ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 2/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 13

Orin 121

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 15 àti Jí! January-March lọni. (Lo àbá kẹta fún Jí! January-March.) Nínú ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan, ṣe àṣefihàn ìjẹ́rìí láwọn ibi táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí.

10 min: Ǹjẹ́ Ò Ń Gba Ibi Tí Ètò Jèhófà Bá Darí Rẹ Gbà? Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 7 sí 10.

25 min: “Sọ Fáwọn Ẹlòmíràn Nípa ‘Ìmọ́lẹ̀ Ayé.’”a Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Ka orúkọ àwọn tó ti forúkọ sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Mẹ́nu ba àwọn ìṣètò míì tẹ́ ẹ ti ṣe láti jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Nípa lílo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February 2005, ní ojú ìwé 5, fi àlàyé kún un lórí bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe lè ṣètò àkókò òde ẹ̀rí.

Orin 224 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 20

Orin 89

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni La Óò Máa Fi Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”b Ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà tó fi máa yá àwọn ará lára láti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwé tuntun yìí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

20 min: “Ìrànlọ́wọ́ Tá A Lè Rí Tìrọ̀rùntìrọ̀rùn.”c Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Fi àlàyé ṣókí kún un látinú Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1998 àti ti November 2000.

Orin 1 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 27

Orin 20

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásu yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ March 1 tàbí Jí! January-March. (Ẹ lè lo àbá kẹrin fún Jí! January-March.)

10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

25 min: Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ìwé tuntun náà la ó lò lóṣù March. Ṣe àṣefihàn mélòó kan tá a múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa nípa ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àlàyé lórí ojú ìwé 4 sí 5. Bí ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà bá fa onílé mọ́ra, fi ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó náà hàn án nípa jíjíròrò àwọn ìpínrọ̀ inú ìwé náà tó dá lórí àwọn kókó ọ̀hún. (Ìṣí. 21:4, ojú ìwé 27 sí 28, ìpínrọ̀ 1 sí 3; Aísá. 33:24; 35:5, 6, ojú ìwé 36, ìpínrọ̀ 22; Jòh. 5:28, 29, ojú ìwé 72 sí 73, ìpínrọ̀ 17 sí 19; Sm. 72:16, ojú ìwé 34 ìpínrọ̀ 19) Ní káwọn ará sọ ìrírí tó pinmirin tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo ìwé tuntun náà pàápàá lákòókò tí wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Orin 148 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 6

Orin 51

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nítorí pé àwọn ìwé ìléwọ́ rọrùn láti kó dání tí ìrísí wọn sì máa ń fani mọ́ra, wọ́n dáa láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà téèyàn bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, nígbà téèyàn bá ń wàásù láwọn ibi térò sábà máa ń pọ̀ sí àti nígbà téèyàn bá ń wàásù láìjẹ́ bí àṣà. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa lílo ìwé ìléwọ́ tuntun náà Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́! Ṣàlàyé ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ ní ojú ìwé 2 nínú ìwé ìléwọ́ náà.

15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímúra Sílẹ̀.”d Ṣe àṣefihàn ṣókí kan tó dá lórí bí akéde méjì ṣe ń múra sílẹ̀ láti lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, sọ̀rọ̀ lórí ojú ìwé 82 sí 84 kó o sì ka ìpínrọ̀ 21. Kí wọ́n kádìí àṣefihàn náà nígbà tí wọ́n bá ti fẹ́ ṣe ìdánrawò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà ní gbangba.

20 min: “Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.”e Nígbà tó o bá ń jíròrò fídíò tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ, fi páálí rẹ̀ han àwùjọ kó o sì ṣàlàyé ṣókí lórí ohun tá a kọ sára rẹ̀. Ní kí àwùjọ sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.—Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà, 1997 Yearbook, ojú ìwé 54, àti 1995 Yearbook, ojú ìwé 50 sí 51.

Orin 68 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́