Ìmúrasílẹ̀ Ń Máyọ̀ Wá
1 Kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ń mú ayọ̀ ńláǹlà wá fún wa. (Sm. 89:15, 16) Àmọ́ o, kí ayọ̀ yẹn bàa lè kún, ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Báa bá ṣe múra sílẹ̀ dáadáa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni àṣeyọrí wa yóò ṣe pọ̀ tó, bí àṣeyọrí wa bá sì ṣe pọ̀ tó, ni ayọ̀ wa yóò ṣe pọ̀ tó.
2 Lo Àwọn Irinṣẹ́ Táa Pèsè: Bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ nípa kíka àwọn àpilẹ̀kọ inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, kí o sì ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ wọn. Wọ́n sábà máa ń pèsè àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó fi ìrònújinlẹ̀ hàn, tí a ṣètò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà tó rọrùn tó sì gbéṣẹ́. Ìwọ yóò rí oríṣiríṣi àpẹẹrẹ tí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn àtakò tó wọ́pọ̀. Wọ́n ń pèsè ìsọfúnni pàtó nípa báa ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò tó gbéṣẹ́, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O ní òmìnira láti lo ìdámọ̀ràn wọ̀nyí nígbàkigbà tóo bá rí i pé ó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti lò wọ́n. Ní àfikún, ìwé pẹlẹbẹ náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó ń bẹ, tó pèsè ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìdáhùn sáwọn ohun tí ń bẹ́gi dí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ipò tóo ń bá pàdé.
3 Ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀jáde tóo fẹ́ fi lọni, kí o sì yan kókó kan tàbí méjì tí ń wọni lọ́kàn, tí o lè fi han onílé. Ìròyìn kàyéfì tóo gbọ́ tàbí tóo kà nípa rẹ̀ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Má ṣe jẹ́ kí àwọn àtakò wíwọ́pọ̀, tó ṣeé ṣe kí a gbé dìde, bá ẹ lábo, ronú àwọn ohun tóo lè fi fèsì. Lẹ́yìn náà, wá lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi múra ohun tí wàá sọ lẹ́nu ọ̀nà sílẹ̀.
4 Máa Wá Sí Gbogbo Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn: Fetí sílẹ̀ dáadáa ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nígbà táa bá ń jíròrò, táa ń ṣe àtúnyẹ̀wò, táa sì ń ṣe àṣefihàn àwọn ìdámọ̀ràn tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàkíyèsí àwọn ìsọfúnni tóo rí i pé o lè lò nígbà tóo bá ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀. Rántí àwọn ipò kan tó wọ́pọ̀ tóo ti bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí o sì ronú nípa àwọn ọ̀nà tóo fi lè jẹ́rìí lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́. Bá àwọn akéde mìíràn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí ṣáájú ìpàdé àti lẹ́yìn ìpàdé.
5 Ìdánilójú wà pé bóo bá “múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere,” a ó fi ayọ̀ ńláǹlà àti àṣeyọrí sí rere nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà ìyè san ẹ́ lẹ́san.—2 Tím. 2:21.