Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímúra Sílẹ̀
1 Bá a bá múra sílẹ̀ dáadáa ká tó lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó máa jẹ́ ká lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún. Bíi báwo? Bá a bá múra sílẹ̀ bó ṣe yẹ, kò ní jẹ́ pé bá a ó ṣe gbọ́rọ̀ kalẹ̀ nìkan lá o máa ronú lé lórí, a ó sì túbọ̀ lè fiyè sí onílé. Síwájú sí i, kò ní jẹ́ kí ojora máa mú wa, a ó sì lè sọ̀rọ̀ bó ṣe rí lára wa. Ọ̀nà wo la wá lè gbà múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn sílẹ̀?
2 Lo Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó Yẹ: Mú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá máa wúlò ládùúgbò yín lára àwọn tá a dábàá sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, kó o sì wo bó o ṣe máa sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara rẹ. Mú un bá àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá kíyè sí i pé àwọn onísìn kan tàbí àwọn ẹ̀yà kan wọ́pọ̀ ládùúgbò yẹn, ronú lórí bó o ṣe máa gbọ́rọ̀ rẹ kalẹ̀ kó lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Mímú kí kókó tó ò ń bá ẹnì kan sọ jẹ́ ohun tó kàn án á fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ọ́ lógún.—1 Kọ́r. 9:22.
3 Bó o bá ṣe ń lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yẹn, máa ṣàtúnṣe sí i. Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ tó o bá kọ́kọ́ sọ ti ṣe pàtàkì, kíyè sí báwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ṣe ṣe nígbà tó o nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Ǹjẹ́ ohun tó kàn wọ́n lò ń sọ̀rọ̀ lé lórí? Ṣé ó rọrùn fún wọn láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó ò ń bi wọ́n? Bí ò bá rí bẹ́ẹ̀, rí i pé ò ń ṣàtúnṣe tó yẹ sí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.
4 Àwọn Ohun Tó O Lè Máa Fi Rán Ara Rẹ Létí: Ọ̀pọ̀ ni kì í rọrùn fún láti rántí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n fẹ́ lò nígbà tí wọ́n bá déwájú onílé. Bó bá ń ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀, ṣó o ti gbìyànjú ìdánrawò láti sọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó o fẹ́ lò náà sétígbọ̀ọ́ ẹnì kan bí ẹni pé o wà níwájú onílé? Èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí èrò náà ṣe kedere lọ́kàn rẹ, wàá sì lè sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu. Ó tún lè jẹ́ kó o mọ ohun tó kàn nígbà táwọn onílé bá ń mú onírúurú èsì wá.
5 Ọ̀nà míì tó o lè gbà rán ara ẹ létí ni pé kó o kọ díẹ̀ lára ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó o fẹ́ lò sínú ìwé pélébé kan kó o wá wò ó gààràgà bó bá kù díẹ̀ kó o dé ẹnu ọ̀nà tó o ti fẹ́ sọ̀rọ̀. Àkọsílẹ̀ ṣókí bẹ́ẹ̀ ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti túbọ̀ báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn. Láwọn ọ̀nà yìí ni mímúra sílẹ̀ dáadáa lè gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún, ó sì ń jẹ́ ká lè gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà tó dáa.