“Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
1 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ́nà tuntun, ó wáyè láti múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ kó tó rán wọn jáde. (Mát. 10:5-14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa sábà máa ń dí, tá a bá lè máa fi ìṣẹ́jú bí i mélòó kan múra sílẹ̀ ká tó jáde fún iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, iṣẹ́ wa á máa méso jáde.—2 Kọ́r. 9:6.
2 Bá A Ṣe Máa Múra Sílẹ̀: Béèyàn bá fẹ́ múra sílẹ̀, ohun àkọ́kọ́ ni pé kó lóye ohun tó wà nínú ìwé tó fẹ́ lò. A tún gbọ́dọ̀ ronú nípa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Kí ló ń jẹ wọ́n lọ́kàn? Kí ni wọ́n gbà gbọ́? A lè wo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tàbí ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó láti mọ ohun tá a máa bá wọn sọ.
3 Fífetí sílẹ̀ dáadáa sáwọn àṣefihàn ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tún lè ràn wá lọ́wọ́. Bí òye wa bá ṣe wá ń pọ̀ sí i bá a ti ń lo ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, àkókò tá a máa fi múra sílẹ̀ á túbọ̀ dín kù. Síbẹ̀, tá a bá ń ronú lórí ohun tá a fẹ́ sọ ká tó lọ sóde ẹ̀rí, tá a sì ń tún ọ̀nà tá a gbà ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ ṣe, iṣẹ́ wa á túbọ̀ máa sèso. A tún gbọ́dọ̀ yẹ báàgì tá à ń gbé lọ sóde ìwàásù wò bóyá gbogbo ohun tá a fẹ́ lò wà níbẹ̀.
4 Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti rántí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká máa sọ̀rọ̀ sókè ketekete nígbà tá a bá ń fi ohun tá a fẹ́ sọ dánra wò, kó bàa lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. Àwọn ìdílé kan máa ń gbádùn fífi ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ lò dánra wò nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ohun táwọn míì máa ń ṣe tó sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé, wọ́n máa ń kọ ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn ní ṣókí sórí ìwé pélébé kan, wọ́n á sì rọra máa wò ó kí wọ́n tó dé ọ̀dọ̀ onílé.
5 Ìdí Tó Fi Ṣàǹfààní: Mímúra sílẹ̀ dáadáa máa jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa túbọ̀ dán mọ́rán, ó sì máa fi kún ayọ̀ wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ó máa ń jẹ́ kára wa balẹ̀, àyà wa ò sì ní máa já tá a bá dẹ́nu ọ̀nà àwọn onílé. Á jẹ́ ká lè pàfiyèsí sáwọn onílé dípò tí ìrònú ohun tá a fẹ́ sọ á fi gbà wá lọ́kàn. Síwájú sí i, tá a bá ti mọ ohun tó wà nínú ìwé tá a fẹ́ lò dáadáa, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti fìtara sọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń lò ó lóde ẹ̀rí.
6 Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti “gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Títù 3:1) Kò sí iṣẹ́ míì tó dára ju iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ. Tá a bá ń múra sílẹ̀ dáadáa ká tó máa lọ sóde ẹ̀rí, èyí á fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún onílé tó gbà wá láyè àti fún Jèhófà Ọlọ́run tá à ń ṣojú fún.—Aísá. 43:10.