Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Lè Mú Àṣeyọrí Wá
1 Ǹjẹ́ o ti ń lo díẹ̀ lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, tàbí àwọn tó wà nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́? Ọ̀pọ̀ akéde ló ń ròyìn àṣeyọrí ńláǹlà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé wọn nípa lílo àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn bí a ṣe tẹ̀ wọ́n jáde gan-an. Àwọn mìíràn ti rí i pé nípa títúbọ̀ lo àkókò díẹ̀ sí i láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti múra àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́rọ̀ ara wọn ṣùgbọ́n tí wọ́n gbé wọn karí àwọn àbá tí a tẹ̀ jáde.
2 Ohun kan dájú, ohun náà sì ni pé bí o bá mọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ dáadáa kí o tó mú ìhìn Ìjọba náà tọ ẹnì kan lọ, ara yóò túbọ̀ tù ọ́, ìwọ yóò sì túbọ̀ ní ìgboyà. Ọ̀rọ̀ tí o bá sọ yóò fi hàn pé ó wù ọ́ tọkàntọkàn láti sọ ìhìn rere náà. Mímúra tí o bá múra sílẹ̀ dáadáa yóò mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ gbádùn mọ́ ọ nítorí pé wàá rí àbájáde tó sàn jù. Ohun tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé a óò mú kí ìrúbọ iṣẹ́ ìsìn wa jẹ́ èyí tó dára jù lọ tí a lè ṣe.—Héb. 13:15; 1 Pét. 2:5.
3 Nítorí náà, wá àyè láti múra sílẹ̀. Ronú nípa irú àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí o bá pàdé ní ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ. Kí ni ìdààmú wọn, kí ni wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Kí làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tó ń ní ipa lórí ìgbésí ayé wọn? Lẹ́yìn tí o bá ti ronú lórí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, wo àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, tàbí kí o yan ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Má ṣe lọ́tìkọ̀ láti ṣe àyípadà tàbí àtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ níbẹ̀ kí ó lè rọrùn fún ọ láti lò ó. Ohun tí o máa ṣe lẹ́yìn náà ni pé kí o jẹ́ kí àwọn akéde mìíràn ṣàyẹ̀wò àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìfidánrawò. Ó ṣeé ṣe kí èyí fún àwọn mìíràn níṣìírí láti mú kí àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tiwọn pẹ̀lú sunwọ̀n sí i. Bó ti wù kó rí, ó dájú pé ẹ óò máa fún ara yín níṣìírí, ẹ óò sì máa gbé ara yín ró nínú iṣẹ́ rere lẹ́nì kìíní kejì.
4 Àkókò àti ìsapá tí o bá lò láti múra fún ọ̀rọ̀ tí o máa sọ lóde ẹ̀rí yóò lérè. Ìbùkún kíkópa lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìkójọpọ̀ lílárinrin tó ń lọ lọ́wọ́ yìí lè jẹ́ tìrẹ.