Àpótí Ìbéèrè
◼ Ìgbà wo ló yẹ kí á dá àfikún àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ sílẹ̀?
A ní láti ronú nípa dídá àwùjọ tuntun sílẹ̀ kìkì nígbà tó bá pọndandan kí iye àwọn èèyàn tí yóò máa wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kọ̀ọ̀kan, títí kan ti inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lè jẹ́ nǹkan bí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí kó má tilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kí ló fà á tí a fi dámọ̀ràn èyí?
Nígbà tí a bá mú kí àwọn àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mọ níwọ̀n, ó máa ń túbọ̀ rọrùn fún ẹni tó ń darí rẹ̀ láti fún olúkúlùkù ẹni tó ń wá ní àfiyèsí. Láfikún sí i, gbogbo wọn ló máa láǹfààní láti dáhùn láàárín àwùjọ kan tí kò ti ṣòro fún wọn láti polongo ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba. (Héb. 10:23; 13:15) Níní àwùjọ kéékèèké ní àwọn ibi mélòó kan káàkiri ìpínlẹ̀ ìjọ máa ń mú kí wíwá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá túbọ̀ rọrùn. Àwọn ìjọ tí wọ́n ti mú kí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé yìí túbọ̀ pọ̀ sí i ti rí i pé àròpọ̀ iye àwọn tó ń wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti pọ̀ sí i pẹ̀lú.
Àwọn ìdí pàtàkì lè wà tó fi lè bọ́gbọ́n mu láti dá àwùjọ mìíràn sílẹ̀, kódà bí yóò bá túbọ̀ kéré. Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ ní ibi tó bá wà ní àdádó tàbí tó bá jẹ́ pé èrò ń pọ̀ jù níbi tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí tí kò sí àyè tí ó tó láti jókòó. Nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, a lè dá àwùjọ kan sílẹ̀ tí yóò máa ṣèpàdé lójúmọmọ fún àǹfààní àwọn arúgbó, òṣìṣẹ́ alẹ́, tàbí àwọn arábìnrin tí ọkọ wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.
Kí àwọn akéde mélòó kan tó lágbára nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì dáńgájíá wà lára àwọn tí a yàn sí àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kọ̀ọ̀kan, kí olùdarí àti òǹkàwé tí ó tóótun sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Kí àwọn arákùnrin sakun láti kúnjú ohun tí a ń fẹ́ nínú ìjọ yìí.
Àwọn alàgbà lè mú kí ìtẹ̀síwájú ìjọ túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i nípa rírí i dájú pé iye àwọn tó wà nínú àwọn àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kọ̀ọ̀kan kò pọ̀ jù, kí wọ́n máa bójú tó wọn dáadáa nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì máa ṣèpàdé ní àwọn ibi tó rọrùn. Nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, kí wọ́n dá àwùjọ tuntun sílẹ̀ kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lè jàǹfààní kíkún látinú ìṣètò tẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ yìí. Ṣé o lè yọ̀ǹda ká máa ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní ilé rẹ? Ọ̀pọ̀ tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ ti rí ìbùkún tẹ̀mí gbà.