Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Ipò Wọn Mu
1 Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ní ti bó ṣe máa ń mú kí ọ̀nà tóun gbà ń gbé ìhìn rere kalẹ̀ bá ipò àtilẹ̀wá àti ìrònú àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mu. (1 Kọ́r. 9:19-23) Ó yẹ ká sapá láti fara wé e. Tá a bá ronú díẹ̀ lórí ohun tá a fẹ́ sọ ká tó kúrò nílé, àwa náà á lè lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lọ́nà tó fi máa bá ipò àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu. Bá a bá ṣe ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn, a lè kíyè sí àwọn nǹkan kan tó fi ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí hàn ká sì mú un wọnú ọ̀rọ̀ wa. Síbẹ̀, ọ̀nà míì ṣì wà tá a lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bá ipò àwọn èèyàn mu.
2 Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Bá Èsì Ẹni Tó Ò Ń Bá Sọ̀rọ̀ Mu: Nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn onílé, tá ó sì sọ pé kí wọ́n fèsì. Báwo lo ṣe máa ń rí èsì wọn sí? Ṣó o kàn máa ń fẹ́ sọ pé, wọ́n ṣeun, tí wà á sì máa bá ọ̀rọ̀ lọ nípa lílo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó o ti múra sílẹ̀? Àbí ńṣe lọ̀rọ̀ tó o bá sọ lẹ́yìn tẹ́ni náà ti fèsì máa ń fi hàn pé o ka ohun tí onílé náà sọ sí? Tó o bá ń kọbi ara sí èsì àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, á lè ṣeé ṣe fún ọ láti fọgbọ́n lo àwọn ìbéèrè kan láti lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an. (Òwe 20:5) Èyí á jẹ́ kó o lè sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tó máa lè yanjú ohun tó wà lọ́kàn onítọ̀hún gan-an.
3 Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ká máa wà ní sẹpẹ́ láti sọ̀rọ̀ lórí kókó tó yàtọ̀ sí èyí tá a ti múra sílẹ̀ láti jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Bó bá jẹ́ pé ìṣòro kan tá a gbọ́ nínú ìròyìn la fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wa, tẹ́ni tá à ń bá sọ̀rọ̀ sì wá mẹ́nu ba ìṣòro kan tó ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò tàbí èyí tó ń bá òun alára fínra, ìfẹ́ tá a ní láti sọ̀rọ̀ tó bá ohun tó wá lọ́kàn ẹni náà mu á jẹ́ ká lè darí ìjíròrò Bíbélì sórí ohun tó jẹ́ àníyàn ọkàn rẹ̀.—Fílí. 2:4.
4 Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Wa Bá Ipò Wọn Mu: Bí onílé bá béèrè ìbéèrè, ì bá ṣàǹfààní ká dáhùn ìbéèrè ọ̀hún nígbà míì tá a bá padà lọ, ìyẹn tá a bá ti ṣèwádìí tá a sì ti rí àlàyé síwájú sí i lórí kókó náà. A tún lè fún un láwọn ìtẹ̀jáde tó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí kókó náà. Gbogbo èyí tá a mẹ́nu bá yìí á fi hàn pé lóòótọ́ la dìídì fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè mọ Jèhófà.—2 Kọ́r. 2:17.