Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ilé Rẹ fún Lílò?
1 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló yọ̀ǹda ilé wọn pé ká máa lò ó fún ìpàdé ìjọ. (1 Kọ́r. 16:19; Kól. 4:15; Fílém. 1, 2) Láwọn ìjọ kan lónìí, kò sí ibi tó pọ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àtàwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó ti wá mú kí iye èèyàn tó ń wá sáwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan tó ọgbọ̀n tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí sì ti ré kọjá àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tá a dámọ̀ràn.
2 Àǹfààní Ńlá Kan Ni: Ǹjẹ́ o ti ronú yíyọ̀ǹda pé kí a máa ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nínú ilé rẹ? Yàrá kan tó láyè dáadáa, tó mọ́lẹ̀ rekete, táfẹ́fẹ́ sì ń wọnú rẹ̀ dáadáa ló dára fún ète yìí. Níwọ̀n bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpàdé ìjọ, tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára ètò tí Jèhófà ṣe láti fáwọn èèyàn rẹ̀ ní ìtọ́ni, àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ tá a bá ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nínú ilé rẹ. Ọ̀pọ̀ sọ pé àwọ́n ti jàǹfààní nípa tẹ̀mí nípa yíyọ̀ǹda ilé wọn lọ́nà yìí.
3 Tó o bá rò pé ilé rẹ bójú mu fún lílò, jọ̀wọ́ sọ fáwọn alàgbà. Wọ́n lè ti máa wá ibòmíràn tí a ó ti máa ṣe ìpàdé ní àfikún sí èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀. Bí kò bá ṣeé ṣe láti máa ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní ilé rẹ, ǹjẹ́ a lè máa ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá níbẹ̀? Kódà bí kì í bá tiẹ̀ ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí la óò máa ṣe ìpàdé náà níbẹ̀, àwọn alàgbà á mọrírì rẹ̀ tó o bá sọ fún wọn pé wàá yọ̀ǹda ilé rẹ. Àǹfààní yẹn lè jẹ́ tìrẹ lọ́jọ́ iwájú.
4 Híhùwà Ọmọlúwàbí: Ó yẹ kí gbogbo àwọn tó bá ń pàdé pọ̀ nílé àdáni fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun ìní àwọn onílé. Àwọn òbí ní láti rí i pé àwọn ọmọ wọn ò fi ibi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀, kí wọ́n wá máa bẹ́ káàkiri inú ilé tàbí ẹ̀yìnkùlé. Ó tún yẹ ká máa gba tàwọn mìíràn tó ń gbé nínú ilé náà rò, kí a má kàn máa yọ wọ́n lẹ́nu ṣáá.—2 Kọ́r. 6:3, 4; 1 Pét. 2:12.
5 Hébérù 13:16 gbà wá níyànjú pé ká má ṣe gbàgbé “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” Yíyọ̀ǹda ilé rẹ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ jẹ́ ọ̀nà kan tó dára tó o lè gbà máa ṣàjọpín àwọn nǹkan rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti láti máa “fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.”—Òwe 3:9.