ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/08 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 5/08 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12

Orin 134

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April-June

15 min: A Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí! Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 15, 2005, ojú ìwé 30 àti 31. Ní kí àwọn akéde tó o ti sọ fún ṣáájú àkókò sọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro kan.

20 min: Ṣé O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Nígbà Ọlidé? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà lójú ìwé 112 àti 113 nínú ìwé A Ṣètò Wa, kó o sọ àwọn ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní káwọn tó ti fi àkókò ìsinmi tí wọ́n gbà lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n gbádùn, káwọn ọmọ ilé ìwé tí wọ́n fi àkókò ọlidé ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ náà sì sọ báwọn ará ṣe fún wọn níṣìírí àti bí wọ́n ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Kí ló fún wọn láyọ̀ nígbà yẹn? Gba gbogbo àwọn tó bá tóótun níyànjú láti ronú lórí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lóṣù July, August àti September, àgàgà àwọn ọmọ ilé ìwé, nítorí àkókò yẹn ni púpọ̀ wọn máa wà ní ọlidé.

Orin 187

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19

Orin 47

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí Àpótí Ìbéèrè.

15 min: “Jàǹfààní Látinú Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.”a Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú méje kún un, níbi tí òbí kan ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀ lóhun tó wà lójú ìwé 120 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 3 nínú ìwé náà. Kí ó lo ìbéèrè tá a fi ránṣẹ́ pẹ̀lú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.

20 min: “O Lè Di Ọlọ́rọ̀!”b Sọ ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, bó ṣe wà lójú ìwé 113 àti 114 nínú ìwé A Ṣètò Wa. Kí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní September 1 fi ìwé ìwọṣẹ́ wọn sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù.

Orin 206

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26

Orin 103

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! April-June

15 min: “Ẹ Gba Àjàgà Mi Sọ́rùn Yín.”c Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

20 min: Lo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run lóṣù June. Àsọyé àti àṣefihàn. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 lójú ìwé 5 àti 6. Sọ bá a ṣe lè fi àwòrán Párádísè tó wà nínú ìwé yìí bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Fi àṣefihàn alápá méjì kún un. Kí àṣefihàn àkọ́kọ́ dá lórí bá a ṣe lè lo ìwé yìí lóde ẹ̀rí, kí èkejì sì dá lórí bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú níní in lọ́kàn láti fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Orin 169

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 2

Orin 221

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Àwọn Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìṣòtítọ́ Ń Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Gbà. (Òwe 28:20) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí akọ̀wé ìjọ yóò bójú tó. Sọ bí Jèhófà ṣe bù kún ìsapá àwọn ará nínú ìjọ yín láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn láwọn oṣù March, April àti May, kó o sì gbóríyìn fún wọn. Sọ iye àwọn tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn ará ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, àtàwọn àṣeyọrí mìíràn táwọn ará ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà Ìrántí Ikú Kristi àti èyí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi. O lè ní kí ẹnì kan ṣe àṣefihàn èyí tó bá ta yọ nínú àwọn ìrírí tí wọ́n ní. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò ní ṣókí lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta, ní kí wọ́n sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n rí gbà nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

15 min: “Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.”d Ní káwọn ará sọ bí wọ́n ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, kí wọ́n sì sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Orin 44

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́