ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 12/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Ní oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run,” dé, ẹ ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn (ẹ lè lo àkókò tó wà fún àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ) láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó inú àpéjọ àgbègbè náà táwọn akéde rí i pé ó máa wúlò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Apá pàtàkì yẹn nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yóò jẹ́ ká ní àǹfààní láti ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà lo àwọn nǹkan tá a kọ́ ní àpéjọ àgbègbè àti ọ̀nà tó ti gbà ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2005 ojú ìwé 2.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 12

Orin 32

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé kẹjọ (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 15 àti Jí! January-March 2006. A tún lè lo ọ̀nà ìgbékalẹ̀ mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará rí bó ṣe rọrùn tó láti mú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wọnú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tá a bá lò.

15 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ohun Tá À Ń Kọ́ Sílò.” Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sọ ọ́ bí àsọyé. Fi àlàyé kún un látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2005.

20 min: “Ẹ̀kọ́ Tó Máa Jẹ́ Ká Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun.”a Sọ fún akéde kan tàbí méjì pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ àǹfààní tí wọ́n rí nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Orin 101 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 19

Orin 160

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìṣètò àkànṣe tẹ́ ẹ ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní December 25 àti January 1 sétígbọ̀ọ́ àwọn ará. Rán àwọn ará létí láti mú Jí! January-March 2006 wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Ipò Wọn Mu.”b Fi àṣefihàn ṣókí kan kún un láti fi hàn bí akéde kan ṣe lè yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà láti bá ohun tí onílé náà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán mu.

25 Min: “Ǹjẹ́ Ọmọ Rẹ Á Lè Ṣe Ìpinnu bí Àgbàlagbà?”c Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ní kí arákùnrin kan tó mọ̀wé kà ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sókè ketekete. Jíròrò gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ. Lẹ́yìn tó o bá jíròrò ìpínrọ̀ 2, jẹ́ káwọn ará rí ìyàtọ̀ tó wà nínú ipò tó yí àwọn èwe méjèèjì ká, bó ṣe wà ní ìpínrọ̀ 16 sí 17 àti nínú àpótí, lójú ìwé 16 àti 17, nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 1991. Nígbà tó o bá fẹ́ kádìí ìjíròrò náà, fún àwọn òbí níṣìírí láti ṣàtúnyẹ̀wò àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ náà látòkèdélẹ̀, kí wọ́n jíròrò rẹ̀ kí wọ́n sì tún fi ṣe ìdánrawò tó dá lórí àṣẹ Bíbélì nípa ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n bàa lè mú wọn gbára dì láti lè fi ìdánilójú ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Kí àwọn olórí ìdílé rí i dájú pé ọmọ wọn kọ̀ọ̀kan tó bá ti ṣèrìbọmi ń mú káàdì DPA rẹ̀ lọ síbikíbi tó bá ń lọ kí àwọn tí ò bá sì tíì ṣèrìbọmi máa mú Káàdì Ìdánimọ̀ tiwọn náà kiri. Nígbàkigbà tí ẹnì kan bá bá ara rẹ̀ nílé ìwòsàn tó sì di pé ó máa la ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ lọ, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn láti lè ṣèrànwọ́.

Orin 56 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 26

Orin 85

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù December sílẹ̀. Bí ìjọ yín bá máa yí àkókò tẹ́ ẹ̀ ń ṣèpàdé padà nínú ọdún tuntun, ẹ ṣèfilọ̀ àkókò tuntun náà. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò ní January kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí wọ́n ti máa rí àbá lórí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n máa lò.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: Àwọn Nǹkan Tuntun Tó Wà Nínú Jí! Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Mẹ́nu kan àtúnṣe tá a sọ pó máa wà nínú Jí! bá a ṣe ṣèfilọ̀ rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2005, ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 5 sí 6. Ṣàlàyé lórí “Sí Àwọn Òǹkàwé Wa” bó ṣe wà nínú Jí! January-March 2006, ojú ìwé 3 sí 4. Ka àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé tààràtà ni ìwé ìròyìn náà ń darí àwọn òǹkàwé sí Bíbélì. Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe rí àwọn àtúnṣe tuntun tó wà lójú ìwé 31 sí. A ó ṣì máa bá a lọ láti máa fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn èèyàn pa pọ̀ nígbà tá a bá kọ́kọ́ bá wọn pàdé. Àmọ́, ẹ̀dá kan Jí! la ó máa fún àwọn tá a máa ń mú ìwé ìròyìn lọ fún déédéé àtàwọn ẹlòmíràn tó máa ń gbà á lóòrèkóòrè. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January-March. A tún lè ọ̀nà mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January yóò gbé ọ̀nà ìgbékalẹ̀ mìíràn jáde tó máa ṣeé lò fún ọkàn lára àwọn àpilẹ̀kọ inú Jí! January-March. Ẹ lè lo àwọn ọ̀nà ìgbékalẹ̀ méjèèjì jálẹ̀ oṣù náà.

Orin 222 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 2

Orin 5

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Ṣó O Máa Ń Lo Ìwé Ìléwọ́?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní kí àwùjọ sọ àbájáde rere tí wọn ti rí látàrí lílo ìwé ìléwọ́. Fi àṣefihàn kan kún un tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń fi ìpàdé lọ olùfìfẹ́hàn nípasẹ̀ ìwé ìléwọ́.

20 min: “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ọgbọ́n Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa.”d Fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2002, ojú ìwé 1.

Orin 109 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́