YR ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 95 ìpínrọ̀ 13)
Mar. 10 Bíbélì kíkà: Máàkù 13 sí 16 Orin 187
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀rọ̀ Túbọ̀ Máa Yọ̀ Mọ́ Ọ Lẹ́nu (be-YR ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 96 ìpínrọ̀ 2, láìní àpótí tó wà lójú ìwé 95 nínú)
No. 1: Kí Ni Párádísè Tẹ̀mí? (w01-YR 3/1 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Máàkù 13:1-23
No. 3: Ìdí Tí Jésù Ò Fi Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣàkóso Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Lẹ́yìn Tó Gòkè Re Ọ̀run (kl-YR ojú ìwé 95 ìpínrọ̀ 14 sí ojú ìwé 96 ìpínrọ̀ 15)
No. 4: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Gbè Sẹ́yìn Ẹnikẹ́ni Nígbà Ogun?
Mar. 17 Bíbélì kíkà: Lúùkù 1 sí 3 Orin 13
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ohun Tí O Lè Ṣe Bí O Bá Ń Kólòlò (be-YR àpótí tó wà lójú ìwé 95)
No. 1: “Aláyọ̀ Ni Ènìyàn Tí Ó Ti Wá Ọgbọ́n Rí” (w01-YR 3/15 ojú ìwé 25 sí 28)
No. 2: Lúùkù 3:1-22
No. 3: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jọ́sìn Jésù?
No. 4: Nígbà Wo Ni Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀ fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Bẹ̀rẹ̀ Tí Ó sì Parí? (kl-YR ojú ìwé 96 ìpínrọ̀ 16 sí ojú ìwé 97 ìpínrọ̀ 18)
Mar. 24 Bíbélì kíkà: Lúùkù 4 sí 6 Orin 156
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dídánudúró Níbi Àmì Ìpíngbólóhùn àti fún Yíyí Èrò Padà (be-YR ojú ìwé 97 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Dà Bíi Pé Wọ́n Ṣì Ọ́ Lóye? (w01-YR 4/1 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: Lúùkù 6:1-23
No. 3: Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí (kl-YR ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 99 ìpínrọ̀ 4)
No. 4: Ǹjẹ́ Àwọn Kristẹni Lè Máa Retí Ààbò Ọlọ́run?
Mar. 31 Bíbélì kíkà: Lúùkù 7 sí 9 Orin 47
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dídánudúró fún Ìtẹnumọ́ Ọ̀rọ̀, Dídánudúró Láti Fetí Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 99 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 100 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: “Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́, Kí O sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́” (be-YR ojú ìwé 272 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 275 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: w01-YR 3/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 17 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 20
No. 3: Bí A Ṣe Mọ̀ Pé Àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
No. 4: Kí Ni Díẹ̀ Lára Àwọn Apá-Ẹ̀ka Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn? (kl-YR ojú ìwé 99 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 103 ìpínrọ̀ 7)
Apr. 7 Bíbélì kíkà: Lúùkù 10 sí 12 Orin 68
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Títẹnumọ́ Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Yẹ (be-YR ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 102 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: “Jíjẹ́rìí Jésù” (be-YR ojú ìwé 275 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 278 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Lúùkù 10:1-22
No. 3: Àwọn Ìwà Ìbàjẹ́ Tí A Sọ Tẹ́lẹ̀ Pé Yóò Sàmì sí Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn (kl-YR ojú ìwé 103 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 104 ìpínrọ̀ 12)
No. 4: Apá-Ẹ̀ka Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀ Méjì Ti Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn (kl-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 13 àti 14)
Apr. 14 Bíbélì kíkà: Lúùkù 13 sí 17 Orin 208
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ Sunwọ̀n Sí I (be-YR ojú ìwé 102 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 104 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: “Ìhìn Rere Ìjọba Yìí” (be-YR ojú ìwé 279 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 281 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Lúùkù 15:11-32
No. 3: Bí A Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Wa Kúrò Lọ́wọ́ Ìdarí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
No. 4: Ṣiṣẹ́ Lórí Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí (kl-YR ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 107 ìpínrọ̀ 17)
Apr. 21 Bíbélì kíkà: Lúùkù 18 sí 21 Orin 23
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Títẹnumọ́ Àwọn Kókó Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Borí Èrò Òdì (w01-YR 4/15 ojú ìwé 22 sí 24)
No. 2: w01-YR 4/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 22
No. 3: Bí Ìrètí Àjíǹde Ṣe Kan Ìgbésí Ayé Wa
No. 4: Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Ń Bẹ Ní Ti Gidi! (kl-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
Apr. 28 Bíbélì kíkà: Lúùkù 22 sí 24 Orin 218
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohùn Tó Bá Ipò Àwùjọ Mu (be-YR ojú ìwé 107 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 4)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
May 5 Bíbélì kíkà: Jòhánù 1 sí 4 Orin 31
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Mú Ohùn Rẹ Sunwọ̀n Sí I (be-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 110 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Já Fáfá (be-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Jòhánù 2:1-25
No. 3: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ka Mímu Ọtí Líle Léèwọ̀?
No. 4: Àwọn Áńgẹ́lì Burúkú Gbè Sẹ́yìn Sátánì (kl-YR ojú ìwé 109 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
May 12 Bíbélì kíkà: Jòhánù 5 sí 7 Orin 150
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Ṣe Ìyípadà Nínú Bí O Ṣe Ń Gbóhùn Sókè Tàbí Bí O Ṣe Ń Rẹ Ohùn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: O Lè Kẹ́sẹ Járí Láìka Bí Wọ́n Ṣe Tọ́ Ẹ Dàgbà Sí (w01-YR 4/15 ojú ìwé 25 sí 28)
No. 2: Jòhánù 5:1-24
No. 3: Ìdí Tí Ẹ̀kọ́ Nípa Àyànmọ́ Kò Fi Bọ́gbọ́n Mu
No. 4: Kọ Gbogbo Onírúurú Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 8)
May 19 Bíbélì kíkà: Jòhánù 8 sí 11 Orin 102
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Máa Yí Ìwọ̀n Ìyárasọ̀rọ̀ Rẹ Padà (be-YR ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: ‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’ (w01-YR 5/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Jòhánù 10:16-42
No. 3: Ìdí Tí Bíbélì Fi Dá Ìbẹ́mìílò Lẹ́bi (kl-YR ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 11)
No. 4: Bí A Ṣe Lè Borí Másùnmáwo
May 26 Bíbélì kíkà: Jòhánù 12 sí 16 Orin 24
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ—Lo Onírúurú Ìró Ohùn (be-YR ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Fífi Tí Ọlọ́run Fi Àyè Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin (w01-YR 5/15 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: w01-YR 5/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 7
No. 3: Ohun Tí Ó Túmọ̀ sí Láti ‘Má Ṣe Jẹ́ Apá Kan Ayé’
No. 4: Bíbélì Túdìí Àṣírí Ọ̀nà Tí Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Ń Gbà Ṣiṣẹ́ (kl-YR ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 13)
June 2 Bíbélì kíkà: Jòhánù 17 sí 21 Orin 198
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fi Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí Lára Rẹ Hàn Nínú Ohùn Rẹ (be-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Ipa Tí Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Kó Nínú Rírántí Nǹkan (be-YR ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Jòhánù 20:1-23
No. 3: Bí A Ṣe Lè Dènà Àwọn Ẹ̀mí Burúkú (kl-YR ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 14 sí ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 15)
No. 4: Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Dara Pọ̀ Mọ́ Ètò Ẹ̀sìn?
June 9 Bíbélì kíkà: Ìṣe 1 sí 4 Orin 92
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìtara Bá Ohun Tí À Ń Sọ Mu (be-YR ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 117 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Fún Ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ Nínú Jèhófà Lókun (w01-YR 6/1 ojú ìwé 7 sí 10)
No. 2: Ìṣe 4:1-22
No. 3: Bí O Ṣe Lè fún Ìgbàgbọ́ Rẹ Lókun (kl-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 16 sí ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 17)
No. 4: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Bìkítà Nípa Ọ̀nà Tí À Ń Gbà Jọ́sìn Rẹ̀?
June 16 Bíbélì kíkà: Ìṣe 5 sí 7 Orin 2
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 118 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Ìjẹ́wọ́ Tí Ń Yọrí sí Ìwòsàn (w01-YR 6/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Ìṣe 7:1-22
No. 3: Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Yàtọ̀ sí Àwọn Ìsìn Mìíràn
No. 4: Tẹra Mọ́ Ìjà Rẹ Lòdì sí Àwọn Ẹ̀mí Burúkú (kl-YR ojú ìwé 116 ìpínrọ̀ 18 sí ojú ìwé 117 ìpínrọ̀ 20)
June 23 Bíbélì kíkà: Ìṣe 8 sí 10 Orin 116
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn (be-YR ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Ẹ Máa Bójú Tó Àwọn Ọmọ Òrukàn Àtàwọn Opó Nínú Ìpọ́njú Wọn (w01-YR 6/15 ojú ìwé 9 sí 12)
No. 2: w01-YR 6/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 5
No. 3: Gbígbé Ìgbésí Ayé Ìwà-Bí-Ọlọ́run Ń Mú Ayọ̀ Wá (kl-YR ojú ìwé 118 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 4)
No. 4: aÌdí Tí Lílọ sí Ìpàdé Fi Ṣe Pàtàkì fún Ìtẹ̀síwájú Wa Nípa Tẹ̀mí
June 30 Bíbélì kíkà: Ìṣe 11 sí 14 Orin 167
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìjẹ́pàtàkì Ìfaraṣàpèjúwe àti Ìrísí Ojú (be-YR ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
July 7 Bíbélì kíkà: Ìṣe 15 sí 17 Orin 38
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìfaraṣàpèjúwe àti Ìrísí Ojú (be-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí O Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà? (be-YR ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Ìṣe 15:1-21
No. 3: Bí A Ṣe Ń Gbé Ipò Jèhófà Gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Lárugẹ
No. 4: Àìlábòsí Ń Yọrí sí Ayọ̀ (kl-YR ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 6)
July 14 Bíbélì kíkà: Ìṣe 18 sí 21 Orin 32
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwo Ojú Ẹni Tí Ò Ń Bá Sọ̀rọ̀ Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 124 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Má Ṣe Jẹ́ Kí Iyèméjì Ba Ìgbàgbọ́ Rẹ Jẹ́ (w01-YR 7/1 ojú ìwé 18 sí 21)
No. 2: Ìṣe 19:1-22
No. 3: Ìwà Ọ̀làwọ́ Ń Mú Ayọ̀ Wá (kl-YR ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 7 àti 8)
No. 4: Ohun Tí Ó Túmọ̀ sí Láti ‘Máa Bá A Nìṣó ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’
July 21 Bíbélì kíkà: Ìṣe 22 sí 25 Orin 222
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwo Ojú Àwùjọ Nígbà Tí O Bá Ń Sọ Àsọyé (be-YR ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Ṣé Lóòótọ́ Ni Ò Ń Rára Gba Nǹkan? (w01-YR 7/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Ìṣe 24:1-23
No. 3: Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́?
No. 4: Pa Agbára Ìrònú Rẹ Mọ́ Kí O sì Yẹra fún Ohun Búburú (kl-YR ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 10)
July 28 Bíbélì kíkà: Ìṣe 26 sí 28 Orin 14
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó? (w01-YR 6/15 ojú ìwé 5 sí 8)
No. 2: w01-YR 7/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5 sí 8
No. 3: Jíjẹ́ Olóòótọ́ sí Ẹnì Kejì Ẹni Ń Mú Ayọ̀ Wá Nínú Ìgbéyàwó (kl-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 11 sí ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 13)
No. 4: Bí A Ṣe Ń Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ẹ̀bùn Ìwàláàyè
Aug. 4 Bíbélì kíkà: Róòmù 1 sí 4 Orin 106
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Nígbà Tó O Bá Wà Lórí Pèpéle (be-YR ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 130 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Bí O Ṣe Lè Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà (be-YR ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Róòmù 2:1-24
No. 3: Ǹjẹ́ O Ti Gbé Ayé Rí?
No. 4: Má Ṣe Jẹ́ Apá Kan Ayé (kl-YR ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 14 sí ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 15)
Aug. 11 Bíbélì kíkà: Róòmù 5 sí 8 Orin 179
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ Nígbà Tí O Bá Ń Kàwé fún Àwùjọ (be-YR ojú ìwé 130 ìpínrọ̀ 2 sí 4)
No. 1: ‘Ìbùkún Wà fún Olódodo’ (w01-YR 7/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: Róòmù 5:6-21
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kò Fi Ń Ṣe Ayẹyẹ Kérésìmesì Tàbí Ti Ọjọ́ Ìbí (kl-YR ojú ìwé 126 ìpínrọ̀ 16 àti 17)
No. 4: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Gbà Gbọ́ Nínú Àtúnwáyé?
Aug. 18 Bíbélì kíkà: Róòmù 9 sí 12 Orin 206
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwà ní Mímọ́ Tónítóní Ń Buyì Kún Iṣẹ́ Tí À Ń Jẹ́ (be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Jẹ́ Kí Àwọn Àṣà Tó Ti Mọ́ Ọ Lára Ṣe Ọ́ Láǹfààní (w01-YR 8/1 ojú ìwé 19 sí 22)
No. 2: w01-YR 8/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 10 sí 13
No. 3: Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ti Yí Bíbélì Padà?
No. 4: Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Ṣíṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (kl-YR ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 18)
Aug. 25 Bíbélì kíkà: Róòmù 13 sí 16 Orin 43
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti Ìyèkooro Èrò Inú Ṣe Kan Ìwọṣọ àti Ìmúra Wa (be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 3)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Sept. 1 Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 1 sí 9 Orin 48
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìjẹ́pàtàkì Aṣọ Tó Wà Létòlétò (be-YR ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ (be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: 1 Kọ́ríńtì 3:1-23
No. 3: Bí Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣe Kan Iṣẹ́ àti Eré Ìnàjú (kl-YR ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 20)
No. 4: Ǹjẹ́ Ipò Òṣì Dá Olè Jíjà Láre?
Sept. 8 Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 10 sí 16 Orin 123
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìrísí Tó Dára Kì Í Fa Ìkọ̀sẹ̀ Kankan (be-YR ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 2 sí 4)
No. 1: Borí Àwọn Ohun Tó Lè Dènà Ìtẹ̀síwájú Rẹ! (w01-YR 8/1 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: 1 Kọ́ríńtì 12:1-26
No. 3: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Kí Àwọn Nǹkan Burúkú Ṣẹlẹ̀?
No. 4: Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 21 sí ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 23)
Sept. 15 Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 1 sí 7 Orin 16
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dídúró Dáradára àti Ohun Èlò Tó Wà ní Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Bí Ìgbà Èwe Rẹ Ṣe Lè Dùn Bí Oyin (w01-YR 8/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: 2 Kọ́ríńtì 6:1-7:1
No. 3: Máa Ṣègbọràn sí Aláṣẹ Onípò Àjùlọ (kl-YR ojú ìwé 130 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Bìkítà Nípa Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Ba Ilẹ̀ Ayé Jẹ́?
Sept. 22 Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 8 sí 13 Orin 207
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Dín Ìjayà Kù Nígbà Tí A Bá Ń Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání (w01-YR 9/1 ojú ìwé 27 sí 30)
No. 2: 2 Kọ́ríńtì 8:1-21
No. 3: Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ọkàn Lẹ́yìn Ikú
No. 4: Fi Ara Rẹ Sábẹ́ Àwọn Aláṣẹ Onípò Gíga (kl-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 10)
Sept. 29 Bíbélì kíkà: Gálátíà 1 sí 6 Orin 163
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ọkàn Rẹ̀ Máa Balẹ̀ (be-YR ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 138 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́ (w01-YR 10/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: w01-YR 9/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 11
No. 3: Mọrírì Ìṣètò Ọlọ́run fún Ọlá Àṣẹ Nínú Ìdílé (kl-YR ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 11 sí ojú ìwé 136 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Bí A Ṣe Mọ̀ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso
Oct. 6 Bíbélì kíkà: Éfésù 1 sí 6 Orin 99
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìjẹ́pàtàkì Fífi Ẹ̀rọ Gbé Ohùn Jáde (be-YR ojú ìwé 139 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè (be-YR ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Éfésù 2:1-22
No. 3: Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run Mọ́gbọ́n Dání
No. 4: Ọlá Àṣẹ Nínú Ìjọ Jẹ́ Ìṣètò Onífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Jèhófà (kl-YR ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 139 ìpínrọ̀ 25)
Oct. 13 Bíbélì kíkà: Fílípì 1 sí Kólósè 4 Orin 105
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lo Makirofóònù Bó Ṣe Yẹ (be-YR ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 142 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Máa Rìn ní ‘Ipa Ọ̀nà Ìdúróṣánṣán’ (w01-YR 9/15 ojú ìwé 24 sí 28)
No. 2: Fílípì 2:1-24
No. 3: Bí Ìdúróṣinṣin Ṣe Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Jẹ́ Aláyọ̀ (kl-YR ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 141 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: Ohun Tí Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa Lónìí
Oct. 20 Bíbélì kíkà: 1 Tẹsalóníkà 1 sí 2 Tẹsalóníkà 3 Orin 145
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Bíbélì Láti Dáhùn Ìbéèrè (be-YR ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá (w01-YR 10/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: w01-YR 10/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9
No. 3: Àwọn Wo Ló Ń Lọ Sọ́run?
No. 4: Ipa Pàtàkì Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ń Kó Nínú Ìgbéyàwó (kl-YR ojú ìwé 142 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 9)
Oct. 27 Bíbélì kíkà: 1 Tímótì 1 sí 2 Tímótì 4 Orin 46
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Túbọ̀ Já Fáfá Nínú Lílo Bíbélì (be-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Nov. 3 Bíbélì kíkà: Títù 1 sí Fílémónì Orin 30
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì (be-YR ojú ìwé 145 àti 146)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Ṣe Ìwádìí Nínú Bíbélì (be-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Fílémónì 1-25
No. 3: Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Ìjẹ́pípé Yóò Súni?
No. 4: Máa Fi Ọlá àti Ọ̀wọ̀ Hàn sí Ẹnì Kejì Rẹ (kl-YR ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 14)
Nov. 10 Bíbélì kíkà: Hébérù 1 sí 8 Orin 149
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìjẹ́pàtàkì Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́ (be-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run (w01-YR 9/15 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Hébérù 2:1-18
No. 3: Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Kí O sì Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Ọmọ Rẹ (kl-YR ojú ìwé 145 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 146 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Báwo Ni A Óò Ṣe Ṣèdájọ́ Àwọn Tí A Jí Dìde Níbàámu Pẹ̀lú Ìṣe Wọn?
Nov. 17 Bíbélì kíkà: Hébérù 9 sí 13 Orin 144
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọ̀rọ̀ Yíyẹ Láti Fi Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Kí Ni Jíjẹ́ Adúróṣinṣin Túmọ̀ Sí? (w01-YR 10/1 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: Hébérù 9:11-28
No. 3: Ohun Tí Ìbáwí Onífẹ̀ẹ́ àti Ìgbìmọ̀ Ọgbọ́n Lè Yọrí Sí (kl-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 23)
No. 4: Ìdí Tó Fi Ṣàǹfààní Láti Máa Hu Ìwà Tó Ń Buyin Kún Ọlọ́run
Nov. 24 Bíbélì kíkà: Jákọ́bù 1 sí 5 Orin 88
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìtẹnumọ́ Yíyẹ Kan Fífi Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí Lára Hàn (be-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 1: Òfin Pàtàkì Náà Ṣì Bóde Mu (w01-YR 12/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: w01-YR 11/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 19
No. 3: Ìjẹ́pàtàkì Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà
No. 4: Ìdí Tí A Fi Fẹ́ Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 5)
Dec. 1 Bíbélì kíkà: 1 Pétérù 1 sí 2 Pétérù 3 Orin 54
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Tẹnu Mọ́ Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ (be-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Kíkọ́ Láti Lo Àwọn Ohun Èlò Ìṣèwádìí Yòókù (be-YR ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: 1 Pétérù 1:1-16
No. 3: Àwọn Ohun Tí A Béèrè fún Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 9)
No. 4: Bí Ó Ṣe Yẹ Kí Ẹbọ Ìràpadà Kristi Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Wa
Dec. 8 Bíbélì kíkà: 1 Jòhánù 1 sí Júúdà Orin 22
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Onírúurú Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Dáàbò Bo Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ (w01-YR 11/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: 1 Jòhánù 3:1-18
No. 3: Ìdí Tí A Kò Fi Lè Dẹ́bi fún Bíbélì fún Ìwà Àìlọ́wọ̀ Tí Wọ́n Ń Hù Sáwọn Obìnrin
No. 4: Gbàdúrà sí Ọlọ́run Kí Ó sì Fetí Sí Ọ (kl-YR ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 14)
Dec. 15 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 1 sí 6 Orin 219
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ (be-YR ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi (w01-YR 11/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Ìṣípayá 2:1-17
No. 3: Máa Ní Ìforítì Nínú Àdúrà Kí O sì Máa Fetí Sílẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 156 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 159 ìpínrọ̀ 20)
No. 4: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Kì Í Fi Í Ṣayẹyẹ Kérésìmesì
Dec. 22 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 7 sí 14 Orin 6
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jíjẹ́ Kí Ìlò Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere (be-YR ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: O Lè Yẹra fún Àrùn Ọkàn Nípa Tẹ̀mí (w01-YR 12/1 ojú ìwé 9 sí 13)
No. 2: w01-YR 12/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 13 (pa pọ̀ pẹ̀lú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé)
No. 3: Bí A Ṣe Lè Borí Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
No. 4: Rí Ààbò Tòótọ́ Láàárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run (kl-YR ojú ìwé 160 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 4)
Dec. 29 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 15 sí 22 Orin 60
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Máa Fèrò Wérò Látinú Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 156 ìpínrọ̀ 4)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.